Ohun tí a mọ̀ nípa ikú ọ̀dọ́bìnrin Mary Habila, òṣíṣẹ́ Mínísítà David Umahi tí wọ́n ló kú sílé rẹ̀

Oríṣun àwòrán, David Umahi/Mary Habila/FB
Lati bii ọjọ meloo kan ni iroyin iku ọdọmọbinrin kan, Mary Habila, ẹni ti wọn lo ku silee Minisita Iṣẹ òde, David Umahi, ti gba ori ayelujara kan.
Iroyin kan tilẹ sọ pe ihoho ni wọn ba oku Oloogbe Mary, ẹni ti a gbọ pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ eleto ilera fun Minisita naa loni ko to jade laye, eyi to si n mu ki iroyin naa maa tanran kalẹ bii ina inu ọyẹ.
Nigba ti ọrọ naa ko si yee tanka, David Umahi naa jade sọrọ l'Ọjọbọ.
Ni ipari oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii ni iroyin kọkọ jade nipa iku Mary Habila, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26) ti a gbọ pe iṣẹ nọọsi lo n ṣe.
Ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun David Umahi Federal University Teaching Hospital to wa nipinlẹ Ebonyi ni wọn ti fidi iku naa mulẹ.
Iroyin sọ pe Mary, ọmọ bibi ipinlẹ Kaduna, ku lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹfa ọdun 2026, nile David Umahi, nigba to de si Ebonyi lẹyin irinajo ti oun ati ikọ olutọju minisita naa jọ rin.
Fọto oku Mary to gbode lojiji lai si ẹni to le fidi ohun to pa a mulẹ lo mu awọn ajafẹtọọ ọmọniyan maa beere ohun to pa a, ati pe ṣe ile David Umahi lo ku si loootọ.
Amọ ṣaaju ki Umahi funra rẹ to sọrọ lori iku Mary ni agbẹnusọ rẹ, Francis Nwaze, ti sọ fun BBC pe ki I ṣe ile Umahi ni ọmọbinrin naa ku si.
Nwaze sọ pe ninu ọkan lara awọn ile tawọn oṣiṣẹ inu ọgba naa n gbe ni Mary dakẹ si.
"Ile yẹn ki I ṣe lara ile Minisita, ile tawọn oṣiṣẹ n gbe to wa ninu ọgba naa ni. Ọmọbinrin yẹn ki I gbe nibẹ, o kan maa n wa ti iṣẹ ba wa lati ṣe ni.
"Ninu ọkan lara awọn ile awọn oṣiṣẹ David Umahi Teaching Hospital lo ti ya fọto ti wọn n pin kiri, ki i ṣe ile Umahi,'' agbẹnusọ minisita naa ṣalaye fun BBC.
"O ba ọrẹkunrin rẹ sọrọ ko to ku, o sọ fun un pe imu oun n ṣẹjẹ''
Nigba to n ṣalaye ọrọ fawọn oniroyin niluu Abuja, Umahi sọ pe ọpọ nnkan lo rọ mọ iku Mary.
Minisita naa sọ pe ọrẹkunrin Mary gan-an ṣalaye ohun ti wọn jọ sọ ṣaaju iku ojiji naa.
" O ba ọrẹkunrin rẹ sọrọ ko to ku, o sọ fun un pe imu oun n ṣẹjẹ.
" Ọkunrin naa sọ fun un pe oun ko ni I maa ba a sọrọ lọ bi imu rẹ ṣe n ṣẹjẹ, nitori o le fa wahala fun un ju bẹẹ lọ.
"Mary bẹ ẹ pe ko ma ṣe ge ipe naa, amọ ọrẹkunrin rẹ naa ko dahun, o ge ipe naa. Amọ nigba to pe pada, ọrẹbinrin rẹ ko gbe foonu mọ."
Umahi lo ṣalaye bẹẹ.
O ni ọjọ keji ni awọn oṣiṣẹ bii ti Mary ri oku rẹ, lẹyin ti wọn ko ri i ba sọrọ lorii foonu.
"O ti ara rẹ mọnu yara rẹ, nigba ti wọn o ri I laaarọ ọjọ keji, wọn ja ilẹkun rẹ wọle, wọn si ri i pe omi ẹrọ ibẹ ṣi n yọ da silẹ.
"Ohun to wa ya mi lẹnu lorilẹede yii ni bi wọn ṣe sọ gbogbo ẹ di ọrọ oṣelu. "
Bẹẹ ni Minisita David Umahi wi.
Umahi ṣalaye pe oun tilẹ fẹ ki wọn ṣe ayẹwo oku naa lati mọ ohun to pa a, amọ baba rẹ lo ni oun ko fẹ bẹẹ.
Ọlọpaa lawọn yoo ṣewadii
Bo tilẹ jẹ pe Baba to bi Mary Habila, Tanko Habila Wisdom,sọ pe oun ko fẹ ki wọn ṣe ayẹwo oku rẹ lati mọ iku to pa a, sibẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ebonyi ti ni awọn yoo tẹsiwaju ninu iwadii iku naa.
Agbẹnusọ ọlọpaa Ebonyi, Joshua Ukandu, sọ pe ọkan lara awọn ikọ to ba David Umahi lọ si ily Uburu ni Mary, nibi ti wọn ti ri oku rẹ ninu ọkan ninu awọn yara ile naa.
Ukandu sọ pe lẹyin tawọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ikọ ọlọpaa lati agọ Ohaozara gbera lọ sibẹ, wọn si kede iku ọmọbinrin naa ni David Umahi Federal University Teaching Hospital, Uburu, lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹfa.
Agbẹnusọ ọlọpaa naa sọ pe awọn ti fa iwadii naa le ẹka SCID to n tọpinpin iwa ọdaran lọwọ, ati pe bi ayẹwo oku naa yoo ṣe waye ni awọn n reti.


























