Wo ohun márùn-ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa ofin tuntun tó rọ̀ mọ́ nọ́ńbà BVN tí Banki àpapọ̀ gbé jáde

Ọwọ kan n gba owo lati ẹnu ẹrọ to n pọ owo (ATM)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Banki apapọ ilẹ Naijiria, iyẹn Central Bank of Nigeria (CBN), ti gbe awon ofin tuntun kan to le ju ti tẹlẹ lọ jade lori Bank Verification Number ti a mọ si BVN, to wa fun kaluku ni banki rẹ.

Awọn ofin naa ti wọn ni yoo gbera sọ lọjọ akọkọ ninu oṣu Karun-un ọdun 2026, wa fun iforukọsilẹ BVN ati ki ohun gbogbo le ri bo ṣe yẹ ninu akanti rẹ.

Gẹgẹ bi CBN ṣe kede awọn ofin naa ṣaaju loṣu Kẹta ọdun yii, wọn ni gbogbo banki ni yoo kan, pẹlu awọn ileeṣẹ ifowopamọ mi-in.

Wọn fi kun un pe yoo ran akọsilẹ nipa BVN lọwọ, dena jibiti, yoo si tun jẹ ki akọsilẹ awọn onibaara ni banki ṣe rẹgi lai ni abawọn.

Wọnyi lawọn nnkan tuntun ti CBN ni yoo maa ṣẹlẹ pẹlu BVN bayii.

Ẹni ti ko ba ti i pe ọdun mejindinlogun (18) ko le forukọ silẹ fun BVN

Lara ofin tuntun ti Banki agba ilẹ wa gbe kalẹ bayii fun BVN nini ni pe ẹni ti ọjọ ori rẹ ko ba ti i pe mejidinlogun ko le forukọ silẹ fun nọmba yii.

CBN ṣalaye pe ọdun mejidinlogun soke ni ọjọ ori ti ofin fi aaye gba lati le forukọ silẹ fun nọmba yii.

Tẹlẹ, awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko to 18 le fi orukọ silẹ fun BVN labẹ awọn alakalẹ kan. Ṣugbọn ofin to de bayii sọ pe ko siyẹn mọ.

"Ofin yii yoo mu ki nini BVN wa ni ibamu pẹlu ọjọ ori ti ofin gba pe eeyan ti di agbalagba to le da ipinnu ṣe. Yoo si mu akọsilẹ nipa kalulu rọrun lorilẹede yii kaakiri ẹka ifowopamọ."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa wi.

Fun awọn ọmọde atawọn ọdọ langba, wọn yoo ni lati rọgbọku le akanti awọn obi tabi alagbatọ wọn lati lo apo ikowosi funra wọn.

Ẹẹkan ṣoṣo ni o le paarọ nọmba foonu ti o n lo fun BVN

Ofin tuntun keji ni pe CBN ti ni ko si anfaani lati maa paarọ nọmba foonu ti eeyan ba so BVN rẹ mọ ju ẹẹkan ṣoṣo lọ.

Bi Banki agba ilẹ Naijiria naa ṣe ṣalaye, tẹlẹ lo jẹ pe eeyan le maa paarọ nọmba ibanisọrọ to so mọ BVN bo ba ṣe fẹ, ni bayii, ko si ohun to jọ iru rẹ mọ.

Idi eyi bi wọn ṣe wi ni lati le fidi ododo mulẹ bi idunaa-dura ba n waye lori ayelujara.

Awọn bii fifi nọmba ẹẹkan ṣoṣo ranṣẹ (OTP),gbigba iro pe owo ti wọle tabi jade (alaati) ati gbigba akanti to ba ni aroye lori pada.

Wọn gbe atẹ awọn iduna-dura to mu afurasi jibiti lilu dani jade (BVN fraud watchlist)

CBN tun gbe atẹ kan to ni gbedeke kalẹ, to wa fun kikọ awon iduna-dura to mu ifura dani silẹ.

Awọn to jọ pe jibiti lilu wa lọrọ wọn ni eyi wa fun.

Wọn ni ileefowopamọ le fi nọmba BVN eeyan sinu akọsilẹ to mu ifuradani, o si le wa bẹẹ fun wakati mẹrinlelogun ti I ṣe ọjọ kan, lati wadii ohunkohun to ba ruju.

"Nọmba BVN ti a furasi naa le wa nibẹ fun ọjọ kan, laaarin asiko naa, banki gbọdọ kan si ẹni to ni akanti naa lati sọ ohun ifura ti wọn ri ni akanti rẹ fun un.

" Eyi yoo jẹ ki esi tete jade, wọn yoo si le da aabo bo onibaara naa ko ma di pe yoo maa wa bẹẹ lọ."

Bẹẹ ni atẹjade CNB naa ṣalaye.

Ko si aaye lati wọnu akọsilẹ aṣiri ẹlomi-in

Bakan naa ni CBN ti gbegidina awọn ẹka iṣowo tabi ifowopamọ ti ko lẹtọ lati wọnu akọsilẹ onibaara nipa lio BVN rẹ.

Eyi yoo dena ewu titu aṣiri nọmba ikọkọ to le gbe owo jade, awọn ti ko yẹ ko si ni I le wọnu akanti eeyan.

Yoo ṣẹgun lilo awọn nnkan bii orukọ tabi nọmba eeyan lọna to wu awọn ti ko lẹtọ si i naa pẹlu bi Banki agba ilẹ wa ṣe sọ.

Wọn ni awon ẹka ti CBN ba fọwọ si nikan ni yoo ni anfaani lati le wọnu BVN eeyan.

Ṣaa, wọn ṣalaye pe lawọn asiko to ba gba bẹẹ labẹ ofin, banki le fi aaye silẹ fun wọn.

Iforukọsilẹ fun BVN le si i

CBN tun gbe eto kalẹ ti yoo mu ki iforukọsilẹ fun BVN le si i.

Wọn ni eyi yoo kan orukọ atawọn idanimọ ti eeyan fẹ fi silẹ. Bawo lo ṣe jẹ otitọ si, se ohun ti ẹni naa maa n lo niyẹn, yoo si tun dena jibiti pẹlu.

Banki agba ilẹ wa ṣalaye, pe eyi yoo ran mimọ onibaara banki lọwọ, yoo si jẹ kawọn le ṣe ayẹwo ati akọsilẹ daadaa nipa wọn.

"Eyi naa yoo dena jibiti, yoo fi otitọ han nipa ẹni to ni aknati, yoo fi ọkan onibaara balẹ lẹka ifowopamọ Naijria."

Bẹẹ ni atẹjade CBN ṣalaye.