Àwọn afurasí jàndùkú agbébọn ṣekúpa ìyá àti ọmọ l'Ondo

Oríṣun àwòrán, Damilola Oladele
Kaka ki ewe agbọn dẹ, ṣe lo n le koko si lọrọ awọn janduku agbebọn to n ṣoṣẹ nipinlẹ Ondo, ariwo ọfọ tun sọ bi awọn afurasi agbebọn ṣe sẹkupa iya ati ọmọ l'Ondo.
Iṣẹlẹ yi waye ni Igunshin ni agbegbe Ala bi awọn agbebọn naa se se ikọlu yi si igberiko ti wọn ti n sin adiẹ.
Iṣẹlẹ yii lo tun ti fa ibẹru bojo bayii ni agbegbe naa, bi awọn eniyan se n sa asala fun ẹmi wọn, ti wọn si n kọminu lori ipo ti ọrọ eto aabo wa ni Ipinlẹ Ondo.
Ọkan lara olugbe ilu naa salaye pe awọn agbebọn marun un ni wọn yabo oriko ti wọn ti n sin adiye naa, ti wọn si fo ọgba oriko naa wọle lasiko ti awọn ti wọn sekupa naa n ṣiṣẹ lọwọ pẹlu awọn osisẹ to ku.
Wọn salaye pe eniyan mẹta ni awọn agbebọn naa jigbe lasiko ikọlu ọhun eyi to sọ ilu naa sinu ila-ilo.
Ṣugbọn ọfọ nla sẹlẹ lasiko ti wọn ri oku ẹni to ni oriko naa ati ọmọ rẹ.
Lẹyin eyi ni wọn pe ileeṣẹ Ọlọpaa, ti awọn Ọlọpaa naa si ji giri si isẹ wọn.
Kí ni ileeṣẹ Ọlọpa sọ?
Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo, Jimoh Abayomi, ẹni to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ banujẹ gidigidi lori iwa ibi ti awọn kọlọransi ẹda náà hu.
O salaye pe wọn ti doola awọn meji lara awọn ti wọn jigbe naa.
Abayomi salaye pe kete ti wọn pe awọn ikọ ileeṣẹ naa ni wọn jì gìrì ti wọn si bọ soju isẹ, ti wọn si gba awọn meji silẹ lara awọn ti wọn jigbe.
Alukoro naa sọ pe awọn ikọ ajọ naa ti wa ni gbogbo agbegbe ilu naa lati daabo bo awọn olugbe, pẹlu aridaju pe ọwọ yoo tẹ awọn to sọsẹ naa laipẹ.
Ileeṣẹ Ọlọpaa wa rọ gbogbo ara ilu lati joye oju ni alakan fi n sọri, ki wọn si maa se iranwọ fún awọn esọ alaabo nípa fi fi iroyin ohun to n sẹlẹ ni layika wọn to wọn leti ni wajowajo.


























