Super Falcons bẹ̀rẹ̀ ìlépa fún ife ẹ̀yẹ Wafcon fún ìgbà kọkànlá, àwọn tí wọ́n jọ ń kópa ní àwọn ló kàn

Ikọ agbabọọlu Super Falcons orilẹede Naijiria n yọ ayọ aṣeyọri nigba ti wọn gba ife ẹyẹ idije WAFCON lọdun to kọja.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Naijiria ti gba ife ẹyẹ naa ni igba mẹwaa ninu mẹtala to ti waye, ọdun 1998 ni idije ife ẹyẹ awọn obinrin agbabọọlu ilẹ Africa ti a mọ si Women's Africa Cup of Nations (WAFCON) bẹrẹ.
    • Author, Emmanuel Akindubuwa
    • Role, BBC Sport Africa, Lagos
  • Published
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Orilẹede Naijiria ti balẹ si orilẹede Morocco fun idije ẹyẹ awọn obinrin ilẹ Africa ti ọdun 2026 eyi ti a mọ si Women's Africa Cup of Nations (WAFCON). Ero ọkan wọn bi wọn ṣe n debẹ naa ni lati tun gba ife ẹyẹ naa bii ìṣe wọn.

Tẹ o ba gbagbe, Naijiria ti gba ife ẹyẹ naa ni igba mẹwaa, eyi ti wọn gba kọja waye ni Morocco, ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn pe ni "Mission X" - awọn ọmọbinrin agbabọọlu orilẹede Naijiria lo wa nipo ẹni to mọ bọọlu u gba julọ nilẹ Africa labala awọn obinrin bayii.

Ipenija to wa niwaju wọn bayii ni bi wọn ko ṣe ni i jẹ ki ade iyi ti wọn gba naa ṣi mọ wọn lori, bi ife ẹyẹ naa ko ṣe ni i bọ mọ wọn lọwọ.

"Nisinyi to jẹ awa ni olubori wọn, awọn ikọ yoku yoo fẹẹ fa wa jabọ ni"

Bẹẹ ni Justin Madugu, olori akọnimọọgba ikọ Super Falcons wi fun BBC Sport Africa.

"Ki i ṣe ohun to maa rọrun, awa naa mọyẹn, a si maa gbaradi digbi ni."

Ọjọ Iṣẹgun ni Naijiria yoo bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ tirẹ ninu idije ọdun 2026 yii, nigba ti yoo koju Malawi to n kopa ninu idije naa fun igba akọkọ, ki wọn too koju Zambia ati Egypt ni isọri C.

"Gbogbo orilẹede lo fẹ na Naijiria, idi niyẹn ti a fi gbọdọ fi kun ipá wa nipa gbigbaradi ju ti tẹlẹ lọ" Ann Chiejine, Igbakeji akọnimọọgba Super Falcons lo sọ bẹẹ.

Nipa awọn agbabọọlu obinrin Naijiria yii, awọn orukọ to ta lẹnu to si gbajumọ nilẹ Africa ni ikọ naa ko sinu.

Balogun wọn, Rasheedat Ajibade, ni wọn fun ni ami ẹyẹ agbabọọlu to daa ju ninu idije ọdun to kọja. Chiamaka Nnadozie, amule wọn lọwọlọwọ ni wọn fun ni amule to peregede ju lọdun naa.

Bakan naa ni Asisat Oshoala to ti gba ami ẹyẹ agbabọọlu ilẹ Africa fun igba mẹfa ko gbẹyin ninu ikọ Super Falcons.

Amọ Madugu tun ṣetan lati fi awọn ọdọ agbabọọlu obinrin kan kun wọn, atamatase; Joy Omewa, wa ninu wọn, ẹni to n gba bọọlu nilẹẹ Sweden, to si ba wọn yọ ninu idije ti ọdun to kọja lati ilẹ okeere to wa.

'Ẹ̀rù ò b'odò'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lara awọn orilẹede mẹta to ṣee ṣe ki wọn gba ife ẹyẹ WAFCON yii ni Naijiria wa.

Super Falcons ti gbayi to bẹẹ ninu idije yii, debi pe wọn ti gba ife ẹyẹ naa fun igba mẹwaa ninu mẹtala to ti waye.

Ọdun 1998 ni idije WAFCON bẹrẹ, orilẹede Equatorial Guinea (2008 ati 2012) ati South Africa to gba a ni 2022 nikan lo gba ife ẹyẹ naa mọ Naijiria lọwọ ri.

Wayi o, awọn ti wọn jọ n kopa ti ni nnkan ti yatọ, idije naa si ti le ju ti tẹlẹ ti Naijiria n gba a bii ẹni ṣere lọ.

Koda, wọn ti di ikọ mẹrindinlogun bayii, dipo mejila to maa n dije tẹlẹ.

Ohun kan to tun yipada ninu idije WAFCON bayii ni pe bi awọn akopa ba ṣe ṣe si ni yoo sọ ikọ ti yoo pegede fun idije awọn obinrin agbabọọlu lagbaaye (Fifa Women's World Cup) ti yoo waye ni Brazil lọdun to n bọ, ikọ mẹrin to ba yege de ipele to kangun si aṣekagba yoo lọ si Brazil.

"Afojusun wa akọkọ ni lati yege fun idije Ife Ẹyẹ Agbaye. Lẹyin iyẹn ni a le maa ronu nipa bi a ṣe maa da aabo bo awọn ami ẹyẹ ti a ti gba. Ẹru kankan o ba wa, bẹẹ ni ẹnikẹni ko le wa lere, a le koju ikọ yowu kari ilẹ Africa."

Francisca Ordega to n gba igun iwaju lo ṣalaye bẹẹ fun BBC Sport Africa.

Ni ti idije ife ẹyẹ awọn obinrin agbaye, Naijiria ti ṣoju Africa ni igba mẹsan-an to ti waye latigba ti wọn tẹ pẹpẹ akọkọ rẹ ni China ni 1991.

Ni 2023, orilẹede mẹrin rin irin ajo lọ si Australia ati New Zealand, Iwọ-Oorun Africa pẹlu South Africa ni, ati Morocco pẹlu Zambia to kopa fun igba akọkọ.

"Ọjọ wa ti pẹ, bi wọn ba n fi pẹnariti na wa bayii pẹlu ami ayo kan si odo, meji si odo, o fi han pe o ti n ga ju ti tẹlẹ lọ niyẹn."

Bẹẹ ni Cheijine wi nigba to n ṣalaye bi ayipada rere ṣe n ba ifẹsẹwọnṣe ninu idije ilẹ Africa.

Ni Morocco bayii, orilẹede Cape Verde ati Malawi ni wọn jẹ akopa fun igba akọkọ ninu idije WAFCON.

Ni ti ajulọ, Malawi wa ni ipo153 lagbaaye, Naijiria wa nipo kẹrindinlogoji (36th), amọ ikọ agbabọọlu ti a mọ si Scorchers naa n leri pe awọn yoo ṣe bẹbẹ ninu idije yii.

Wọn ni awọn tẹgbọn-taburo; Tabitha ati Temwa Chawinga yoo mu nnkan nilẹ pẹlu awọn ti wọn ba koju.

Ẹgbọn ni Tabitha, oun lo ju awọn ami ayo kan sawọn to gbe Lyon ga ninu idije France ni saa to kọja.

Temwa to jẹ aburo ti gba ami ẹyẹ bọọlu wura (National Women's Soccer League Golden Boot ati ti MVP, ninu ifẹsẹwọnsẹ rẹ ni saa meji to ṣe pẹlu Kansas City.

Awọn ti Naijiria yoo tun ni lati ro tiwọn mọ ọn ninu idije yii ni Zambia, pẹlu awọn agbabọọlu meji wọn kan ti wọn ni iriri iṣẹ naa pupọ.

Awọn ni atamatase Barbra Banda ati Racheal Kundananji, tawọn mejeeji tun n gba bọọlu lorilẹede America.

"Ko sẹni to ṣee foju parẹ tabi ka si yẹpẹrẹ."

Madugu lo wi bẹẹ lọjọ to ku ọla ti ifẹsẹwọnsẹ wọn yoo waye, bẹẹ ni Ajibade sọ pe bi Malawi ṣe wa kopa yii fi han pe awọn naa ti n tẹsiwaju.

Akojọpọ awọn ọdọ agbabọọlu atawọn to ti ni iriri iṣẹ bọọlu afẹsẹgba

Asisat Oshoala, wọṣọ alawọ ewe ti wọn kọ nọmba kẹjọ si. O kun irun ori rẹ ni ọda pupa, o n sare si bọọli lorii papa, awọn ikọ alatako meji wa lẹyin rẹ, ọ̀kan n sare bọ niwaju.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Asisat Oshoala to ti gba ami ẹyẹ agbabọọlu ilẹ Africa fun igba mẹfa yoo kopa ninu idije WAFCON 2026 ni Morocco

Tẹlẹ ni Naijiria ko ni akoko to to lati fi gbaradi fun WACON,lọtẹ yii Madugu atawọn oṣiṣẹ rẹ ti ni anfaani lati gba awọn ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹẹ-sọrẹẹ kan ti yoo ṣe iranwọ.

Ṣaaju ni wọn koju Cameroon, wọn ṣe pẹlu Senegal wọn si bori Tanzania lọsẹ to kọja.

Bakan naa ni awọn ọdọ ẹlẹjẹ tutu kan ti darapọ mọ Super Falcons, bii Comfort Erhabor, amule ẹni ọdun mọkanlelogun ti yoo maa ran Nnadozie lọwọ, bi Madugu ṣe to o.

Netherlands ni wọn ti bi Erhabor, England ni wọn ti tọ ọ, ikọ Cameroon lo kọkọ ba fẹsẹwọnsẹ fun igba akọkọ rẹ nita gbangba.

"Igbagbọ ti Madugu ni ninu awa ọdọ agbabọọlu jẹ ohun ti mo bọwọ fun pupọ.

"Mi o mọ pe mo le tete darapọ mọ ikọ naa kiakia bẹẹ. Amọ wọn gba mi tọwọtẹsẹ."

Bẹẹ ni Comfort Erhabor wi.

Lọwọlọwọ yii, o n kopa nipele kẹta ikọ agbabọọlu ti a mọ si English football, ni Portsmouth, ilu kan ti ko ju irin wakati kan lọ si Brighton, nibi ti Nnadozie ti n gba bọọlu jẹun.

O ṣapejuwe Nnadozie bii "ẹgbọn agba lobinrin" , ẹni toun maa n ba ṣe faaji, toun ko si ni i ro o lẹẹmeji koun too sun mọ ọn fun idanimọ agbaye.

"O wa ninu ẹjẹ mi, mo si ro o pe oore ti mo le ṣe ju ni lati ṣoju orirun mi, ki n si mu ori awọn obi mi wu pẹlu.

"Mo fẹran aṣa naa, nnkan kan to si tun tobi loju mi ni bi kaluku ṣe tẹwọ gba ẹsin Kristẹni nibi, tori mo gba pe yoo jẹ ki n le gbe igbagbọ mi wa sinu ikọ naa, ki n si le fi ara mi han."

Comfort lo ṣalaye siwaju bẹẹ si i.

Bi Madugu ṣe n wa awọn ọdọ to tun ni iriri ati imọ bọọlu afẹsẹgba, Omewa ṣapejuwe rẹ bii wura.

"Bi ko ba si wọn, a ko le wa nibi lonii.

Ẹlẹsẹ ayo atamataṣe; Oshoala, wa lara awọn ti Omewa dupẹ lọwọ rẹ.

Ki i ṣe gbogbo awọn agbabọọlu Super Falcons ti wọn lorukọ lo peju lọtẹ yii, Ashleigh Plumptre to kopa to jọju lọdun to kọja ko si nibẹ lọtẹ yii, nitori ifarapa ẹsẹ to ni.

Bakan naa ni ikọ yii koju ole to ja wọn nigba ti wọn de si Morocco, iroyin sọ pe Esther Okoronkwo, padanu ọpọlọpọ dọla ti wọn ji lọ.

Nipa owo ti wọn yoo gba, wọn ti ṣe afikun ti ọdun yii.

Ikọ to ba jawe olubori yoo gba $2m (£1.5m) - eyi to ṣafihan bi igbega ṣe n ba idije ife ẹyẹ awọn obinrin Africa.

Amọ bi idije naa ṣe n gunke agba to, bẹẹ ni ikọ Naijiria jẹ eyi ti orilẹede gbogbo fẹẹ fẹyin rẹ janlẹ.