Ohun tí a mọ̀ rèé lórí àwọn agbébọn tí wọ́n ní wọ́n ti wọ ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, Others
Lati bii ọjọ diẹ sẹyin ni oniruuru fidio ati aworan ti gba ori ayelujara nibi ti awọn eeyan kan ti n sọ pe awọn agbebọn ti wọ ipinlẹ Eko.
Awọn fidio naa lo ti n da inu fu aya fu silẹ ti ọpọ eeyan si n beere pe ṣe loootọ ni ọrọ naa.
Eyi ko ṣẹyin iṣẹlẹ ijinigbe to waye ni ipinlẹ Oyo ati Borno to waye ni ọsẹ diẹ sẹyin nibi ti awọn agbebọn ti ji ọpọ akẹkọọ ati olukọ, ti wọn ṣi wa ni ahamọ awọn ajinigbe naa, gbe lọ.
Lati ọjọ Kiini, oṣu Kẹfa ni oniruuru fidio ati fọto lọkan-o-jọkan ti gba ori ayelujara titi di asiko yii, ti wọn si n fẹsun kan pe awọn agbebọn ti wọ ipinlẹ Eko.
Lara awọn ibi ti wọn darukọ ninu awọn fidio naa pe awọn agbebọn ti balẹ si ni ipinlẹ Eko ni agbegbe Lekki ati Ikorodu ati pe awọn ọlọpaa ti nawọ gan awọn kan ninu awọn agbebọn naa.
Ninu ọkan ninu awọn fidio naa ni ẹnikan ti n sọ pe ọpọ awọn obi ni wọn ti n mu awọn ọmọ wọn kuro ni awọn ile ẹkọ bi iroyin pe awọn agbebọn ti yawọ agbegbe ti kan wọn lara.
Niṣe ọrọ naa bẹrẹ bi ere amọ awọn gbajumọ ilu kan naa ti n fi awọn fidio naa soju opo ayelujara wọn lati fi ta awọn ara ilu nu olobo.
Eyi lo mu BBC kan si awọn ti ọrọ kan lati fi idi ootọ mulẹ lori iroyin naa.
Ki ni awọn alaṣẹ sọ?
"Mo fẹ fi to awọn araalu leti pe awọn ẹṣọ aabo ni ijọba ipinlẹ ati ijọba ibilẹ ti gbọ nipa iroyin to n lọ lori ayelujara, wọn si ti n ṣiṣẹ lati mojuto iṣẹlẹ naa. Gbogbo igbesẹ aabo to yẹ ni a n gbe lati ri pe alaafia ati iduro ire aabo w ani agbegbe wa."
Eyi ni ọrọ ni ti alaga ijọba ibilẹ Ibeju Lekki, Abdullahi Sesan Olowa sọ lati fi fesi si gbogbo awọn iroyin to gba ori ayelujara lori pe awọn agbebọn ti n ṣọṣẹ ni Lekki.
Alaga naa rọ awọn eeyan lati ma ṣe idajọ lọwọ ara wọn ati pe ko si ẹni to lẹtọọ lati tẹ ẹtọ awọn eeyan loju mọlẹ tabi tabuku ẹnikẹni tabi fi iya jẹ enikẹni lọna aitọ.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko sọ pe awọn ti ri ọpọ awọn fidio to gba ori ayelujara nibi ti wọn fẹsun kan pe awọn agbebọn ti n gbiyanju lati ṣekọlu sawọn ile ẹkọ atawọn ọmọde ni Ibeju-Lekki, Imota, Oke-Afo atawọn agbegbe mii ni ipinlẹ Eko.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni irọ to jina si ootọ ni iroyin naa. Agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Abimbola Adebisi sọ pe awọn to n gbe iroyin naa kiri n mọọmọ fẹ da ipaya silẹ laaarin ilu ni.
Adebisi ni ko si ipenija aabo kankan ni ipinlẹ Eko tabi ikọlu kankan sawọn ile ẹkọ lawọn agbegbe Ibeju Lekki, Imota Oke-Afo atawọn ibomii.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ohun ibanujẹ ni pe ọlọkada kan, tawọn eeyan fẹsun kan bii Fulani agbebọn, ti wọn si ṣekọlu sii, padanu ẹmi rẹ ninu ikọlu naa.
Adebisi ni bi wọn ṣe fẹsun kan ọkunrin naa pe agbebọn ni ko ṣẹyin iroyin tawọn kan n gbe kiri lo jẹ ki wọn ṣekọlu sii.
"Bi wọn ṣe n gbe iroyin ofege kiri ti mu ẹmi eeyan kan, Kulaha Ayuba, ẹni ọdun mẹrinlelogun to jẹ ọlọkada lọ.
"Awọn ọdọ ilu ko ṣe iwadii iroyin ti wọn gbọ nipa awọn agbebọn, ti wọn si fẹsun kan-an pe agbebọn ni."
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn afurasi mẹẹdogun ni ọwọ ti ba pe wọn n gbe iroyin ofege nipa awọn agbebọn naa kiri ati pe igbagbọ wa pe wọn lọwọ ninu iku Ayuba.
Wọn ni iwadii ti n lọ lori iṣẹlẹ naa.
Bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe n fidi rẹ mulẹ pe ko si awọn agbebọn ni ipinlẹ Eko ni wọn n jawe ikilọ pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o n gbe iroyin ofege lori ayelujara, tabi kọ ohunkohun to le da inu fu aya fu silẹ ni wọn maa foju wina ofin.
Ki ni ohun to ṣẹlẹ ni Ikorodu ati Lekki?
Nigba ti BBC News Pidgin kan si DPO Lekki nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, Rasheed Owoseni ni ko si aaye ti awọn agbebọn le fara pamọ si ni Lekki.
O ni fidio tawọn eeyan n gbe kiri gẹgẹ bi awọn agbebọn lo jẹ awọn eeyan ti wọn wa ta ẹran agbo lasiko ọdun Ileya
Ni Ikorodu, awọn fidio kan ṣafihan bawọn obi ṣe n sare lọ mu awọn ọmọ wọn ni ile ẹkọ nitori iroyin pe awọn agbebọn ti w ani agbegbe naa.
Amọ ọlọpaa Oguniyi Babatunde to jẹ alakoso agbegbe Imota nibi ti wọn ti fẹsun kan pe iṣẹlẹ naa waye sọ pe awọn eeyan lo n gbe iroyin ofege.
O ṣalaye pe ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn eeyan ni wọn dawọjọ na Hausa kan ni agbegbe naa nitori wọn ba awọn aṣọ ọmọde ninu baagi rẹ.
O ni nigba ti oun atawọn ọlọpaa mii de agbegbe naa ni awọn ri pe ọrọ ko ri bi wọn ṣe n gbe lori ayelujara.
O sọ pe obinrin kan lo fun Hausa naa lawọn aṣọ ọmọde nitori awọn ọmọ rẹ ko ri aṣọ wọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ranṣẹ pe obinrin naa lati fidi ọrọ naa mulẹ ti wọn si ni bẹẹ lo ri.
























