"Dọ̀tun, ṣé mi ò ní kú ṣá?" Ìbéèrè tí Dele Giwa bi dókítà tí wọ́n gbé lọ sílé ìwòsàn rẹ̀ kó tó jáde láyé

Aworan Dele Giwa
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọjọ Aje ọjọ kẹrindinlogun lo pe ogoji ọdun ti agba akọroyin ni, Dele Giwa ku lẹyin ti o ṣi lẹta kan ti wọn kọ sii amọ ti wọn ti ro pẹlu ado oloro.

Ni ọsan ọjọ Aiku ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹwaa ọdun 1986, Dele Giwa, to jẹ oludari ileeṣ iwe iroyin Newswatch nigba naa wa ninu ile rẹ nigba ti oniṣẹ kan de fun pẹlu lẹta kan. Lẹta yii ni Dele Giwa ṣi ti ado oloro bu. Girigiri ni wọn gbe e o di ile iwosan. Dokita ti wọn ba lọjọ naa ni ileewosan First Foundation Medical Center to wa ni Ikẹja ni Dokita Dọtun Adedeji.

Nnkan bi aago mejila abọ ọsan ni wọn gbe e de, nnkan bi aago kan lo ku - Dokita Adedeji

"Ẹni ti mo n tọju ni, bi ẹgbọn lo si mi, bi ọmọ iya lo si ṣe n tọju mi" Dokita Adedeji lo fi eyi bẹrẹ ọrọ rẹ nibi eto ifilọlẹ iwe ti wọn kọ ni iranti ogoji ọdun iku Dele Giwa, lọjọ Aje.

Nigba to n ṣalaye bi awọn akoko igbẹyin Dele Giwa ṣe ri, Dokita Dọtun Adedeji ṣalaye iyawo rẹ Funmi ati ọmọ rẹ, Aisha lo n beere nitoripe ọmọ rẹ naa n fa lọ si ọdọ rẹ nigba ti ado oloro naa bu.

Dokita Adedeji ni nnkan bii agogo mejila abọ ni bọọsi konbi ti wn fi gbe Dele Giwa de gunlẹ si ileewosan First Foundation Medical Center to wa ni Ikẹja, oun si ni dokita to wa lẹnu iṣẹ.

O ni lẹsẹkẹsẹ ni wọn gbe e wọ yara itọju aisan pajawiri nibi ti oun ti awọn ọgbẹ ara rẹ, iru eyi to ni oun ko ri ri titi di oni .

"Ara rẹ ti fọ yẹlẹyẹlẹ. ẹsẹ rẹ mejeeji ti la, ẹjẹ si n jade."

'O san ki Dele Giwa ku lọjọ naa ju ko ye, pẹlu gbogbo ọgbẹ ti mo ri lara rẹ'

Aworan Dele Giwa

O fi kun un pe pẹlu gbogbo ọgbẹ yii, Dele Giwa ṣi n sọrọ. O ni, 'Dọtun, ṣe mi o ni ku sha?' ti oun si fun un lesi pe 'Mi o le sọ'.

Dokita Adedeji ni nnkan bii agogo kan ọsan ni Dele Giwa dagbere faye. O ni bi oun ṣe rii lọjọ naa, oun gan mọ pe o san ko ku ju ko wa laaye lọ 'nitoripe ko si bi ẹgbọn Dele ṣe maa le gbe igbe aye to dara pẹlu awọn ọgbẹ to ni lọjọ naa,'.

O ni ẹjẹ to jade lara Dele Giwa kun gbogbo aṣọ iṣẹ oun latoke de ilẹ titi kan bata ti oun wọ lọjọ naa. O fi kun un pe fun ọdun marun un loun fi fi aṣọ naa kọ sori ikọ ni yara oun pẹlu ẹjẹ naa lara rẹ lati le maa ranti akọroyin naa ti oun ri gẹgẹbi ẹgbọn oun.