'Ẹ̀sìn àbáláyé ló le yọ Nàìjíríà kúrò nínú ìpèníjà ààbò'

Ogiyan ti ilu Ejigbo, Ọba Omowonuola Oyeyode fi ọwọ si ẹgbẹ ori, o n wo ọọkan
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bi ipenija aabo to n ba Naijiria finra lasiko yii ṣe n peleke si, ni awọn eeyan n pe fun oniruuru ọna lati wa ojutuu si iṣoro naa.

Bi awọn araalu ṣe n wa ojutuu si naa ni awọn ori ade ọrun ilẹkẹ ko dakẹ, ti wọn n fi imọran lede lori ọna ti wọn ro pe o le mu aabo pada silu.

Eyi naa lo mu Ọba Omowonuola Oyeyode, Ogiyan ti ilu Ejigbo ni ipinlẹ Osun gba gbogbo ọmọ bibi ilẹ yoruba nimọran pe ki wọn pada sibi ẹṣin abalaye awọn baba-nla wọn lojuna ati gbogunti eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria bayii.

‎Ọba alaye naa gba awọn eeyan nimọran yii nibi ayẹyẹ Gbagede Ọba ilu Ejigbo lọjọ Abamẹta, ọjọ Kẹfa, osu Kẹfa ọdun 2026.

‎Kabiyesi Oyeyode rọ awọn eeyan lati maa wa ni oju ni alakan fi n ṣọri lasiko yii, ki wọn si ri pe wọn ko rin lọna aitọ lasiko yii.

‎Ninu ọrọ rẹ, Peter Oyedele, ẹni to wa lati idile Ọba niluu Ejigbo ṣalaye pe Gbagede Ọba jẹ ọdun aṣa ti awọn ba laye lati ọdọ awọn baba-nla wọn ni ilu naa.

O ni o jẹ ọjọ ti Ogiyan ti ilu Ejigbo yoo bọ si gbangba lati ba awọn ọmọ iluu Ejigbo sọrọ ti ara ilunnaa yoo si ni anfaani lati ba Ogiyan sọrọ ohun ti wọn fẹ lati ọdọ ọba.

O sọ pe yatọ eyi, o jẹ Ogiyan ti iluu Ejigbo yoo wure fun gbogbo ọmọ bibi ilu Ejigbo nile loko, eyi si jẹ ohun to maa n waye ni ẹẹkan lọdun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O fi kun pe ayẹyẹ naa maa n jẹ okunfa isopọ fun gbogbo awọn ọmọ ilu Ejigbo nitori gbogbo awọn to wa lajo lo maa n wale ti kii si jẹ ki wọn gbagbe aṣa ati ise ilẹ Yoruba ni gbogbo ibi ti wọn ba tẹdo si.

Peter tẹsiwaju pe Gbagede Ọba ilu Ejigbo yatọ si ayẹyẹ Ojude Ọba ti awọn ilẹ Ìjẹ̀bú bi o tilẹ jẹ pe awọn eto ibẹ fẹ fara jọ mọ ti ilẹ Ìjẹ̀bú.

‎Bakan naa ni Olaide Raji, ẹni to jẹ alaga fun eto ayẹyẹ Gbagede Ọba, ṣalaye pataki to wa ninu Gbagede Ọba ati ipa to n ko ninu asa ilẹ Yoruba.

‎Olaide ni Gbagede Ọba maa n ṣokunfa gbigbe aṣa Yoruba laruge lọpọlọpọ nipasẹ imura ati iwọsọ ni akoko ọdun naa.

O wa rọ gbogbo ọmọ bibi Yoruba lati maa gbe aṣa Yoruba laruge ni gbogbo ibi ti wọn ba tib a ara wọn, to si ni ṣiṣe bẹẹ yoo jẹ ki iṣọkan pada si aarin iran ọmọ Yoruba.

Bi o ti lẹ jẹ wi pe, ibẹru ati ifoya pọ lọkan awọn eeyan lasiko ti a wa yii, sibẹ awọn eeyan ilu Ejigbo ko kaarẹ ọkan lati ṣe ayẹyẹ Gbagede Ọba ti ọdun yii.

Niṣe ni oniruuru aṣọ ofi ti wọn fi ran aṣọ alamrabara n pe ara wọn ranṣẹ nibi ayẹyẹ naa.‎

Ọkunrin ati obintin ti wọn jọ wọ aṣọ alawọ ewe, wọn n rẹtin-in.
Awọn ọkunrin to wọ aṣọ ofi
Awọn obinrin ti wọn wọ aṣọ olomi aro
Awọn ero to pọ to wọ aṣọ iru kan naa
Obinrin to wọ aṣọ ofi, o fa ẹṣin lọwọ