Makinde kéde ìgbà tó ṣeéṣe kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ Oriire darapọ̀ mọ́ mọ̀lẹ́bí wọn

Makinde nile iwosan pẹlu awọn ti wọn ji gbe

Oríṣun àwòrán, Oyo State Government

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọ pe awọn kan lara awọn akẹkọọ Oriire to ṣẹṣẹ gba itusilẹ n ṣaarẹ amọ wọn ti n gba itọju lọwọ.

Makinde lo sọrọ naa lọjọ Abamẹta lẹyin to lọ ṣabẹwo si awọn ọmọ atawọn olukọ ọhun ti wọn ṣẹṣẹ gba itusilẹ lakata ajinigbe.

Ile iwosan awọn ọmọ ogun, 2 Division Nigerian Army Medical Services, Odogbo, to wa ninu ọgba awọn ologun niluu Ibadan ni wọn ti n gba itọju.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, akẹkọọ mọkandinlogoji ni awọn agbebọn naa ji gbe pẹlu olukọ meje, amọ gbogbo wọn ni wọn ti pada wale bayii.

O fi ẹmi imoore han si Eledua, ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria atawọn oṣiṣẹ agbofinro mii fun akitiyan wọn lati dola awọn ọmọ naa.

"Ọmọ ogun ku lasiko ti wọn n doola awọn eeyan naa"

Makinde ninu ọrọ rẹ sọ siwaju si pe bo tilẹ jẹ pe lootọ ni ijọba doola gbogbo awọn eeyan to wa lahamọ ajinigbe, ijọba padanu awọn ọmọ ogun kan to kopa ninu idoola ẹmi naa.

Gomina ọhun ṣalaye pe ifaraẹnijin awọn to padanu ẹmi wọn ki awọn akẹkọọ ati olukọ naa le pada wale ni ijọba ipinlẹ Oyo ko ni gbagbe lailai.

Lẹyin naa lo ba gbogbo mọlẹbi awọn to padanu ẹmi ki awọn akẹkọọ ọhun le pada wale kẹdun.

Igba wo lawọn akẹkọọ ati olukọ naa yoo lọ darapọ mọ mọlẹbi wọn?

O ni awọn ọmọ naa ti wọn ṣẹṣẹ de lati ahamọ agbesunmọmi yoo wa lakata awọn eleto ilera fun ọjọ meji gbako fun itọju ati ayẹwo.

Makinde sọ pe lẹyin ayẹwo ati itọju wọn ni ijọba yoo to jọwọ wọn fun awọn mọlẹbi wọn.

Gomina naa mẹnuba ọkan lara awọn ọmọ naa to n fi gbogbo igba bere iya rẹ ki wọn to pe iya rẹ ko wa ri.

O ni gbogbo atilẹyin to yẹ ni ijọba oun yoo ṣe fun awọn eeyan naa latari iriri aburu ti wọn ti la kọja lakata agbesunmọmi.

Lẹyin naa lo ṣeleri pe oun yoo bun gbogbo eeyan ipinlẹ Oyo gbọ nipa bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ati bi ijọba ṣe doola wọn.