Ohun tí a mọ̀ nípa rògbòdìyàn tó wáyé l'Osogbo níbi tí èèyàn méjì ti kú, tí ọ̀pọ̀ tún farapa

Awọn ọkọ to bajẹ lasiko ikọlu naa ati eeyan kan to fara gbọgbẹ lẹyin.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Eeyan meji ti jade laye lẹyin rogbodiyan to waye niluu Osogbo, nipinlẹ Osun, lẹyin ti awọn janduku oloṣelu kan kọlu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.

A gbọ pe agbegbe Owode-Igbonna ni rogbofiyan naa ti bẹ silẹ lọjọru ti awọn janduku naa si wọ iboju lati fi oju wọn pamọ.

Iroyin ni asiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ọhun n ṣe ipade lọwọ ni awọn afurasi naa ya bo agbegbe naa ninu bọọsi Toyota Hiace kan ti gbogbo wọn si wọ aṣọ dudu.

Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa ti ikọlu naa ṣoju rẹ, Rasheed Abiola sọ fun ileeṣẹ iroyin Vanguard pe niṣe lawọn janduku naa ṣina ibọn bolẹ ni kete ti wọn de ibẹ.

Lara awọn to ba ikọlu naa lọ ni Kazeem Akande, to jẹ ẹni aadọrin ọdun.

Awọn ọkọ alawọ pupa kan to bajẹ lasiko ikọlu naa, Gbogbo gilasi ọkọ naa ni wọn ti fọ tan.

Ẹlomiran to tun ku ni Lekan ti wọn pa ninu iṣẹlẹ mii lagbagbe Egbatedo. Ọgbẹ ọta ibọn lo gbemi awọn mejeji.

Awọn mii ti wọn farapa ni obinrin kan to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, Kehinde Salaudeen to jẹ ẹni ọgọta ọdun; Olalekan Mutiu ati ọmọ ọdun mẹtala kan, Rodiyat Ariyo, atawọn mii.

Wọn ti gbe oku Lekan lọ sile igbokupamọsi ni fasiti ẹkọṣẹ iṣẹgun ipinlẹ naa to wa niluu Osogbo nigba ti wọn gbe oku Kazeem lọ sile iwosan gbogbogbo Osogbo ki wọn to gbe fun awọn mọlẹbi rẹ.

Eeyan marun un ọtọtọ ni a gbọ pe wọn n gba itọju nile iwosan Osogbo Central Hospital, nigba ti ọmọ ọdun mẹtala to farapa n gba itọju nile iwosan mii.

Wayi o, bo tilẹ jẹ awọn kan ti sọ pe ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni rogbodiyan naa, ẹgbẹ oṣelu APC ti fẹsun kan gomina Adeleke pe awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ lo kọlu awọn ọmọ ẹgbẹ oun.

Ṣugbọn Ademola Adeleke ti fesi pe ko ri bẹẹ.

Ki lo gbe gomina Ademola Adeleke lọ si ọọfisi ajọ DSS?

Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Ọsun.

Oríṣun àwòrán, ademola adeleke/x

Gomina Ademola Adeleke ti lọ si ọọfisi ajọ DSS lati ṣide ipade awọn adari ajọ ọtẹlẹmuyẹ to n waye niluu Osogbo.

Ipade awọn adari DSS naa ni wọn pe "South-West Zonal Conference of State Directors of the Service."

Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ n lọ ni igboro pe rogbodoyan to waye ṣaaju lo gbe gomina naa lọ si ọọfisi DSS.

Wayi o, ninu atẹjde kan ti agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed fi lede, o ni Adeleke koro oju si iṣẹlẹ iṣẹkupani ati idaluru to waye nibẹ, o si ti ke si awọn agbofinro ki wọn ṣewadii rẹ finifini.

Rasheed ni irọ ni iroyin ti awọn kan n gbe kiri igboro pe ijọba Adeleke lo wa nidi ikọlu naa.

Awọn ẹgbẹ oṣelu tọwọ-bọwe adehun alaafia ni Osun

Ẹwẹ, awọn ẹgbẹ oṣelu to n kopa ninu eto idibo gomina to n bọ lọna nipinẹ naa ti tọwọ-bọwe adehun alaafia, eyii ti wọn pe ni Peace and Accountability Charter.

Adehun alaafia naa ni wọn fi ṣeleri pe wọn ko ni lọwọ ninu jadidijagan oṣelu tabi orogbofiyan kankan ṣaaju, lasiko ati lẹyin eto idibo naa.

Ẹgbẹ Osun Development Association (ODA) lo ṣagbatẹru eto ọhun to waye ni gbagede Aurora Event Centre, Osogbo.

Lara awọn to kopa ninu rẹ ni awọn olori ẹgbẹ oṣelu, awọn oṣiṣẹ eto idibo, awọn agbofinro, awọn ọba alade, awọn ẹgbẹ ti kii ṣe ti ijọba, awọn olori ẹlẹsin atawọn ẹgbẹ mii.

Gomina Ademola Adeleke, ti igbakeji rẹ, Kola Adewusi ṣoju fun nibẹ sọ pe ijoba oun ko ni lọwọ ninu ohunkohun to ba lodi si ofin.

Aworan awọn eeyan meji kan to faragbọgbẹ. wọn wa ni ori ibusun ni ile iwosan kan.

Ọba alade rọ awọn oloṣelu Osun ki wọn yago fun iwa janduku

Ọlẹẹgbẹ ti Akingbade Ipoye Ife, ọba Fakowajo Adekayaoja ti rọ awọn oloṣelu ati gbogbo awọn alatilẹyin wọn ki wọn gba alaafia laaye lasiko eto idibo to sunmọle.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ninu aafin rẹ, Ọba Adekayaoja kọminu lori gbogbo rogbodiyan oṣelu to n waye kaakiri awọn agbegbe kan nipinlẹ naa.

O ni awọn oloṣelu ko gbọdọ gba ki afojusun wọn lati de ori ipo mu wọn da omi alaafia ilu ru.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, eto ijọba awarawa ni eto idibo jẹ, awọn oloṣelu ko si gbọdọ sọ ọ di nnnkan jagidijagan.

Lẹyin naa lo kilọ fun awọn ọdọ ki wọn ma fi ara wọn silẹ fun oloṣelu gẹgẹ bi irinṣẹ ijọgbọn.