Àlàyé rèé lórí bí afurasí tọkọtaya ṣe lu ọmọ tí wọ́n gbà tọ́ pa l'Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọrọ bẹyin yọ fun ọkunrin kan; Paul Onyeama ati iyawo rẹ, Adline Ogbonna, nigba ti ọmọ ọlọmọ ti wọn gbatọ ku mọ wọn lọwọ latari ifiyajẹni gbogbo igba, lagbegbe Igando, ipinlẹ Eko.
Gẹgẹ bi awọn eeyan to sunmọ tọkọtaya yii ṣe wi, ọmọbinrin ni ọmọ ti wọn gba tọ yii, Faith ni wọn pe orukọ rẹ, ọmọ ọdun mẹwaa si ni.
O pẹ ti tọkọtaya yii ti maa n ṣe ọmọdebinrin naa baṣubaṣu bi a ṣe gbọ, ọpọ awọn to mọ wọn ni wọn sọ pe lilu lalubami ni wọn maa n lu Faith.
Yatọ si lilu, ọlọkan-o-jọkan iya ni wọn ni Faith koju lọdọ awọn to gba a tọ, bẹẹ ni wọn maa n ran an niṣẹ buruku ti wọn ko le ran ọmọ tiwọn.
Bawo lọrọ ọmọ naa ṣe ja siku?

Oríṣun àwòrán, Adekunle Taofeek
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, o ti to nnkan bii ọsẹ meji ti ara Faith ko ti ya, ṣugbọn awọn alagbatọ rẹ ko tori eyi ṣaanu fun un.
Ifiyajẹni to lagbara lai ṣe itọju rẹ, tabi ra oogun fun ọmọ naa ni a gbọ pe wọn tẹsiwaju ninu rẹ, ti awọn alajọgbele wọn si n ri gbogbo ohun ti wọn n ṣe.
Bi ara Oloogbe Faith ko ṣe ya naa ni wọn tun maa n ran an ni awọn iṣẹ de torutoru, gẹgẹ bawon eeyan to mọ wọn ṣe wi.
Olugbe agbegbe naa kan, Adekunle Taofeek, sọ fun ẹka iroyin Punch, pe tọkọtaya to n gbe lopopona Jemesi Papa, n'Igando naa ba a de oju ẹ lọjọ Aiku ọsẹ yii.
"Mo gbọ pe o ti rẹ ọmọbinrin naa fun ọsẹ meji, sibẹ, wọn ko yee fiya jẹ ẹ.
" Lanaa (ọjọ Aiku) wọn ni tọkọtaya tun lu ọmọ naa lalubami pẹlu bi ara rẹ ko ṣe ya to, o si ṣe bẹẹ dagbere faye."
Bẹẹ ni ọkunrin naa wi.
A gbọ pe wọn pada gbe e lọ sile iwosan, ṣugbọn awọn dokita sọ pe o ti ku bi wọn ṣe gbe e de.
Awọn ọdọ adugbo binu, wọn mu tọkọtaya
Lẹyin to ti han pe Faith ti ku, awọn ọdọ adugbo fi ẹhonu wọn han lori iṣẹlẹ naa, wọn si kọkọ mu Adline, iyawo to wa nitosi.
Paul to jẹ ọkọ ni a gbọ pe o lọ pe kẹkẹ Marwa ti yoo fi gbe oku Faith, bo si ṣe de ni wọn nawọ gan oun naa.
"Ẹsẹkẹsẹ ti ọmọ yẹn ku, wọn tọju oku rẹ sinu yara, wọn si ṣe bii pe ko si nnkan kan to ṣẹlẹ. Iyawo tiẹ tun dana nile idana bii pe ko si nnkan kan.
"Awọn alajọgbe to ti n woye ohun to n ṣẹlẹ lo beere ibi ti Faith wa, ki wọn too mọ pe o ti ku.
"To ba jẹ pe wọn ri aaye ju oku rẹ nu ni, ko sẹni ti yoo mọ ohun to ṣẹlẹ si i."
Bayii ni aladugbo wọn kan ti ko darukọ ara rẹ wi.
O tẹsiwaju pe awọn fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa Igando leti lẹsẹkẹsẹ, wọn si waa mu tọkọtaya yii, wọn gbe oku Faith lọ.
Iwadii si n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii, pẹlu igbagbọ pe tọkọtaya naa yoo foju bale ẹjọ.



























