Awon to ha
Omo ogun ilẹ Africa ti wọn mu logun to jinna réré
Lud Beverley, ọmọ ogun tẹlẹ lati Congo-Brazzaville to n kọṣẹ ogun,fẹṣọ gbe ọwọ rẹ ti wọn we ni bandeeji, bẹẹ ni awọn ika ọwọ rẹ kan ko pé mọ.
O sun sori ibusun ileewosan kan ni agọ awọn ẹlẹwọn to wa ni Ila-Oorun Ukraine
Ẹni ọdun mejidinlọgbọn naa ti wa nileewosan yii fun oṣu mẹta nigba ti BBC ṣabẹwo sibẹ nipari oṣu Kẹta lati mọ si i nipa bi awọn ọmọ Africa ti ogun Russia-Ukraine ti ka mọ ṣe n pọ si i.
Gẹgẹ bi akọsilẹ onka Ukraine ṣe wi, ẹyọkan ninu eeyan mẹjọ ti wọn mu logun lọdun to kọja wa lati Iwọ -Oorun Africa. Igbagbọ Ukraine bayii ni pe awọn eeyan Africa pọ to ida mẹwaa ninu ẹgbẹrun mẹtadinlọgbọn ti wọn jẹ ajoji to n kọṣẹ ogun jija
"Nigba ti mo n jagun lọwọ, ara mi ti gan-nigba ti wọn si mu mi ko si ìbọ̀wọ́ kankan lọdọ mi mọ."Beverley lo ṣalaye nipa bo ṣe ṣèṣe bẹẹ pẹlu ede Russia to da ṣaka.
''Ẹsẹ la fi n rin, otutu si mu gidi.''
''Ara gigan ipele to le ju ni mo ni''. o ṣalaye.
Ọdun meje sẹyin ni wọn ran an lọ si Russia gẹgẹ bii ọmọ ologun kekere lati kẹkọọ nile ẹkọ ologun oju omi, o pada fẹ iyawo o si bimọ obinrin kan. Amọ o ko si iṣoro ọrọ owo, o si bẹrẹ si i ta oogun oloro to fidi pe o pari rẹ si ẹwọn ni Russia. Dipo ko ṣẹwọn ti wọn da fun un, wọn ni awọn yoo fun un lominira to ba le ka lọ soju ogun.
'Lati le tán ọran ti mo da, mo pinnu lati sin Russia, fun idi eyi, wọn ran mi,'' bẹẹ lo sọ fun mi.
Eto abẹwo awon akọroyin si agọ yii maa n waye l'Ọjọbọ to ba gbẹyin oṣu, gẹgẹ bi ọkan lara awọn eto nla ti Ukraine gbe kalẹ lati fi han pe wọn n tọju awọn ti wọn mu logun daadaa. Awọn alaṣẹ ibẹ ko ṣetan lati fun wa ni onka iye awọn to wa ninu agọ naa geerege, ju pe wọn kan sọ fun wa pe awọn Africa to wa nibẹ wa lati orile ede mẹẹẹdogun ọtọọtọ lọ.
Beverley ṣalaye pe ohun gbogbo lo n lọ bo ṣe yẹ pẹlu itọju oun:awọn dokita ni aanu, igbesi aye ninu agọ naa si da bii igba ti eeyan wa ninu iṣẹ ologun ni-o maa n suni.
Agọ awọn ti wọn mu logun ni Ukraine lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kọkanla, 2025. Aworan Getty.
Ṣugbọn o fi ironupiwada han lasiko ifọrọwanilẹnuwo rẹ- o bẹ awọn mọlẹbi ati orilẹede rẹ, eyi to ni ko gbe lẹyin ẹnikẹni ninu ogun naa lati fi ori jin oun. Ninu ohun gbogbo,o fẹ ki ogun naa pari.
“Igun mejeeji ti padanu pupọ-mo mọ bo ṣe n lọ, o lagbara gan-an.”
Lud Beverly
Ọmọ ogun ti wọn mu sẹwọn ni Ukraine
Awọn ti wọn mu logun
Gbogbo awọn ti wọn mu logun ti wọn gba lati ba wa sọrọ ni ero wọn lori ogun naa yatọ,ọpọ wọn sọ pe awọn fẹẹ pada si Russia lati ri i pe awọn ri owo ti wọn jẹ awọn gba-bẹẹ ni ko sẹni to fẹẹ pada soju ogun.
Nigba ti a kọkọ debẹ, òórùn ọbe kọkọ fi wa lọkan balẹ-a si darapọ mawọn ẹlẹwọn ti wọn wọṣọ ologun oju omi, ti wọn n to jẹjẹ lati gba ounjẹ ọ̀sán.
Lẹyin eyi ni wọn beere lọwọ awọn ẹlẹwọn boya wọn fẹ ba awọn akọroyin to waa ṣabẹwo sọrọ. Awọn ọmọ ilẹ Africa kan kora jọ si ẹyin ibi ti wọn maa n sun si: awọn to n da wa, wa lẹgbẹẹ kan, awọn ti wọn bẹ ti wọn si maa n sọrọ daadaa n ṣe awada, wọn n fi ara wọn ṣe yẹyẹ, bẹẹ ni awọn kan si wa ti wọn ko tilẹ le wo eeyan loju rara.
Ọkunrin kan bọ siwaju nigba to gbọ pe awọn BBC wa lara awọn to wa yii. O ṣalaye ara rẹ, o ni Richard Kanu lorukọ oun, lati Olu ilu Sierra Leone ti i ṣe Freetown.
O ni toun ba sọrọ ara oun bayii, yoo jẹ ọna kan fawọn ẹbi oun atawọn ọmọ oun mẹtẹẹta pe oun ṣi wa laye.
Ẹni ọdun mẹtalelogoji naa ti wa ni ipagọ yii fun ọdun kan, o si ti wa nigbekun Ukraine fun ọdun meji,
Gẹgẹ bo ṣe ri fun Beverly, oun naa ni ẹkọ ologun lati ibẹrẹ pẹpẹ-ṣugbọn o loun ko mọ nigba toun gba iṣẹ ọlọdẹ, pe oju oun loun yoo balẹ si.
O ti ṣiṣẹ nileeṣẹ ologun ilẹ Sierra Leone fun ọdun mẹtadinlogun, o n gba $100 loṣu kan. Idaamu abẹle laaarin ẹbi rẹ lo mu un kuro-ati erongba lati maa gbowo to pọju bẹe lọ, o fẹẹ lọ si Europe, o wa ọna lati lọ pẹlu iwe irinna ẹni to n lọ gba afẹ nibẹ lasan.
''Ọmọ mi obinrin fẹ di dokita.O wu mi ki n le sanwo ẹkọ rẹ ni yunifasiti, ko le baa mu ero ọkan rẹ ṣẹ,'' bẹẹ lo ṣalaye fun mi.
Gbogbo orilẹede to kọwe si fun fisa lo ja a kulẹ-afi Russia nikan. Nigba to de Russia ni 2024, o kan si Abaniwaṣẹ kan, o si ya a lẹnu nigba ti wọn sọ fun un pe wọn yoo fun un ni $15,000 lati tọwọ bọwe adehun iṣẹ ọlọdun kan, pẹlu owo oṣu $2,000, bo tilẹ jẹ pe ko le sọ ede Russia kankan. Bẹẹ ni wọn ṣe ran an lọ si Guusu ilu Rostov-on-Don, to to igba kilomita si ibi ti rogbodiyan wa ni Ukraine.
''Nigba ti mo de Rostov, agọ ologun kan ni mo ti ba ara mi'', o ṣalaye-o ni ẹnikan nibẹ sọ foun pe oun ti kọwọ bọwe adehun ọlọdun kan pẹlu ileeṣẹ ologun ilẹ Russia. O ni o ya oun lẹnu, ṣugbọn oun tu ara oun ninu, nigba to ti jẹ pe eyi yoo fun oun ni anfaani lati jẹ ọmọ orilẹ ede Russia.
''Lẹyin ọdun kan mi, ma a niwee ilu Russia pẹlu owo mi. Ma a ni anfaani lati ko ẹbi wa si Russia. Ma a si maa gbe igbesi aye to daa ni Russia.''
O ni ṣugbọn iwaju lewu gidi pẹlu imọ ẹrọ to ti tẹsiwaju gidi ni igun mejeeji. Awọn ẹlẹwọn kan ṣi n mọ ohun ti wọn koju bii irira lara wọn titi di bayii.
Ninu yara miran ti wọn n sun si, ẹlẹwọn ọmọ ilẹ Kenya kan, Kibet, kọkọ kọ lati bawa sọrọ, ṣugbọn nigba ti a fi ede Swahili ki i, ede ti emi maa n sọ, ara rẹ balẹ diẹ si i.
Ṣugbọn Kibet tun sẹraro nigba to gbọ nipa bawọn mọlẹbi ṣe n kaya soke to nile nipa iroyin awọn ti wọn fi ẹtan ko wọṣẹ ologun ni Russia, pẹlu ọna awuruju tawọn abaniwaṣẹ fi n gba wọn, ti wọn yoo ṣeleri owo nla fun wọn pe awọn yoo fun wọn niṣẹ ti araalu le ṣe, ti yoo si wa di pe wọn a pada ba ara wọn nibi ti wọn ti n jagun Russia ni.
Abọ iwadii Ukraine fi han pe awọn eeyan Kenya lo pọ ju ninu ọmọ ilẹ Africa ti wọn gba siṣẹ ologun ilẹ Russia-lẹyin naa lo kan Egypt, Cameroon, Ghana atawọn ọmọ Uganda.
''Oju ogun ki i ṣe ibi eré.Awọn eeyan n ku lọtun-un, losi ati aarin gbungbun.Ko si sẹni to kan,'' bẹẹ ni ẹni ọdun mẹrindinlogoji naa wi.
O ṣalaye bi ado oloro ti wọn ba ju latoke ṣe maa n pa ọpọ eeyan, ti oku eeyan yoo kunlẹ kaakiri kitikiti.
Awọn ṣọja yoo maa sun siwaju, wọn le ma le ṣeranwọ nigba mi-in, wọn si le ṣai lagbara ati ṣeranwọ.
O nawọ si ọmọ Kenya kan fun ikọ BBC,to wa ni yara miran, o ni o ṣee ṣe kiyẹn fẹẹ sọrọ niwaju kamẹra.
Willy Macharia ni tiẹ fi idunnu rẹ han lati sọrọ ko too lọ jẹ ounjẹ ọsan: Ounjẹ pọ nibi. Mo le jẹun to ba ya.''
Oju kan ti mo da mọ ni, nitori ẹni ọdun mẹtalelogun naa maa n han gan-an lori ayelujara, to maa n kilọ fawọn ọdọ Kenya lati ma ṣe darapọ mawọn.
Nigba ti mo beere lọwọ rẹ nipa eyi, o ni awọn ṣọja Ukraine lo fipa mu oun lati ya awọn fidio naa.
Mo pada beere lọwọ Petro Yatsenko, agbẹnusọ fun riri si ọrọ awọn ologun ẹlẹwọn ni olu ileeṣẹ wọn ni Ukraine, ṣugbọn o sọ pe ko sohun to jọ bẹẹ.
Macharia sọ pe agbegbe ogun loun wa fun oṣu mẹta, ti wọn fa oun soju ogun pẹlu adehun owo nla ati anfaani lati le tẹsiwaju ninu ẹkọ oun. Ṣugbọn o n ṣọra lati ṣalaye bi wọn ṣe gba a siṣẹ ologun gan-an: ''Russia ni mo n ja fun, bi mo ṣe wa ni Ukraine yii tumọ si pe ọwọ ọta ni mo wa."
Lati le maa ri nnkan fi asiko rẹ ṣe ninu agọ yii gẹgẹ bii awọn ẹlẹwọn yoku, o maa n ṣe awọn iṣẹ keekeeke lati rowo to le na nibudo itaja kekere kan ti wọn ti n ta nnkan jijẹ, ọsẹ ati ṣuga.
O tun n kọ ede Ukraine nile ikawe awọn ẹlẹwọn, nitori o fẹẹ mọ awọn nnkan to ba n ṣẹlẹ layika rẹ.Ọdọkunrin yii n wa ọna ti yoo fi gba ominira, o si nireti pe orukọ oun ko ni i pẹ wa lara awọn ti wọn yoo fi ṣe paṣi-paarọ, koun le pada si Russia.
Ṣugbọn Yatsenko, lati ibudo awọn ologun ẹlẹwọn yii, ko ri i daju pe iru paṣi-paarọ yii le waye.Titi dasiko yii, gẹgẹ bi Yatsenko ṣe wi,Ghana nikan ni ilẹ Africa to ṣi fi erongba rẹ lati ko awọn ologun ẹlẹwọn wọn wale. Pẹlu bawọn aṣoju wọn ṣe n bẹ agọ naa wo, ti idunaa-dura lori ati gba wọn silẹ si n lọ lọwọ.
“Lọwọlọwọ, awọn ilẹ Africa ko lọwọ si paṣi-paarọ yii. Wọn fẹ ki wọn fawọn paarọ fun Russia nitori owo ni.Ṣugbọn a ko ti i ri nnkan kan latọdọ Russia lati gba wọn pada.”
Petro Yatsenko
Agbẹnusọ to n ri si bi wọn ṣe n tọju awọn ẹlẹwọn ti wọn mu logun ni Olu ileeṣẹ wọn ni Ukraine
Mo tun fọrọ wa Minisita fun ọrọ ilẹ okeere ni Ukranine, Andrii Sybiha, lẹnu wo, ẹni to ri awọn ọmọ ilẹ Africa to n wọnu ogun yii bii ẹtan ti Russia fi tan wọn wa lọna ti lodi sofin.
''Nigba mi-in, wọn maa n pe wọn lati waa kẹkọọ ni Russia wọn yoo si balẹ soju ogun lojiji,'' o ṣalaye bẹẹ fun mi.
Minisita naa sọ pe awọn ajoji le jagun bi ikọ ologun Ukraine naa-amọ o ni tawọn yatọ si ti Russia, ilana ti wọn fi n darapọ mọ ti Ukraine jẹ ilana to ba ofin mu, eyi to ti ọkan eeyan wa ti ohunkohun ko si ruju nipa rẹ bo ṣe sọ. Ko sọ onka tabi ohunkohun nipa awọn ajoji to wa nibẹ.
Awọn to tajo de
Eeyan pupọ kọ lo le pada wale. Ṣugbọn Duncan Chege, ọmọ ilẹ Kenya,de ni tiẹ. O sa kuro nileewosan ti wọn ti n tọju rẹ lẹyin to dibọn bii pe o ni arun ọpọlọ nigba to wa ninu ikọ ologun ilẹ Russia.
Fun Chege, o pinnu lori ileri owo nla ti wọn ṣe fun un pe yoo maa gba. Lẹyin ti ko riṣẹ ni Dubai latari iṣoro fisa, ileeṣẹ to gba a sisẹ gba a nimọran lati gbiyanju Russia wo, nibi to ti ri fisa gba laaarin ọsẹ kan.
Aworan to wa latọwọ Duncan Chege
Lati rowo lọ si irinajo naa, iya rẹ yawo lọwọ awọn araale atawọn ẹbi, o si kaju owo abaniwaṣẹ ati owo tikẹẹti irinajo alọ nikan.
Duncan Chege
Sibẹ, ohun ti yoo ṣẹlẹ sawọn ologun ẹlẹwọn ilẹ Africa yii ko ti i foju han.
IGBORIYIN FUN
Onkọtan: Sammy Awami, To n jabọ iroyin lati Iwọ-Oorun Ukraine
Olootu ati akọroyin to ya fidio: Hassan Lali
Agbekalẹ ati aworan òde: Mille Wachira
Oludara iwaju:Mayowa Alabi
Aworan to ṣe apẹẹrẹ: George Wafula
Awọn aworan: Ukraine(Getty), Sierra Leone ati Kenya (Sammy Awami ati Hassan Lali)
Oluyẹwo ọrọ: Lucy Fleming ati Victor Oluoch
Olootu ati oluyẹ fidio wo:Kathy Harcombe
Olootu oju ewe:Dorothy Otieno
Afikun iranwọ:Shalom Olatunji, Brian Osweta,Njoroge Muigai, Boaz Ochieng ati Damilola Ojetunde
Ọjọ agbejade: ọjọ kẹrin oṣu Kẹfa 2026

