Àwọn agbábọ́ọ̀lù méje tí ilẹ̀ Africa ń fojú sọ́nà fún ní ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé 2026

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Rob Stevens
- Role, BBC Sport Africa
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Orilẹ ede ilẹ Africa mẹwaa ni yoo kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 2026 lẹyin ti wọn ti mu alekun ba iye orilẹ ede to le kopa nibi idije naa wọ mejidinlaadọta.
Ni ọdun 2022 ni Morocco fi itan balẹ bi orilẹ ede Africa to maa kọkọ de ipele to kangun sibi aṣekagba iyẹn semi-finals.
Igba akọkọ niyi ti Cape Verde maa kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye nigba ti DR Congo n kopa fun lẹyin ọdun 1974 ti wọn ti kopa kẹyin.
BBC Sport Africa ṣe agbeyẹwo awọn agbabọọlu meje lati foju sọna fun nibi idije ife ẹyẹ agbaye to maa waye ni awọn orilẹ ede United States, Mexico ati Canada lati ọjọ Kọkanla, oṣu Kefa, ọdun 2026.
Antoine Semenyo (Ghana)
Ẹni to n gba ọwọ iwaju fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City naa padanu lati gba ife ẹyẹ Premier League nis aa to ṣẹṣẹ pari yii amọ to da bẹbẹ ara lati mu egbẹ agbabọọlu naa gba ife ẹyẹ FA mọ Chelsea lọwọ.
Ẹni ọdun mẹrinlọgbọn naa to darapọ mọ Manchester City ni osu Kiini ọdun yii n kopa ninu idije naa lẹyin to da ninu liigi to ṣẹṣẹ pari pẹlu bo ṣe jẹ goolu meje niju mẹtadinlogun to ṣakitiyan rẹ.
A le sọ pe Semenyo ni Ghana gbọkanle bayii lati gbe orilẹ ede naa de ebute ogo nibi idije yii bo ṣe jẹ pe akẹgbẹ rẹ Mohammed Kudus, to n gba fun ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham ko ni kopa nibi idije naa nitori ifarapa to ni.
O wa lara awọn to gba fun Ghana ni ọdun 2022 ni Qatar amọ ko fi bẹẹ gba bọọlu nitori orilẹ ede naa ko ja ipele isọri ti wọn fi ja.
Ghana ko kopa nibi idije ife ẹyẹ Africa, Afcon to pari, fun idi eyi Semenyo yoo maa gbiyanju lati jẹ goolu akọkọ nibi idije to ṣe koko yii nigba ti wọn ba n koju awọn orilẹ ede bii England, Croatia ati Panama ti wọn jọ w ani isọri L.
Yan Diomande (Ivory Coast)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ agbabọọlu Ivory Coast ti inagijẹ wọn n jẹ Erin n kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye lẹyin ọdun 2014 ti wọn ti kopa kẹyin, ti agbabọọlu to kere, to si dara nibi idije German Bundesliga jẹ ọmọ orilẹ ede wọn.
Ẹni ọdun mọkandinlogun naa, to jẹ goolu meji, to si ṣeranwọ fun goolu mẹjọ mu ki ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, RB Leipzig gbe ipo kẹta, ki wọn si le kop ani idije Champions League.
Fun idi eyi, wọn ti n gbiyanju lati fi owo nla gbe e lọsawọn ẹgbẹ agbabọọlu bii Liverpool ati Chelsea.
Diomande to wa lara awọn agbabọọlu akọkọ to bẹrẹ bọọlu fun orilẹ ede rẹ ni Afcon 2025 lo ni akọọlẹ gige awọn akẹgbẹ rẹ julọ nibi idije Bundesliga saa 2025/26.
Diomande yoo maa fi oun to wọn han Germany, Ecuador ati Curacao ti wọn jọ wa ni isọri kan naa ti wọn ba pade.
Ronwen Williams (South Africa)
Igba akọkọ ti South Africa yoo maa kopa nibi idije ife ẹyẹ agbaye niyi lẹyin ti wọn gba bọọlu naa ni orilẹ ede wọn lọdun 2010.
Ohunk an ti South Africa ko i tii ri ṣe pẹlu bi wọn ṣe ti kopa ninu idije fun bii ẹẹmẹta sẹyin iyẹn lọdun 1998, 2002 ati 2010 ni pe wọn kii kọja ipele isọri lati igba ti wọn ti n kopa.
Aṣọle ẹgbẹ agbabọọlu naa, Williams, to di gbajumọ lẹyin to mu pẹnariti mẹrin nibi ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Cape Verde nibi idije Afcon 2023, lo n ko ẹgbẹ naa sodi.
Ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn naa ni oun fẹran lati maa sọle, to si tun ti ni iriri awọn idije nla bayii pẹlu bi ẹgbe agbabọọlu rẹ Sundowns ṣe ṣẹṣẹ gba ife ẹyẹ awọn ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Africa.
South Africa yoo maa wako pẹlu Mexico nibi iṣide idije naa lọjọbọ, ki wọn to maa koju Czech Republic ati South Korea.
Roberto 'Pico' Lopes

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Cape Verde kii saba si ni iwaju nigba ti a ba n sọrọ ere idaraya amọ ti wọn de ipele orilẹ mẹjọ nibi idije Afcon 23, ti wọn si tun ṣaaju awọn orilẹ ede bii Cameroon lati kopa nibi idije ife ẹyẹ agbaye ọdun yii.
Lopes to n gba ọwọ ẹyin fun Shamrock Rovers ni wọn kọkọ pe lati maa gba fun Blues Sharks amọ to kọ nitori pe Portugal lo wa.
Ni ọdun 2019 ni ẹni ọdun mẹtalelọgbọn naa kọkọ bẹrẹ, ko kopa nibi ifẹsẹwọnsẹ kan pere lati mu ki Cape Verde ribi de idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 2026 fun igba akọkọ yii.
Cape Verde to wa ni isọri H pẹlu awọn orilẹ ede bii Spain Uruguay ati Saudi Arabia ni iṣẹ lati ṣe.
Brahim Diaz (Morocco)
Agbabọọlu fun Real Madrid yii wa lara awọn eekan ti irawọ tan nibi idije Afcon 2025. O jẹ goolu marun-un lati mu ki orilẹ ede rẹ wọ ipele aṣekagba amọ to ni iṣẹ lati ṣe bayii.
Ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn naa ko ribi jẹ pẹnariti ti orilẹ ede rẹ ri tako Senegal lasiko ti ifẹsẹwọnsẹ naa ti n pari lọ nibi aṣọle Senegal, Edouard Mendy mu bọọlu naa mọ lọwọ.
Bi Senegal ṣe fẹhonuhan lati kuro lori papa lẹyin ti wọn fọn pẹnariti fun Morocco mu ko to ri bọọlu naa gba pẹ fun igba diẹ, to si n sunkun lẹyin ti Senegal pada gbe ife ẹyẹ naa.
Ajọ to n ri si bọọlu ilẹ Africa pe ẹjọ kotẹmilọrun lori eyi ti wọn si dajọ pe ki Senegal da ife ẹyẹ naa pada fun Morocco amọ Senegal naa tig be ejọ naa lọ siwaju ile ẹjọ to n ri ọrọ bọọlu.
Atlas Lion Morocco yoo maa koju Brazil, Scotland ati Haiti ni isọri C ti wọn jọ wa.
Ismaila Sarr (Senegal)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹni ọdun mejidinlọgbọn yii jẹ ogbontarigi nidii bọọlu ti ogo rẹ si ham gidi fun Crystal Palace ni saa yii.
O ṣe iranwọ fun Eagles lati gba ife ẹyẹ akọkọ ni Yuroopu pẹlu Uefa Conference League.
Sarr n gbaradi fun igba kẹta ti yoo kopa nibi idije ife ẹyẹ agbaye.
Awọn Teranga Lions, ti a le pe ni eekan Africa lọwọ bayii yoo koju France, Norway ati Iraq ni isọri I.
Senegal to na France pẹlu ami ayo kan sodo ni 2002 ni ifẹsẹwọnsẹ akọkọ, ti ireti si wa pe Sarr maa ṣeranwọ lati tun gbe ogo orilẹ ede soke bayii.
Omar Marmoush (Egypt)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn yii le maa ti ṣiṣẹ $79.5m (£59m) ti wọn ra a lati darapọ mọ Man city lati Eintracht Frankfurt ni oṣu Kiini ọdun to kọja, amọ Marmoush ṣeranwọ fun Pep Guardiola lati gba ife ẹye FA nis aa yii.
O wa lara awọn agbabọọlu to n lewaju fun orilẹ ede Egypt, to si jẹ goolu meji nibi idiji Afcon 2025.
Bo ṣe n kopa ninu idije ife ẹye agbaye fun igba akọkọ, ireti wa pe o maa pọnkun akitiyan nibi idije yii.
Bi o tilẹ jẹ pe Egypt ni orilẹ ede akọkọ ti wọn maa kọkọ kopa nibi idije ife ẹyẹ agbaye, wọn ko i tii kọja ipele round of 16 ri.
Pẹlu bi ara Mohamed Salah ṣe ṣẹṣẹ n balẹ pelu ifarapa to ni, akọnimọọgba Hossam Hassam yoo maa reti ki Marmoush ṣe gudugudu meje yaya mẹfa nibi idije yii.























