Ìdí tí mo fi pinnu láti má báwọn jàndùkú tó jí ìyàwó mi gbé nílé ẹ̀kọ́ Esinele sọ̀rọ̀ mọ́ - Ọ̀jọ̀gbọ́n Alamu

Arabinrin Rachael Alamu wọ aṣọ olomi buluu, Ọjọgbọn Wole Alamu wọ aṣọ dudu, o si mu ẹrọ gbohungbohun lọwọ

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọjọgbọn Wole Alamu to jẹ ọkọ ọga ile ẹkọ girama Esinele to wa lara awọn olukọ ati akẹkọọ ti wọn ji gbe nijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso nipinlẹ Oyo ti sọ pe oun pinnu lati ma bawọn ajinigbe naa sọrọ mọ nitori idunkoko wọn n ṣakoba fun ilera oun.

Ọjọgbọn Alamu sọrọ yii lasiko eto idupẹ ni ṣọọṣi ti ẹbi rẹ ṣe lori bi Ọlọrun ṣe gba iyawo rẹ atawọn mii lọwọ awọn janduku ajinigbe.

Ọkọ ọga agba ile ẹkọ girama Esinele sọ pe ni gbogbo igba tawọn ajinigbe naa ba ti ba oun sọrọ lori foonu ni ẹjẹ oun maa n ru soke.

Ọjọgbọn Alamu ṣapejuwe ijinigbe iyawo rẹ gẹgẹ bii iṣoro to ga julọ ti ẹbi oun ti koju laye.

O ni iṣẹlẹ naa da igbe aye alaafia ti ẹbi oun n gbe ru.

Ọgbẹni Alamu ko ṣai gboṣuba rabandẹ fawọn ẹṣọ eleto aabo fun iṣẹ ribi ribi ti wọn ṣe lati ri pe iyawo oun atawọn akẹkọọ ti wọn ji gbe gbominira.

Ọgbẹni Alamu to jẹ olukọ fasiti fikun ọrọ rẹ wi pe ọsẹ mẹta loun fi ba awọn ajinigbe naa sọrọ.

Amọ, o ni bawọn ajinigbe naa ṣe n dunkoko ṣakoba nla fun agọ ara oun.

Ọjọgbọn Alamu ni oun pinnu lati maa bawọn ajnigbe naa sọrọ mọ tori ilera oun, oun si fi igbagbọ oun sinu Ọlọrun wi pe iyawo oun yoo bọ lọwọ awọn ajinigbe.

Olukọ fasiti naa ṣalaye wi pe lẹyin toun o bawọn ajinigbe naa sọrọ mọ ni wọn dunkoko lati pa iyawo oun amọ iyawo oun fi igbagbọ sọ fun wọn pe wọn ko ni pa oun, Ọlọrun ko si jẹ ki wọn pa a.

O ni ọpọ eeyan ni Naijiria ati loke okun ni wọn ṣatilẹyin fawọn lasiko ti iyawo oun wa lakata awọn ajinigbe.

Ọjọgbọn Alamu wa rọ awọn kristẹni wi pe ki wọn duro sinsin ninu igbagbọ wọn si Ọlọrun, o ni idanwo igbagbọ ni ipenija tabi iṣoro to ba n koju kristẹni jẹ.