Ṣé lóòótọ́ ni Boko Haram yọ̀ǹda èèyàn 416 tí wọ́n jí gbé ní Borno? Ohun tí a mọ̀ rèé

Awọn eeyan naa ti wọn ni Boko Haram ṣẹṣẹ tu silẹ ree

Oríṣun àwòrán, BOSYA/PUNCH

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan naa bi ẹgbẹ BOSYA ṣe fi lede
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iroyin kan to gbode bayii ni pe ko din ni eeyan mẹrindin ni ookolenirinwo (416) ti awon ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram ti tu silẹ bayii lẹyin ti wọn ji wọn gbe niluu Ngoshe, ijọba ibilẹ Gwoza, ipinlẹ Borno loṣu Kẹta ọdun 2026 yii.

Ẹka iroyin Punch to kede iroyin naa lọjọ Aiku, ọjọ keje oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii, sọ pe aarẹ ẹgbẹ awọn ọdọ kan ni Borno, 'Borno South Youth Alliance', (BOSYA) Samaila Kaigama,lo fidi ẹ mulẹ pe ana ode yii ti i ṣe ọjọ Satide ni wọn fi awọn eeyan naa silẹ.

Ọpọ obinrin ati awọn ọmọde ni wọn pe awọn ti wọn ni Boko Haram tu silẹ naa.

Alaye BOSYA

Aarẹ ẹgbẹ BOSYA, Samaila Kaigama, ṣalaye fun Punch pe ẹgbẹ yii lo jẹ alarena laaarin ikọ agbesunmọmi naa ati awọn ti wọn ji gbe.

Wọn fi kun un pe BOSYA lo n ba awọn akọroyin sọrọ lati ọjọ kẹwaa oṣu Kẹrin ọdun yii nipa bi ohun gbogbo ṣe n lọ laaarin awọn ajinigbe atawọn to wa nigbekun wọn.

Kaigama sọ fun Punch pe:

"BOSYA ti gba awọn obinrin atawọn ọmọde Ngoshe ti iye wọn jẹ 416. Wọn fi wọn silẹ lọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa.

"Inu wa dun, a si dupẹ pe lati ara igbiyanju wa, ẹkun asunndakẹ wa ati ajọsọ ọrọ fun igba pipẹ, ati ri esi bayii."

O rọ ijọba apapọ Naijiria ati ijọba ipinlẹ Borno atawọn ẹka to ba yẹ gbogbo, lati ṣayẹwo finnifinni fawọn ti wọn ṣẹṣẹ ti ibuba ajinigbe de yii.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrin oṣu Kẹta ọdun 2026 yii ni iroyin jade, pe awọn agbebọn yabo ileeṣẹ awọn ologun Naijiria to wa niluu Ngoshe, nipinlẹ Borno.

Wọn dana sun awọn ọkọ tawọn ologun naa n lo, ṣi ọpọ ologun nidii kuro ni aaye wọn, bẹẹ ni wọn si pa ọpọ eeyan, wọn gbe pupọ wọgbo lọ.

Afikun:Ileeṣẹ ọlọpaa tabi ẹka kankan ko ti i fi atẹjade sita lori ọrọ yii nigba ti a pari akojọpọ iroyin yii.