Wo àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ láti kékeré tí àyẹ̀wò DNA sọ pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni wọ́n

Meena ati Minal jẹ ọrẹ meji ti obi ọtọọtọ gba tọ lati kekere, ṣugbọn ibi ti wọn n gbe ko jina si ara wọn ni orilẹede Netherlands. wọn pade lẹynin ti ayẹwo DNA fihan pe ọmọ iya ati baba kan naa ni wọn.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Meena Geltink ati Minal Tijssen paàdé nínú oṣù Kẹjọ lẹ́yìn tí àyẹ̀wò DNA sọ pẹ ọmọ bàbá kan náà ni wọ́n
    • Author, Geeta Pandey
    • Role, Women Affairs Editor, India
  • Published
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Titi di asiko yii ni iṣẹlẹ naa ṣi n jẹ kayeefi fun awọn eeyan, paapaa awọn obinrin meji to ṣẹlẹ si, to si fẹẹ dabi fiimu agbelewo ti Bollywood.

Awọn obinrin India meji kan ti wọn ṣẹṣẹ le logoji ọdun ni wọn ṣẹṣẹ mọ pe ẹgbọn ati aburo ni awọn.

Awọn mejeeji yii ni wọn gba tọ lati kekere lọtọọtọ, to si tun jẹ pe ile awọn to gba awọn mejeeji tọ ni orileede Netherlands ni ko jinna sira wọn.

Meena Geltink ati Minal Tijssen, ni wọn bi laaarin ọdun 1980s, ti wọn si gbe wọn lọ sile awọn ọmọ alailobi meji ọtọọtọ ni ẹkun Ila Oorun India to wa ni Mumbai, iyẹn laaarin oṣu ti wọn bi wọn tan.

Nigba ti wọn kọkọ pade ara wọn nibi akanṣe eto kan ti awọn alakoso ibi ti awọn obi wọn gbe wọn lọ, niṣe ni awọn mejeeji nifẹ ara wọn, paapaa julọ nigba ti wọn rii pe awọn jọ ara wọn, ti wọn si tun ni irori kan naa.

Meena, to ti pe ọdun mẹtalelogoji bayii ranti ọjọ naa daadaa. "Ọjọ Abamẹta bi wọn fi eto naa si fun awọn mọlẹbi to ba fẹẹ gba ọmọ tọ. Ni irọlẹ ọjọ Ẹti, gbogbo awọn ọmọ ti wọn gba tọ ni wọn ko papọ lati ni ibaṣepọ to dan mọnran, lati tun jọ jẹ ounjẹ alẹ."

Awọn mejeeji, Meena ati Minal wa pẹlu awọn ọrẹ wọn ti wọn jọ wa papọ, lẹyin ti wọn ṣakiyesi pe awọn mejeeji ni afijọ.

"Wọn sọ pe ẹ wo ara yin ninu digi. Iyalẹnu lo jẹ fun mi, ẹnu ya mi gidi, nitori pe iru imu ti mo ni, loun naa ni. a tun jọ n rẹrin bakan naa. Nibi ounjẹ alẹ, mo n wo o leralera," Meena sọ fun BBC ni ile rẹ to wa ni Netherlands.

Lọjọ keji, awọn ọmọbinrin naa gba ẹrọ ibanisọrọ ara wọn ati adirẹẹsi ile ti wọn n gbe, lati le jọ maa ba ara wọn sọrọ.

Bo tilẹ jẹ pe ko si nnkan to jọ pe wọn ẹjẹ kan naa lo pa wọn pọ, ẹsẹkẹsẹ ni wọn ti bẹrẹ sii ni ibaṣepọ. Fun ọpọlọpọ ọdun, wọn kọ iwe sira wọn, ti wọn si n pe ara wọn ni ọrẹbinrin mi "nitori pe a fẹẹ bẹẹ".

Wọn kọ iwe nioa ile-ẹkọ, awọn ọrẹ, ọkunrin, jijade lati jo. Wọn sọ funra wọn nipa irufẹ ere idaraya ti wọn fẹran, bẹẹ si ni wọn sọrọ nipa orin, ti wọn si tun ṣakiyesi pe ohun ti wọn fẹran jọra wọn.

Ṣugbọn ni ọdun mẹẹdogun sẹyin, wọn ko gburo ara wọn mọ. Meena - to ti jẹ iya ọlọmọ mẹta bayii - sọ pe nigba toun ti bi ọmọ akọkọ loun ko ti raaye mọ. Bẹẹ ni Minal lọ si France.

Meena ati Minal jẹ ọrẹ meji ti obi ọtọọtọ gba tọ lati kekere, ṣugbọn ibi ti wọn n gbe ko jina si ara wọn ni orilẹede Netherlands.

Oríṣun àwòrán, Meena Geltink

Àkọlé àwòrán, Minal ati Meena nigba ti wọn kọkọ pade, ti wọn si di ọrẹ timọtimọ.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni ọdun 2017, Meena tun lọ si ipade miran to jẹ ti awọn to n gba awọn ọmọde tọ lati India, nibi to ti gbọ nipa ayẹwo DNA, to si pinnu lati ṣe ayẹwo naa.

Fun bii ọdun mẹwaa, ko ri ẹnikẹni to ni afijọ pẹlu, ṣugbọn ni ọdun yii, Meena yọ aapu (App) naa kuro lori ẹrọ ibanisọrọ rẹ nitori ko si aye pupọ lori rẹ mọ.

"Logunjọ, oṣu Karun-un, mo gba atẹjiṣẹ ori ikanni Facebook lati ọdọ Minal. Njẹ o ranti mi? o beere bẹẹ. O ti ṣe ayẹwo kan ninu oṣu Kẹrin nigba to n ṣabẹwo sọdọ awọn obi rẹ ni Netherlands. O si tun ti fi esi naa pamọ sori foonu rẹ."

"Mo pada fi aapu (App) naa sọri foonu mi. O fẹẹ ba mi lọkan jẹ nitori pe nnkan ranti nọmba afipamọ mi mọ, fun igbamẹwaa ni wọn fi gbiyanju rẹ, ki n too wọle."

Esi ayẹwo naa kọkọ ru mi loju gidi - ida ọgọrun ni ayẹwo naa fi jọ ara wọn."

"Mo ni ojulowo arabinrin temi, leyi to jẹ pe baba ati iya kan naa lo jọ bi wa.

"Niṣe lo dabi nnkan ti wọn ta kiji si lojiji. Mo sunkun. Minal naa ni ohun ti mo ti n duro tipẹ fun. a ti n pe ara wa ni arabinrin. Ayẹwo DNA ṣafihan wi pe ohun ti a n ri lati ọdun pipẹ sẹyin jẹ otitọ."

Awọn ọrẹ atijọ naa pade gẹgẹ bi arabinrin fun igba kọkọ ni ọjọ kan ninu oṣu Kẹjọ ni ibudokọ.

"O jẹ ohun iyalẹnu. O dabii pe eeyan pada sile lati ọdun pipẹ. Fun ọpọlọpọ ọdun ni emi pẹlu Minal fi ni iho nla kan ninu ọkan wa. A wa lero wi pe ni bayii, a ti pe. Ohun gbogbo ti wa dabi pe nnkan ti pada bọ sipo to yẹ ko wa," Meena sọ bẹẹ.

Nigba to n sọ nipa imọlara pipade lọna ọtun, Reuters sọ pe "omije, didi mọ ara ẹni ati ẹrin lo pade bi wọn tun ṣe pada foju kan ara wọn.

MInal, ẹni ọdun mẹrinlelogoji, to n gbe ni France pẹlu ọkọ rẹ ati awọn ọmọkunrin rẹ meji, sọ fun awọn alakoso wi pe nigba ti ayẹwo DNA rẹ jade ninu oṣu kẹrin, o loun ko lero wi pe ẹni ti awọn jọ kọkọ pade nigba ti awọn wa ni ọjẹwẹwẹ, ni ọgbọn ọdun sẹyin le wa a jẹ ibatan oun.

O wa bẹrẹ sii wọ mi lọkan nigba ti mo lọ bẹrẹ sii wo awọn aworan rẹ lori ayelujara. "Mina: Arabinrin mi. Nko le gbagbọ. A ti jẹ ọrẹbinrin timọtimọ ko too di pe a di mọlẹbi. A ti jọ wa lati ọdun pipẹ, ṣugbọn a ko mọ," o sọ bẹẹ.

Meena ati Minal jẹ ọrẹ meji ti obi ọtọọtọ gba tọ lati kekere, ṣugbọn ibi ti wọn n gbe ko jina si ara wọn ni orilẹede Netherlands. wọn pade lẹynin ti ayẹwo DNA fihan pe ọmọ iya ati baba kan naa ni wọn.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Meena ati Minal wo aworan ara wọn nigba ti wọn wa ni kekere

Meena ati Minal ni awọn tọkọtaya meji ọtọọtọ lati Dutch tẹwọgba nile awọn ọmọ alailobi meji ọtọọtọ.

Meena sọ pe inu abule kekere kan loun dagba si ni Netherlands lọdọ awọn obi ti wọn fi ifẹ han. "Awọn obi mi jẹ olukọ nile ẹkọ aladani. Koda, wọn tun jẹ olukọ mi nile ẹkọ. Wọn fi ifẹ nla han si ni, wọn si ṣee gbẹkẹ le."

Ọdun diẹ sẹyin ni baba rẹ jade laye, ṣugbọn inu abule naa ni mama rẹ ṣi n gbe. "Ojoojumọ la maa n sọrọ. Iya mi ṣi jẹ ibi aabo fun mi," o sọ bẹẹ.

Lọdun 2003, nigba ti Minna pe ọmọ ọdun mọkandinlogun, o lọ ṣabẹwo sile awọn alailobii naa to wa ni Mumbai pẹlu awọn obi rẹ, ati aburo rẹ ọkunrin ti wọn gba oun naa tọ ni Goa.

Wọn lo ọsẹ meji lati fi yẹ gbogbo iwe akọsilẹ wo, nigba ti wọn n gbiyanju lati mọ ojulowo awọn obi Meena, "nitori pe o ṣe pataki fun i lati mọ ibi ti mo ti wa, taani mama mi, ṣugbọn awọn alakoso ile alailobii naa ko nii fi ẹri wọn sita," o sọ bẹẹ.

Meena ati Minal jẹ ọrẹ meji ti obi ọtọọtọ gba tọ lati kekere, ṣugbọn ibi ti wọn n gbe ko jina si ara wọn ni orilẹede Netherlands.

Oríṣun àwòrán, Meena Geltink

Àkọlé àwòrán, Minal ati Meena nigba ti wọn wa ni ọjẹwẹwẹ ni ọdun 1990s

Lati inu oṣu Karun-un, Meena ati Minal ti n ba awọn sọrọ. Wọn ti pade ọkọ ara wọn, awọn ọmọ wọn, awọn obi ati aburo wọn.

"Gbogbo eeyan lo n rii pe ọrọ kan naa lo n jade lẹnu wa, bi a ṣe n gbe ori wa, ati bi a ṣe n rin lo jọ ara wọn," o sọ bẹẹ.

Wi pe wọn jẹ tẹgbọn-taburo ṣi n jẹ kayeefi, gẹgẹ bi Meena ṣe sọ, pẹlu afikun wi pe gbogbo nnkan ti wọn ti padanu sẹyin ni wọn gbọdọ gbiyanju lati ṣe atunṣe si.

"Nigba miran, a maa sọrọ fun wakati meji ti a ko si nii mọ, lojiji la ma ṣẹṣẹ ranti pe a ni lati llọ gbe awọn ọmọ wa nile-ẹkọ, ti a si maa ran nnkan."

Meena sọ pe ohun kan ti oun ati aburo rẹ maa fẹran lati ṣe ni lati pada sibi ti gbogbo nnkan ti bẹrẹ lati ibẹrẹpẹpẹ.

"O maa wu wa lati lọ si India nigba kan, ka rin kaakiri ilu Mumbai papọ.

"Awọn igba kan wa to jẹ pe awa mejeeji lero wi pe a ko ni ẹnikan, paapaa nigba ti mo padanu baba mi nipasẹ ijakulẹ ọkn. Mo kabamọ wi pe a ko si papọ. Niṣe lo yẹ ka jọ pin idunnu, ka jọ maa ran ara wa lọwọ lasiko iṣoro ati ipenija."