Ìdí mẹ́rin rèé táwọn ibùdó ìfọporọ̀bì Naijiria kò fi lè ṣiṣẹ́ láéláé - Obasanjo ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oloye Olusegun Obasanjo ti ṣalaye idi ti o fi sọ pe awọn Ibudo ìfọporọbi Nàìjíríà ko le ṣiṣẹ lailai.
Aarẹ Naijiria tẹlẹ ko ye maa sọrọ yii, bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo maa n tako o nigba kugba to ba ti sọrọ naa.
Ti ẹ o ba gbagbe, lẹyìn oṣu mẹta ti Aarẹ Bola Tinubu gori aleefa ni o sọ pe Ibudo ìfọporọbi Nàìjíríà to wa niluu Port-Harcourt yoo bẹrẹ iṣẹ pada loṣu Kejila ọdún 2023
Tinubu sọrọ yii lẹyin iṣẹ atunṣe ti ajọ NNPCL to n ṣakoso epo robi ni Naijiria ati ileeṣẹ orilẹede Italy kan, Maire Tecnimont SpA ṣe níbẹ.
Amọ, nigba to n sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu Soni Irabor, Obasanjo ni awọn Ibudo ìfọporọbi Nàìjíríà ko le ṣiṣẹ lailai.
Obasanjo loun sọrọ yii latari nnkan ti ileeṣẹ epo rọbi Shell sọ foun lasiko toun jẹ Ààrẹ orilẹede Naijiria.
Obasanjo sọ lori eto Soni Irabor wí pé "lara awọn ẹkọ ti mo ti kọ ni pe ibasepọ laarin ileeṣẹ aladaani ati ìjọba maa n ṣiṣẹ daadaa.
Akanṣe iṣẹ kan ṣoṣo ti ko tii bajẹ ni Naijiria ni ileeṣẹ afẹfẹ gaasi NLNG ti aladaani n ṣakoso ida 51% ileeṣẹ naa ti ijọba si n dari ida 49%.
NNPC ní awọn Ibudo ìfọporọbi, mo si maa n sọ fawọn eeyan wí pe awọn Ibudo ìfọporọbi naa ko le ṣiṣẹ.
Amọ, ẹnikan laya lati sọ pe mi kii ṣe onimọ ẹrọ lati sọ pe awọn Ibudo ìfọporọbi NNPC ko le ṣiṣẹ lailai."
"Iwa ajẹbanu pọju lawọn Ibudo ìfọporọbi NNPC"
Oloye Ọbasanjọ ṣalaye bi o ṣe kepe ileeṣẹ epo Shell lati maa ṣakoso awọn Ibudo ìfọporọbi Nàìjíríà ṣugbọn ti wọn kọ lati ṣe bẹẹ.
Obasanjo ni "mo pe Shell nigba ti mo wa nipo aarẹ lati wa maa ṣakoso awọn Ibudo ìfọporọbi NNPC, wọn si ni rara pe awọn ko ṣe.
Lẹyin naa ni mo pe ọga agba ileeṣẹ naa pe ko sọ fun mi ìdí tí wọ́n o ṣe fẹ ṣakoso awọn Ibudo ìfọporọbi Naijiria.
Ohun ti o kọkọ sọ fun mi ni pe awọn ko le jere to pọ lori isakoso Ibudo ìfọporọbi NNPC.
Nnkan keji to sọ fun mi ni pe awọn Ibudo ìfọporọbi Nàìjíríà kere.
O ni agba epo 60,000 ni Ibudo ìfọporọbi Naijiria kan lagbara lati fọ lojumọ nigba ti omiran lagbara lati fọ agba epo 100,000 lojumọ.
Ọga Shell naa sọ fun mi pe nnkan bíi àgbá epo 250,000 sí 300,000 ni gbèdéke tawọn Ibudo ìfọporọbi n fọ lojumọ lagbaye lásìkò naa.
Nnkan kẹta to sọ fun mi ni pe Naijiria ko ṣe iṣẹ atunṣe awọn Ibudo ìfọporọbi rẹ daadaa.
O ni awọn onimọ ẹrọ ti ko mọṣẹ doju ami lo maa n ṣatunṣe awọn Ibudo ìfọporọbi Nàìjíríà.
O tun sọ fun mi pe idi niyi t'awọn Ibudo ìfọporọbi NNPC ko fi le maa ṣiṣẹ daadaa.
Ìdí kẹrin ti o sọ fun mi ni pe iwa ajebanu pọju lawọn Ibudo ìfọporọbi NNPC, awọn ko si fẹ lọwọ ninu iwa ibajẹ to n lọ nibẹ," Obasanjo lo sọ bẹẹ.


























