Kí ló kàn fún àwọn olórí ogun Mali lẹ́yìn ìkọlù àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀?

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
- Author, Makuochi Okafor
- Role, BBC Africa
- Author, Mohamed Ibrahim
- Role, BBC Arabic
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10
Bi ọja ba ti tun tan, patẹpatẹ ni yoo ṣẹku. Ibẹrẹ ogun ni a si n mọ, ẹni ogun ko ba pa ni yoo pada royin ogun.
O ṣoro lati ṣalaye bi nnkan ṣe ri lẹyin ikọlu to waye ni Mali lọjọ Abamẹta to kọja, nigba ti awọn kan kọlu Bamako ti i ṣe Olu ilu Mali, ti wọn ṣe eto naa rẹgi debii pe wọn pa minisita eto aabo ilu naa, wọn si tun gba akoso awọn agbegbe Ariwa ibẹ.
Kaakiri ẹkun Iwọ-Oorun Africa ni wọn ti gbọ pe rẹrẹ run ni Mali.
Iro ibọn ati ibugbamu ado oloro lo ji awon eeyan Mali kaakiri ilu naa lọjọ Abamẹta ọhun -Ikọ meji ti wọn n pe fun iyapa - iyẹn Azawad Liberation Front (FLA) ati al-Qaeda-to jẹ igun ẹgbẹ JNIM - si ti ni gbogbo ohun to ṣẹlẹ naa ko ṣẹyin awọn .
Bi rogbodiyan ọhun ṣe to, ati bi ikọ ogun Mali ati Russia ṣe kuro ni Kidal to ti wa labẹ akoso FLA bayii ti n jẹ kawọn eeyan maa ṣiyemeji lori agbara ologun to n dari Mali. Ọgagun Assimi Goïta, ẹni to ditẹ gbajọba loṣu Kẹjọ ọdun 2020 ni ologun to n dari orilẹede naa.
Goïta ko tete jade sọrọ nigba ti ikọlu naa waye, eyi to si n mu ọpọ araalu kọminu nipa bi ọjọ iwaju ijọba yii yoo ṣe ri gan-an.
Bakan naa ni wọn n sọ nipa ikọ ologun Russia ti wọn ran wa si Mali, ati awọn ilu alamuleti rẹ lati tan iṣoro aabo.
Ki ni yoo wa ṣẹlẹ bayii?
Nnkan akọkọ to le ṣẹlẹ: Kawọn ologun maa ba ijọba lọ ki wọn si doju ija kọ awọn ọlọtẹ pada.
Ọpọ awọn awoye ọrọ ni wọn gba pe ọna abayọ akọkọ ree fun ologun Mali, to le sare yanju iṣoro wọn fun akoko yii na.
Wọn ni nigba to jẹ pe ologun naa lo ṣi n dari ọpọ awọn ilu nla ati awọn ileeṣẹ nibẹ.
Ṣugbọn wọn ni ohun to n bọ niwaju le lagbara pẹlu bawọn ologun naa ṣe n pete ogun si awọn ọlọtẹ JNIM ati FLA.
Aṣeyọri tabi ijakulẹ ti wọn ba ni, ni yoo sọ "bi ologun yoo ṣe pẹ to lori itẹ."
Gẹgẹ bi Beverly Ochieng, awoye agba nileeṣẹ kan to n ri si ewu lagbaaye ṣe sọ.
Ọjọ kẹta lẹyin ikọlu naa, Ọgagun Goïta ba awọn araalu sọrọ lori amohumaworan.
O ni ohun gbogbo ti wa labẹ akoso bo ṣe yẹ ko ri, o si ṣeleri lati gba agbara lọwọ awon to wa nidii ikọlu naa.
Ṣaaju ni ẹka ayelujara ileeṣẹ aarẹ naa ti gbe aworan ibi ti Ọgagun Goïta ti n ṣepade pẹlu aṣoju Mali lati Russia, Igor Gromyko, jade, eyi to jẹ apẹẹrẹ pe ajọṣe .
Wọn tun lo aworan olori ogun naa lasiko to ṣabẹwo sile iwosan lati wo awọn to farapa ninu ikọlu naa ti wọn n gba itọju lọsibitu.
Amọ alaye awọn awoye lori iku minisita eto aabo; Sadio Camara, ni pe o le mu adinku ba bi awọn ologun Mali yoo ṣe dira ogun lasiko ikọlu.
Wọn fi kun un pe iku Camara tun le ṣe akoba fun ajọṣẹpọ pẹlu Russia, gẹgẹ bi Ulf Laessing, Olori eto Sahel Konrad Adenauer Foundation, ẹka centre-right German think-tank, ṣe sọ.
"Oloogbe Camara jẹ ọkan lara awon alagbara to n ṣoju Mali ni Moscow, oun si lo wa lẹyin bi wọn ṣe gbe ikọ Russia wa si Sahel."
Ulf Laessing lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, @PresidenceMali
Bi awọn ologun Mali ṣe n sọ pe awon n ja lati gba awọn apa ibi to ṣe gboogi lorilẹede naa, ipenija kan wa fun wọn.
Ipenija naa ni pe awọn ọlọtẹ FLA to ti gba Kidal tun ti n gbe igbesẹ lati wa si apa Guusu bayii.
"A fẹẹ gba ilu Gao. Gbogbo ibi to gba Gao wọle lo ti wó, amọ agọ awọn ologun ko ti i wo."
Agbẹnusọ wọn; Mohamed Elmaouloud Ramadane, lo sọ bẹẹ.
O sọ fun BBC pe ilu iṣẹmbaye to ti pẹ, iyẹn Timbuktu, naa wa lara ibi ti awọn n foju si lati gba : "O maa rọrun lati gba lọgan ti a ba ti gba ẹkunrẹrẹ akoso ni Gao ati Kidal."
Nigba ti ijọba ologun gbajọba Mali lọdun mẹfa sẹyin, ọpọ eeyan lo ṣe atilẹyin fun wọn. Wọn gba wọn tọwọtẹsẹ, ijọba naa si ṣeleri lati ṣẹgun iṣoro ai si aabo to ti n koju Mali lọdun gbọọrọ sẹyin.
Amọ ni bayii, wọn ti sun wọn kan ogiri to bẹẹ to jẹ ọna abayọ ni wọn n wa, ati bi wọn yoo ṣe bọ lọwọ awọn JNIM ti wọn ti di ọna ti epo n gba kọja ni olu ilu.
Awọn ologun naa n wa ọna bi wọn yoo ṣe tun koju iṣoro ọrọ aje to ti ba wọn bayii ni.
Bi awọn alatako yii ba rọwọ mu ṣaaju ologun, o ṣee ṣe ki rogbodiyan ọlọdun pipẹ gbilẹ ni Mali, eyi to le pa ọjọ iwaju ijọba ologun lara.
Ọna abayọ keji: Ki ologun maa ṣejọba lọ pẹlu atilẹyin Russia, ṣugbọn ki wọn wa awọn alajọṣe mi-in kunra
Ikọlu opin ọsẹ to kọja yii tun tabuku orukọ Russia gẹgẹ bii alatilẹyin aabo fun Mali. Ochieng lo sọ bẹẹ.
Lẹyin ti ologun gbajọba nibẹrẹ saa yii, wọn sọ fun awọn ikọ ilẹ Faranse to ti n ṣatilẹyin fun wọn lọdun pipẹ pe ki wọn maa lọ, awọn ajagun Russia si gba ipo wọn lati ba wọn ṣẹgun igbesunmọmi.
Amọ ni bayii, iyi Russia ti n koju "abuku" nla, lẹyin ti ikọ ologun ilẹ Africa to ti lẹyin ti lulẹ, ti wọn ko le da aabo bo awọn ilu nla wọn, ti Kidal si ti wó.
Laessing lo ṣe afikun bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Nigba ti wọn ba ṣi n duro ti atilẹyin latọdọ Russia, o le di dandan fun orileede Mali lati wa afikun si awọn ti yoo ti i lẹyin lẹka ologun.
Ohun kan to tun ṣee ṣe ko waye ni ki wọn ni ajọṣe to ju ti tẹlẹ lọ pẹlu Turkey, iyẹn Turkey to ti n wa ọna ti yoo fi fagbara rẹ han nilẹ Africa tẹlẹ.
Ochieng ṣalaye pe ọpọ iroyin lo ti jade nipa ileeṣẹ ọmọ oun Turkey kan ti wọn fẹẹ ran wa lati kọ awọn ikọ ologun to n ṣọ aarẹ Mali.
Turkey ti ni ajọsẹ aabo pẹlu Mali tẹlẹ, wọn maa n ko ẹrọ duroonu fun wọn, eyi ti a gbọ pe o ran awọn ologun lọwọ lati gba Kidal pada lọwọ awọn ọmọ ogun ọlọtẹ ni 2024.
Mali tun ti fi awọn apẹerẹ kan han, to n tọka si pe wọn ti fẹẹ maa ba ilẹ America ṣe pada, lẹyin ọdun gbọọrọ ti nnkan ti daru laaarin wọn tẹlẹ.
Nibẹrẹ ọsẹ yii, Nick Hocker, olori ẹka to n ri si ọrọ ilẹ Africa, rin irinajo lọ si Bamako lati fi bi America ṣe bọwọ fun Mali to han lori "idaduro rẹ bii orilẹede"
Ki wọn si gbe ilana tuntun kalẹ ti yoo ran wọn lọwọ bi wọn ba pinnu lori igbesẹ kan.
O fi kun un pe America ti ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn alamuleti Mali ju ti tẹlẹ lọ bayii, atawọn alajọṣe rẹ bii Burkina Faso ati Niger, ti yoo da lori aabo ati ọrọ aje.
Bakan naa ni Bamako tun le farati ajọṣe ati iranwọ lati ibi Alliance of Sahel States (AES), eyi ti yoo so Mali, Niger ati Burkina Faso pọ- nigba to jẹ ologun lo n dari ijọba ibẹ nikọọkan.
Ni Russia, koko ohun to wa nilẹ ni pe ṣe wọn ṣi le ni ọwọ agbara bi Mali ba pin agbara eto aabo rẹ sọdọ awon mi-in naa.
Rogbodiyan rẹ tun le di ohun ti wọn yoo maa gbe yẹwo l'Africa, nibi ti Moscow ti fi agbara rẹ han de nipasẹ ajọṣepọ pẹlu ologun.
Bi o ba di pe wọn n ri Russia bii ikọ ti ko le ran awọn alabaṣe rẹ lọwọ, awọn ijọba yoku ni ẹkun naa yoo bẹrẹ si i ro wo, pe boya ni awọn ko ni i din igbẹkẹle awọn ninu Moscow ku.
Àbá kẹta: Ki wọn le ologun kuro nijọba, amọ ta ni yoo maa ṣakoso lọ?
Ikọlu ọjọ Satide to kọja ti ko ipenija nla ba awọn ologun Mali, ju bi wọn ṣe n ba a bọ tẹlẹ lọ.
Bi ikọlu ba tun tẹsiwaju, o le mu idaamu ọkan ba ijọba ologun, nigba ti awọn araalu ko ba yee sọ pe awọn ko gbagbọ ninu wọn mọ.
Ohun kan to tun foju han pe o le ṣẹlẹ ni ki iditẹgbajọba mi-in tun waye, ti awon ologun mi-in yoo gbajọba yatọ sawọn to wa nibẹ lọwọ yii.
Tabi ki awọn ọmọ ogun ọlọtẹ FLA-JNIM parapọ ki wọn gba ipo ijọba to wa lori aleefa, amọ wọn yoo koju iṣoro abẹnu ni tiwọn.
Igun FLA ni tiẹ n ri ara rẹ bii ẹgbẹ oṣelu ati ti orilẹede, nigba ti JNIM jẹ ẹgbẹ adimọra ogun alakatakiti ẹsin Islam.
Ikọ meji to n daamu Mali, iyẹn awon to fẹ yapa atawọn alakakiti, ti n koju aiko ẹnu lati ọdun pipẹ sẹyin.
2012 ni awọn alakatakiti ẹsin Islam ja Tuareg to n fẹ iyapa gba .
Agbẹnusọ FLA kan nigba to n ṣapejuwe awọn onija JNIM, sọ pe : "ibatan" ni wọn.
O fi kun un pe "ọta kan naa la jọ ni , fun idi eyi, a gbọdọ jọ wa labẹ aburada kan naa ni."
Amọ olori FLA; Sayed Bin Bella, pada sọ fun BBC pe ko sohun to n jẹ ajọṣepọ ti yoo sọ awon di "ọkan ṣoṣo."
"Awa la ni gbogbo awọn asia ti a ti ta, wọn ki i ṣe tawọn al-Qaeda. To ba wu wọn lati darapọ pẹlu wa, wọn gbọdọ kuro ninu ẹgbẹ agbaye al-Qaeda ."
Bẹẹ ni Sayed Bin Bella wi.
Nigba ti awọn awoye n wo ọrọ yii, wọn ni iyapa ati aiko ẹnu to ba won yii yoo mu iṣoro wa fun wọn nipa bi wọn yoo ṣe maa lo agbara lọjọ iwaju.
Awọn odun diẹ sẹyin bayii ni JNIM ti bẹrẹ si i yago fun ẹgbẹ alakatakiti al-Qaeda atawon ẹgbẹ to ba jọ ọ.
Ochieng lo sọ eyi.
O ni ohun kan to ṣee ṣe ko waye ni pe nnkan yoo ri bo ṣe ṣẹlẹ ni Syria- nibi ti ẹgbẹ kan to ti wa pẹlu al-Qaeda ri, ti gba ipo agbara.
Awọn alakatakiti ẹsin Islam kan ti tako ilana olori ilẹ Syria naa ri, wọn lo ti fi ara jọ ti aye ju.
Wọn ti n nawọ ika aleebu iru rẹ si JNIM ni tiẹ tẹlẹ, nitori ajọṣe rẹ pẹlu FLA.
Awọn awoye to n wo ṣaakun atawon ohun ti won maa n gbe jade lori opo awon alakatakiti naa lo sọ bẹẹ.
Ṣugbọn ṣaa, iyapa ẹnu ati aiṣọkan ero laaarin JNIM ati FLA le di ohun ti yoo mu idaamu wa lọjọ iwaju, afi ti awọn to n pe fun ipinya yii ba ri akoso gbogbo Ariwa gba, ti wọn si yọ ara wọn kuro lara ohun to le ṣẹlẹ lapa ibomi-in lorilẹede naa.



























