Switzerland fẹ́ ṣòfin tí kò ní jẹ́ kí gbogbo èèyàn orílẹ̀èdè náà kọjá mílíọ́nù mẹ́wàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Njẹ o ṣeeṣe ki orilẹede kan ma jẹ ki iye eeyan to wa nilẹ rẹ kọja iye ti wọn n fẹ? Ibeere ti orilẹede Switzerland yoo maa dahun lonii ọjọ Aiku ree nibi ipade apero kan.
Nibi ipade apero yii ni awọn eeyan orilẹede naa yoo ti jiroro lori boya wọn ko fẹ ki iye eeyan ti yoo maa gbe nibẹ le kọja miliọnu mẹwaa.
Aba lati jẹ ki eeyan ilẹ naa ma kọja miliọnu mẹwaa yii lo wa lati inu ẹgbẹ oṣelu Swiss People's Party, ti wọn sọ pe yoo mu ki aye dẹrun fun awọn to n gbe nibẹ.
Ninu alaye wọn, ṣiṣẹ eyii yoo din iṣoro ile gbigbe atawọn iṣoro mii ti araalu n dojukọ ku.
Amọ awọn ọmọ ẹgbẹ alatako ti tako aba naa pe niṣe ni wọn gbe kalẹ lati mọọmọ ti ilẹkun mọ awọn ọmọ ilẹ okeere ki wọn ma baa wọle sibẹ.
Ẹwẹ, ijọba ilẹ naa, to fi mọ awọn ẹgbẹ oṣelu atawọn ẹgbẹ oniṣowo ni igbesẹ ọhun buru jọjọ latari pe yoo din iye awọn oṣiṣẹ ile itura ati ile iwosan ku, bẹẹ ni yoo tun ṣakoba fun ibaṣepọ wọn pẹlu ajọ European Union.
Lati ọdun 2020 ni iye eeyan to wa ni Switzerland ti bẹrẹ si n pọ si nigba to ṣi wa ni 7.3 miliọnu.
Lọwọ yii, iye eeyan to wa nilẹ naa ti pe 9.1 miliọnu, ti ida 27% ninu wọn si jẹ ọmọ ilẹ mii to n gbe nibẹ.
Eto ijọba awarawa ti wọn n lo ni Switzerland ni wọn n pe "direct democray," to tumọ si pe wọn maa n dibo ki wọn to gbe gbogbo igbesẹ to ba ṣe pataki nilẹ naa ni, amọ awọn to ba n ṣagbatẹru igbesẹ ọhun gbọdọ ni 100,000 eeyan ti yoo fọwọ si ki gbogbo ilu to le dibo le lori.
Pupọ ninu awọn oludibo lo ti n sọ pe iye ero ibudokọ oju irin ti n pọ ju, ile n wọn ju ti tẹlẹ lọ, bẹẹ si ni eto ilera n gbowo lori.
Lọwọ yii, ida 45% eeyan ilẹ naa lo sọ pe awọn fọwọ si aba ọhun amọ ọpọlọpọ araalu ni ko tii sọ boya wọn faramọ tabi bẹẹ kọ.
Igbesẹ ti Switzerland fẹ gbe yii jẹ eyii yi orilẹede kankan ko tii gbe ri.
Ti ẹ ko ba gbagbe, China ti fi akoko igba kan ṣofin pe ki araalu ma bi ju ọmọ kan ṣoṣo lọ amọ wọn ti opa ofin ọhun ti bayii.
Aba ti Switzerland yii sọ pe iye eeyan to wa nilẹ naa ko gbọdọ kọja miliọnu mẹwaa ti yoo ba fi di ọdun 2050 ati pe ijọba gbọdọ bẹrẹ igbesẹ lati jẹ ko ri bẹẹ ti awọn eeyan ibẹ ba ti le ni 9.5 miliọnu.

























