Ladi Adebutu ló wọlé ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun lọ́dún 2023 àmọ́ mi ò ní ẹ̀rí fún-un - Iyabo Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Chazi Photograffy
Oludije sipo sẹnetọ laaarin gbungbun ipinlẹ Ogun, Iyabo Obasanjo ti ṣalaye idi to fi oun fi n ṣe atilẹyin fun oludije sipo gomina ni ipinlẹ naa lẹgbe oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Ladi Adebutu ati idi ti oun naa fi pada sinu ẹgbẹ naa.
Obasanjo ni igbesẹ naa ko ṣeyin pe Ladi Adebutu ni o wọle ibo sipo gomina ipinlẹ Ogun nibi eto idibo ọdun 2023.
O ni bi o tilẹ jẹ pe oun ko ni ẹri fun eyi, ọpọ eeyan lo sọrọ si oun lọwọ ati pe oun kii ṣe ọmọde ninu oṣelu ipinlẹ Ogun.
Nigba ti BBC News Yoruba beere lọwọ Iyabo Obasanjo idi to fi pada n du ipo sẹnetọ lẹyin to ti ṣaaju sọ pe oun ko ni du ipo naa mọ pe ipo gomina lo wu oun lati lọ fun, o sọ pe Ladi Adebutu lo sọ fun oun pe ọna kan gboogi ti oun fi le ṣe atilẹyin fun oun nibi eto oṣelu to n bọ ni lati ri daju pe oun naa kopa ninu idije naa.
O ni idi niyi ti oun fi gba lati dije dupo naa ati pe awọn erongba Ladi Adebutu jọ mọ awọn afojusun oun fun ipinlẹ Ogun, ti oun si mọ pe ajọṣepọ awọn maa mu ilọsiwaju ba ipinlẹ Ogun.
O fi kun pe lati igba ti awọn eeyan ti sọ fun oun lati pada sinu oṣelu ni oun ti sọ pe ipo ti oun ti le ṣe anfaani fun gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun lo wu oun lati dupo le lori, eyi to fa a to fi jẹ pe ipo gomina ni oun kọkọ du nigba naa.
Nigba to n sọrọ lori idi to fi fẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC silẹ, o sọ pe oun kọwe ranṣẹ si ẹni ti ẹgbẹ fa kalẹ lati fi ki i ku oriire to si pe oun si ipade lati jọ jiroro.
O ni gbogbo nnkan ti awọn jọ jiroro le lori ni ko muṣẹ ati pe niṣe ni wiwa ninu ẹgbẹ oṣelu APC dabi ẹni pe oun kan n ti ara oun mọ wọn lọrun ni nitori oniruuru iwọsi ni wọn fi lọ oun ki oun to kuro.
Obasanjo ni gbogbo awọn nnkan yii ni oun ro papọ ti oun fi kuro ninu ẹgbẹ naa.
O sọ pe idi ti oun fi yan ẹgbẹ oṣelu PDP ko ṣeyin pe ọpọ ẹgbẹ lo kọwe ranṣe si oun nigba ti oun fi APC silẹ ṣugbọn nigba ti oun jọ gbogbo awọn ẹgbẹ naa wo, oun ri pe PDP nikan lo ni gbongbo, to si rẹsẹ walẹ ati pe oludije sipo gomina lẹgbẹ naa jẹ ẹni to ni afojusun to dara fun ipinlẹ Ogun.
Lori ẹsun to fi kan pe Ladi Adebutu lo wọle ibo gomina nipinlẹ Ogun lọdun 2023, Obasanjo ni gbogbo awọn to tu aṣiri naa fun oun ni oun maa fi orukọ wọn lede ninu iwe ti oun yoo kọ nigba ti baba oun, Olusegun Obasanjo ba pe ẹni aadọrun-un ọdun lọdun 2027.

























