Ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni tako òfin tó sọ ọ́ di èèwọ̀ láti máa wàásù nínú ọkọ̀ akérò

Ọkunrin to n ba awon eeyan sọrọ ninu ọkọ akero nla

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi kan ti tako aba si atunṣe ofin irinna oju popo to sọ ọ di eewọ lati maa waasu ninu ọkọ ero.

Awọn ẹgbẹ naa ni ẹgbẹ Christian Council of Nigeria, (CCN) ati ẹgbẹ Organisation of African Instituted Churches (OAIC).

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, wọn ni ofin ọhun yoo tẹ ẹtọ araalu loju mọlẹ lati ṣe ohun to wu wọn ni igboro.

Ọjọbọ ọsẹ to kọja ni ile igbimọ aṣofin Naijiria buwọlu atunṣe ofin irina oju popo, iyẹn Federal Road Safety Corps (Amendment) Bill, 2026 to sọ sọ ọ di eewọ lati maa waasu tabi kiri ọja ninu ọkọ akero igboro.

Ofin naa ni ẹnikẹni to ba jẹbi ṣiṣẹ bẹẹ yoo san ẹgbẹrun lọna aadọta naira gẹgẹ bii owo itanran tabi ko fi ẹwọn jura.

Awọn aṣofin ni ofin naa ni wọn gbe kalẹ ki awọn to n ta ọjọ tabi waasu ma baa maa di awọn awakọ lọwọ, ki irufẹ awakọ bẹẹ le foju si ọkọ to n wa.

Ti Aarẹ ba le tọwọ bọ abadofin ọhun, ẹni to ba jẹbi ẹsun naa le fi ẹwọn oṣu mẹfa jura tabi ki wọn san N50,000 naira owo itanran tabi mejeji.

Wọn ni ọrọ naa tun kan awakọ to ba kọ lati fọwọsowọpọ pẹlu oṣiṣẹ FRSC loju popo lasiko ti wọn ba n ṣayẹwo fun irufẹ awakọ bẹẹ boya o mu ọti tabi bẹẹ kọ.

Nigba to n sọrọ tako abadofin ọhun, akọwe ajọ CCN, alufaa Evans Onyemara ni o jẹ ohun to gbọgbẹ lọkan ajọ naa pe wọn fi awọn oniwaasu sinu awọn ti wọn fofin ọhun de.

O ni bo tilẹ jẹ pe awọn faramọ ofin ti yoo mu ki aabo oju popo nipọn si, awọn ko faramọ ohun ti yoo tẹ ẹtọ araalu loju mọlẹ.

Onyemara sọ pe ko tọ ki ijọba ko awọn to n ṣiṣẹ igbala ọkan papọ mọ awọn ti n ru ofin.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, fun ọpọ ọdun lawọn ọmọleyin Kristi ti maa n pin iwe iwaasu ninu ọkọ ero lai si wahala kankan ti wọn a si maa gbadura fun awọn ti wọn n rinrinajo.

O tun bu ẹnu atẹ lu owo itanran ti iye rẹ jẹ N50,000 fun awọn ti wọn n kiri ọja.

Alufaa naa ni ko si ẹni to wu lati maa kiri ọja amọ iṣẹ ati iya to n ba awọn ọmọ Naijiria finra lo n mu ki wọn kiri ọja.

Lẹyin naa lo rọ Aarẹ Bola Tinubu, ile igbimọ aṣofin ati gbogbo awọn ti ọrọ naa kan ki wọn ṣe ayẹwo abadofin ọhun finifni ki wọn to buwọlu u.