Ilé tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń gbé dàwó, èèyàn méjì kú, mẹ́ta dèrò ilé ìwòsàn

Wọn ti ri oku ọdọbinrin kan yọ labẹ ile to dawo ni Amokpala, Oko, to wa ni ijọba ibilẹ ariwa Orunmba, nipinẹ Anambra.
Iku ọdọbinrin naa waye lẹyin ti ilegbe awọn akẹkọọ ti orukọ rẹ n jẹ Elite Five Star lodge ṣadede dawo lalẹ ọjọ Aiku.
Awọn adoola ẹmi tun sọ pe awọn ri oku ọdọkunrin mii yọ ti igbagbọ wa pe o jẹ akẹkọọ.
Ile ọhun, ni a gbọ pe ọpọlọpọ awọn akẹkọọ Federal Polytechnic Oko n gbe ṣaaju iṣẹlẹ naa.
Akojọpọ awọn adoola ẹmi lati ajọ Red Cross, NEMA, ileeṣẹ adoola ẹmi ipinlẹ Anambra, SEMA, ileesẹ panapa, ileeṣẹ ọlọpaa atawọn adoola ẹmi miran ni wọn wa nibẹ.
Awọn irinṣẹ nlanla ti wọn n lo lasiko ti ile ba dawo ni wọn si fi n ṣiṣẹ adoola ẹmi nibẹ pẹlu.
Ọpọlọpọ awọn ero adugbo atawọn akẹkọọ lo ko ara wọn jọ sibẹ lati wo bi iṣẹ ṣe n lọ.
Arabinrin to gbẹnusọ lorukọ SEMA, Ndidi Omega, fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni awọn ti ri oku ọdọbinrin kan nibẹ ti oku ọdọkunrin mii ṣi ha sabẹ ile ọhun nigba ti wọn ti ko eeyan mẹta ti wọn farapa lọ sile iwosan.
"Ko si akẹkọọ wa kankan to ku ninu ile naa"

Wayi o, awọn alasẹ ile ẹkọ Federal Polytechnic, Oko ti sọ pe ko si eyikeyi ninu akẹkọọ wọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Aje, agbẹnusọ ile ẹkọ naa, Ọmọwe Oguegbu Celestine Udoka, lo fidi ọrọ naa mulẹ.
Wọn ni pupọ ninu awọn akẹkọọ wọn lo ti pada sile wọn lẹyin idanwo saa keji ẹkọ.
Lẹyin naa ni wọn ke si awọn araalu ki wọn maṣe naani iroyin ẹlẹjẹ to gba igboro kan pe awọn akẹkọọ wọn wa lara awọn ti wọn ku ninu iṣẹlẹ naa.
Ṣaaju ni adari ile ẹkọ ọhun, Ọmọwe Chioma Irene Awuzie, ti kọkọ ṣabẹwo sibẹ lati wo bi nnkan ṣe ri.




























