Ọ̀gágun fẹ̀yìntì Rabe Abubakar táwọn agbébọn jí gbé pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ ti kú sí àkàtà àwọn jàndùkú ajínigbé

Ọgagun fẹyinti Rabe Abubakar wọ aṣọ ologun

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọgagunfẹyinti nileeṣẹ ologun Naijiira, Maj Gen Rabe Abubaka, twọn agbesunmọmi ji gbe pẹlu iyawo rẹ lapa ariwa Naijiria ti ku bayii si akata awọọn janduku ajinigbe.

Adari eto iroyin fun ileeṣẹ ologun Naijiria, Maj Gen Samaila Uba, lo fi idi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade ti o fi sita lonii ọjọ Abamẹta ọjọ kẹtala oṣu Kẹfa yii.

Ọgagun Samaila ni pẹlu ibanujẹ ọkan ni ileeṣẹ ọmogun Naijiria fi kede iku ajagunfẹyinti Abubakar.

Ileeṣẹ ologun ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi, atawọn akẹgbẹ oloogbe lori iku Ọgagun fẹyinti naa.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun Naijiria ṣapejuwe ajagunfẹyinti Abububakar gẹgẹ biu akinkanju to sin orilẹede Naijiria ninu iṣẹ ologun.

O ni Ọgagun naa ti figba kan ri jẹ agbẹnusọ fun ikọ AFN nileeṣẹ ologun nigba aye rẹ.

Bakan naa ni Ọgagun to doloogbe naa kopa ribi ribi ninu igbogun ti awọn agbesunmọmi ni Naijiria.

Ọgagun Samaila ni awokọṣe rere ni Ajagunfẹyinti Abubakar jẹ fun ọpọ eeyan pẹlu bi o ṣe jẹ olufọkansin nigba to ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ ọmogun Naijiria.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun ni ileeṣẹ ọmogun mọ ọn mọ pinnu lati ma sọ nnkankan lori akitiyan lati doola ọgagun naa ko to di pe o jade laye.

Alukoro ileeṣẹ ọmogun sọ pe iku Ọgagunfẹyinti Abubakar ti tun fawọn ọmogun lagbara sii lati tẹsiwaju pẹlu ija tawọn n gbe koju awọn agbesunmọmi.

O ni awọn ki ni kaarẹ ninu akitiyan awọn lati daabo ọmọ orilẹede Naijiria.

''Ni bayii, iṣẹ si n lọ lọwọ lati fọwọ ofin mu gbogbo eeyan to wa nidi iku ọgagun Abubakar ati gbogbo awọn agbesunmọmi to n dunkoko mọ alaafia orilẹede Naijiria.

A n fi dawọn ọmọ Naijiria loju wi pe a ko ni sinmi titi ti a o fi ṣẹgun awọn agbesunmọmi ti alaafia yoo si jọba ni Naijiria,'' alukoro ileeṣẹ ologun Naijiria lo sọ bẹẹ.