Àwọn agbébọn ṣíná ìbọn bolẹ̀ nígboro South Africa, èèyàn méjìlá kú, mẹ́sàn-án farapa

Oríṣun àwòrán, Reuters
O kere tan, eeyan mejila lo di oloogbe lojiji lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹsan-an oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii, nigba ti iro ibọn bẹrẹ si i dun lakọlakọ nigboro Johannesburg, lorilẹede South Africa.
Ileeṣẹ ọlọpaa South Africa fidi eyi mulẹ.
Yatọ si awọn to ku, awọn eeyan mẹsan-an mi-in tun farapa lagbegbe Cleveland to ti waye,ni Johannesburg .
Ileeṣẹ ọlọpaa kede pe wọn ti n dọdẹ awọn to wa nidii iṣẹlẹ naa.
Ki lo fa ibọn yinyin nigboro?
Ninu atẹjade ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ South Africa ni wọn ti ṣalaye nipa iṣẹlẹ naa pe:
"Ṣadeede ni awọn afurasi kan yabo agbegbe naa, wọn si bẹrẹ si i lọ lati ibi kan sibi kan.
"Awọn afurasi ti iye wọn ju mẹwaa lọ ni a gbọ pe mọto Toyota funfun kan ja kalẹ nitosi ile epo kan ni Cleveland.
" Bi wọn ṣe n rin kiri adugbo ni wọn n yinbọn si awọn olugbe ibẹ ti wọn ba ti ri nibikibi ti wọn ba ti ri wọn ki wọn too sa lọ pẹlu ọkọ ti wọn gbe wa."
"Ọkunrin mẹjọ ati obinrin mẹta ni wọn ku lẹsẹkẹsẹ nibi ti wọn ti yinbọn fun wọn, nigba ti ọkunrin kan pada ku sile iwosan ti wọn gbe e lọ latari ọta ibọn to ba a."
Eyi mu onka awọn to ku naa jẹ mejila gẹgẹ bi akọsilẹ awọn agbofinro.
Bakan naa ni wọn gbe eeyan mẹsan-an mi-in lọ sile iwosan, lẹyin ti wọn fara kaasa ọta ibọn.
Lori idi ti awọn to yinbọn ọhun ṣe ya wọlu, awọn ọlọpaa sọ pe awọn ko ti i le sọ idi kan pato to mu wọn pa awọn ẹni ẹlẹni.
Wọn ni lara iwadii tawọn n ṣe naa niyẹn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
South Africa jẹ ọkan lara awọ ilu ti ipaniyan ibẹ pọ ju lagbaaye
Gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe fi han, orilẹede South Africa wa lara awọn ilu ti wọn ti n pa eeyan ju lagbaaye.
O kere tan, eeyan ọgọta (60) ni wọn ni wọn n pa nipa ifọnna-fọnṣu lojiji lojumọ.
Eyi yatọ gedegbe si pipa awọn ajeji to maa n sabaa ṣẹlẹ lorilẹede naa.
Ibọn yinyin fawọn eeyan nibi ti wọn ba ti jokoo faaji maa n saba waye lorilẹede naa.
Iwa jagidigijagan tabi ija ti ẹnikan ba ti ba ẹnikeji rẹ ja tẹlẹ ni akọsilẹ sọ pe o maa n fa a ti wọn fi saba maa n pa ara wọn ju.
Ni ti ọjọ Iṣẹgun yii, awọn ọlọpaa ibẹ sọ pe nnkan bii aago mẹwaa kọja iṣẹju mẹwaa alẹ ni awọn gbọ nipa ikọlu naa, tawọn si debẹ.
Lọdun to kọja, eeyan mẹsan-an ni wọn pa ninu ibọn yinyin to waye nile ọti kan ni Johannesburg.
O to ibọn miliọnu mẹta ti awọn to ni wọn ti gba iwe aṣẹ lati lo wọn ni South Africa, o si fẹrẹ to iye onka ija bayii naa ti ofin ko faaye gba wọn lati lo to wa lọwọ awọn kan.
Onka yii wa ninu akọsilẹ Gideon Joubert, lati ẹgbẹ awọn to ni ibọn ni South Africa (South African Gunowners' Association).
























