Wo ìdílé mẹ́wàá tí wọ́n lówó jùlọ káàkiri àgbáyé

Aarẹ United Arab Emirates ati dari ilu Abu Dabi, Sheikh Mohammed bin Zayed Al Nahyan

Oríṣun àwòrán, reutesr

Àkọlé àwòrán, Aarẹ United Arab Emirates ati dari ilu Abu Dabi, Sheikh Mohammed bin Zayed Al Nahyan
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ti a ba n sọ nipa awọn baba olowo lagbaye, awọn idi idile kan wa ti Eledua kẹ, oniruru iṣẹ si ni wọn n ṣe lati ni ogunlọgọ ọrọ ti wọn ti ni.

Lara awọn nnkan ti wọn ti ṣe to sọ wọn di ọlọrọ ni ile tabi ilẹ tita, aṣọ tita, ounjẹ tita ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Iwọnyii ni awọn idile to lowo julọ lagbaye gẹgẹ bii atẹjade Bloomberg ati Investopedia.

10. Idile Wertheimer

Gẹgẹ bii atẹjade Bloomberg ati Investopedia, iye owo ti idile yii ni to $88 biliọnu.

Idile yii lo n ṣe aṣọ Channel to gbajumọ kaakiri agbaye lati orilẹede France.

Baba-baba wọn Gabrielle Coco Chanel, lo da ileeṣẹ naa silẹ amọ awọn ọmọ-ọmọ rẹ Alain ati Gerhard Wertheimer, lo n tukọ ileeṣẹ naa bayii.

9. Idile Ambani

Idile Ambani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iye owo ti idile yii ni to $89.2 biliọnu.

Ọmọ orilẹede India ni idile naa to ni ileeṣẹ Reliance Industries, ti wọn kalẹ silẹ Aisa.

Mukesh Ambani, to jẹ baba alaga ileeṣẹ naa lo da ileeṣẹ ọhun silẹ lọdun 1957.

Iwe iroyin Forbes sọ ninu oṣu Karun un, ọdun 2026 pe apapọ iye owo idile naa ti to $99.7b, owo epo rọbi ni wọn si n ṣe.

8. Idile Bettencourt Meyers

Nnkan bii $92.1b ni apapọ iye owo to wa ninu idile yii.

Ileeṣẹ L'Oréal, to n ṣe ohun ẹṣọ oju ni idile naa ti n pa owo wọle, eyiii ti Eugène Schueller da silẹ lọdun 1909.

Françoise Bettencourt Meyers, to jẹ ọmọ-ọmọ oludasilẹ ileeṣẹ naa ati obinrin to lowo julọ lagbaye lo n dari ileeṣẹ naa bayii.

7. Idile Mars

Idile Mars lo ni ileeṣẹ M&Ms to n ṣe ohun jijẹ ṣokoleeti ti awọn ọmọde fẹran.

Jacqueline Mars ati John Mars, ti wọn jẹ ọmọ-ọmọ ẹni to da ileeṣẹ naa silẹ ni wọn jọ n tukọ rẹ lọwọ yii.

Baba-baba wọn, Frank Mars, lo da ileeṣẹ naa silẹ lọpọ ọdun sẹyin.

6. Idile Koch

David ati Charles Koch

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, David ati Charles Koch

Apapọ iye owo idile yii jẹ $149.5b lonii yii.

Idi oko owo epo rọbi ni idile Charles Koch ti pa owo wọn ko to ya bara si ṣiṣe agbatẹru awọn oloṣelu to ba fẹ du ipo.

Oun ati ẹgbọn rẹ David ni wọn jọ n tukọ ileeṣẹ naa ki David to di oloogbe lọdun 2019.

5. Idile Hermès

Iye owo ti idile Hermès ni lọwọ yii le ni $184.5b.

Awọn ohun ti ileeṣẹ naa n gbe jade ni oniruru aṣọ, iborun, ororo oloorun didun to fi mọ gbajugbaja baagi Kelly & Birkin.

Lonii, ileeṣẹ naa lo n ṣe bata fun agbajugbaja agbabọlu alapẹrẹ, LeBron James atawọn akẹgbẹ rẹ.

Axel Dumas ni adari ileeṣẹ naa bayii, nigba ti Pierre-Alexis Dumas jẹ igbakeji rẹ.

4. Idile Al Thani

Iye owo ti idile naa ni lonii yii to $199.5b.

O ti le ni nnkan bii igba ọdun ti idile Al Thani ti n tukọ orilẹede Qatar bọ.

Igba meji ọtọtọ ni awọn ologun ti gbiyanju lati fi agidi gba ijọba lọwọ wọn amọ ti wọn lulẹ.

Laarin ọdun mejidinlogun pere ni Sheikh Hamad bin Khalifa Al Thani yi kadara Qatar pada si eyii to ṣe e mu yangan laarin awọn orilẹede lagbaye.

Ọdun1995 lo gbajọba Qatar lẹyin to ditẹgbajọba lọwọ baba rẹ lai tẹ ẹjẹ ẹnikẹ ni silẹ.

Lara awọn nnkan ti Qatar fi n ṣọrọ ni epo rọbi, irinajo afẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

3. Idile Al Saud

Idile Al Saud

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Idile Al Saud

Apapọ iye owo idile yii to $ 213.6b.

Idile yii, to n tukọ ijọba Saudi Arabia ti wa lori oye lati nnkan bii ọgọrun un ọdun sẹyin.

Ibaṣẹpọ idile naa pẹlu ileeṣẹ Saudi Aramco, to jẹ ọkan lara awọn ileeṣẹ to n pa owo wọle julọ lagbaye ti jẹ ki ọrọ wọn di pupọ si.

Iye eeyan to wa ninu idile yii le ni 15,000 ti pupọ ninu wọn si jẹ ọlọrọ ati oniṣowo.

2. Idile Al Nahyan

Owo ti idile yii ni to $335.9b.

Idile Al Nahyan ti ọpọ tun mọ si "House of Nahyan, ni idile keji to lowo julọ lagbaye.

Olori idile naa, Sheikh Mohammed bin Zayed Al Nahyan, lo n tukọ ilu Abu Dhabi to tun jẹ Aarẹ United Arab Emirates.

Ọro idile naa ati ti United Arab Emirates tunbọ n gberu si latari owo epo rọbi ti wọn n ri.

Sheikh Mohamed bẹrẹ si n tukọ Abu Dhabi ati Aarẹ United Arab Emirates lọdun 2022.

Ṣaaju rẹ ni ibatan rẹ, Sheikh Khalifa tukọ ilẹ naa lati ọdun 2004 si 2022.

1. Idile Walton

Idile Walton

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Idile Walton to ni ile itaja igbalode Walmart

Owo to wa ninu idile yii to $513.4b.

Idile yii lo ni ile itaja igbalode Walmart ti Sam Walton da silẹ niluu Akansas lọdun 1962.

Lọdun 2025 nikan ṣoṣo, iye owo ti idile naa pa wọle to $681b.

Ẹka ile itaja ti Walmart ni kaakiri agbaye to 10,800.

A gbọ pe wọn gbajumọ pe owo ọja wọn kii wọn bii ti awọn ile itaja mii amọ awọn kan ti fẹsun ileeṣẹ naa pe o n lo awọn oṣiṣẹ rẹ ni ilokulo.