Ọkùnrin tí ọlọ́pàá ká ẹ̀yà ara èèyàn mọ́ lọ́wọ́ l'Ondo dèrò àtìmọ́lé

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo atawọn nnkan ti wọn ri nile ọkunrin naa

Oríṣun àwòrán, NPF Ondo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ ọkunrin kan ti wọn ba ohun to farajọ ẹya ara eeyan ninu ile rẹ nipinlẹ Ondo.

Ileeṣẹ ọlọpaa lo fidi iroyin naa mulẹ ninu atgẹjade kan loju opo Facebook rẹ, eyi ti agbẹnusọ rẹ, DSP Abayomi Jimoh, buwọlu.

Jimọ sọ pe baba afurasi naa lo fi ẹsun ole jija kan an ki awọn to lọ yẹ ile rẹ wo nibi ti wọn ti ṣawari awọn oogun kan nibẹ ninu eyii ti wọn ni o ṣeeṣe ki ẹya ara eeyan wa.

Gẹgẹ bii ọlọpaa ṣe sọ, ọkunrin kan, Awomehinde Kehinde, lo fi ẹjọ ọmọ rẹ, Awomehinde Tope, to jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn sun ni agọ awọn to wa niluu Ile Oluji.

Baba ọkunrin ọhun sọ pe ọmọ oun ji awọn dukia oun ko.

Lara awọn dukia to ni ọmọ rẹ ọhun ji ni alupupu Boxer Bajaj mẹta, ewurẹ mẹsan an, ẹrọ ilewọ Android mẹrin, epo pupa, silinda gaasi meji, atawọn nnkan mii.

Atẹjade naa tẹsiwaju pe "Ọlọpaa yẹ inu ile rẹ wo nibi ti wọn ti ri awọn nnkan to jọ ohun ti wọn fi n joogun ati eyii ti wọn fi n wu iwa ọdaran.

"Lara awọn nnkan ti a ri ni egungun kan ti a gbagbọ pe o jẹ egungun eeyan ti a maa ṣe iwadii rẹ daadaa, to fi mọ korofo ọta ibọn ibọn Ak-47 kan.

Atẹjade ọlọpaa sọ pe ni itẹsiwaju iwadii awọn, ọwọ awọn tun tẹ afurasi meji mii ti wọn ni ibaṣepọ pẹlu afurasin akọkọ ti wọn ko si le ṣalaye awọn nnkan ti ọlọpaa ba lakata wọn.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ iwadii to peye lori awọn nnkan ti wọn ka mọ awọn afurasi naa lọwọ.

Lẹyin naa lo rọ awọn araalu ki wọn maa ṣọra, ki wọn ma si dẹkun ati maa ke si ọlọpaa ni gbogbo igba ti wọn ba kofori iwa ọdaran kankan layika wọn.