Bí mo ṣe kọ́kọ́ rí àwòrán ọkọ mi lára àwọn tí wọ́n tú sílẹ̀ ní Ogbomoso mo ṣubú mo ń sun ẹkún ni - Ìyàwó ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ tí wọ́n jí gbé
Bí mo ṣe kọ́kọ́ rí àwòrán ọkọ mi lára àwọn tí wọ́n tú sílẹ̀ ní Ogbomoso mo ṣubú mo ń sun ẹkún ni - Ìyàwó ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ tí wọ́n jí gbé
Published
Idunnu ṣubu layọ fun idile Ọlatunde nigba ti iroyin kan wọn lara pe wọn ti tu awọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn ji gbe ni Ogbomọṣọ ni ipinlẹ Ọyọ silẹ.
Arakunrin Ọlatunde to jẹ olori idile naa wa lara awọn ti awọn ajinigbe ji gbe ni ọjọ karundinlogun oṣu karun un eleyi ti o ti sọ idile naa ati gbogbo awọn ọmọ orilẹede Naijiria si iporuru ọkan lati igba naa.
Arabinrin Ọlatunde Taiwo ba BBC News Yoruba sọrọ lori bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, ipo ti idile naa wa lati igba to ti ṣẹlẹ ati bi nnkan ṣe ri nigba ti wọn gbọ iroyin ọhun.