Ilé aṣòfin àgbà ní kí ìjọba yé dáríji àwọn agbéṣùmọ̀mí Boko Haram tó bá juwọ́ sílẹ̀ mọ́

Awọn agbeṣumọmi to fi asọ boju, gbe ibọn dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile aṣofin Naijiria ti ni ki ijọba apapọ da eto ṣiṣe atunto ati dida awọn ẹgbẹ Boko Haram ti wọn juwọ silẹ pada saaarin ilu fun igba kan na.

Awọn aṣofin naa tun rọ awọn ẹṣọ aabo lati tẹmpẹlẹmọ akitiyan wọn lati nawọ gan, ki wọn si tun fiya awọn agbeṣumọmi to n ṣokunfa awọn ikọlu to n waye kaakiri ni orilẹ ede Naijiria.

Ile aṣofin agba fẹnuko lori igbesẹ yii nibi ijiroro to waye nile aṣofin lọjọ Iṣẹgun lori aba ti aṣofin Abdulaziz Yar'Adua fi siwaju ile lori awọn ikọlu to n waye lemọlemọ kaakiri Naijiria to fi mọ ijinigbe ati ipaniyan.

Aṣofin naa ni jiji ati pipa awọn ọmọ ogun tẹlẹ ri safihan pe ọrọ aabo to n ba Naijiria finra jẹ idunkoko nla si eto aabo Naijiria.

Ile aṣofin tun dari igbimọ to n ri si eto aabo rẹ lati mu alekun ba ojuṣe wọn nipa mimojuto aabo, ki wọn si ri pe wọn ri daju pe awọn olori ileeṣẹ eto aabo n ṣiṣẹ wọn bo ṣe yẹ.

Wọn fẹnuko pe ki ikọ kan ti aarẹ ile aṣofin agba, Godswill Akpabio maa ko sodi lati lọ ṣabẹwo si Aarẹ Bola Tinubu lati jiroro lori ipenija aabo to n fi ojoojumọ peleke sii.

Nigba to n gbe aba naa kalẹ, Sẹnetọ Yar'Adua kọminu lori bi awọn agbeṣumọmi ṣe n ṣekọlu sawọn ọga ologun, awọn to ṣi wa lẹnu iṣẹ atawọn ti wọn ti fẹyinti ni ọpọ ipinlẹ eyi to ti ṣokunfa ọpọ iku, fifi awọn ologun naa si ahamọ awọn ajinigbe, sisan owo itusilẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O darukọ awọn iṣẹlẹ bẹẹ to ti waye bii jiji Ọgagun Rabiu Garba Yandoto atawọn ọmọ rẹ meji gbe ni opopona Gusau-Tsafe ni ipinlẹ Zamfara ati pipa Ọgagun Ricgard Chukwudi Duru ni ipinlẹ Imo lẹyin ti wọn san owo itusilẹ $50,000 fawọn ajinigbe naa.

"Ijọba gbọdọ maa fiya to tọ jẹ ẹnikẹni ti ọwọ ba ti tẹ pe o lọwọ ninu iwa igbeṣumọmi tabi iwa ọdaran mii"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Yatọ si eyi aṣofin ọhun tun sọrọ lori Ọgagun Uwem Udokwere tawọn ajinigbe pa sile rẹ ni Lokogoma, Abuja lọdun 2024 ati olori NYSC tawọn agbebọn ji gbe lọdun 2025 to lo ọjọ marundinlọgọta ni ahamọ wọn ko to gba itusilẹ ni oṣu Kẹrin, ọdun 2025.

Yar'Adua fi kun pe pipa Ọgagun Abubakar atawọn mii si ahamọ ajinigbe jẹ adanu nla si orilẹ ede yii to si n ṣafihan ipenija aabo nla to n koju Naijiria.

O ṣekilọ pe dida oju oro kọ awọn Ologun paapaa awọn to ti dipo nla mu ninu iṣẹ Ologun latọwọ awọn agbeṣumọmi ati agbebọn ṣafihan ewu nla to n koju aabo Naijiria.

Lẹyin ijiroro lori aba naa, ile aṣofin fẹnuko lati ke si ijọba apapọ lati ṣe idaduro didariji awọn agbeṣumọmi to ba ti juwọ silẹ fun ijọba, ki wọn si ye da wọn papọ saaarin ilu mọ.

Wọn ni dipo bẹẹ niṣe ki ijọba maa fiya to tọ jẹ ẹnikẹni ti ọwọ ba ti tẹ pe o lọwọ ninu iwa igbeṣumọmi tabi iwa ọdaran mii.

Nigba ti wọn n gboriyin fawọn ileese aabo to fi mọ awọn Ologun, ileeṣẹ ọlọpaa, DSS, NSCDC atawọn ẹṣọ aabo mii fun akitiyan wọn lori aabo Naijiria, wọn pe fun ajọṣepọ to danmọran laaarin awọn ẹṣọ aabo yii lojuna ati koju ipenija aabo.

Ile aṣofin agba ni igbega gbọdọ ba bi won ṣe n pin iroyin nipa aabo, iṣamulo imọ ẹrọ ati ajọṣepọ pẹlu awọn araalu lati dena ikọlu lọjọ iwaju.

Wọn fi kun pe ọpọ ijinigbe lasiko yii lo jẹ pe ipaniyan lo n gbẹyin rẹ, sisan owo itusilẹ gọbọi, sisọ awọn ẹbi ẹni ti wọn ba ji gbe sinu ipayinkeke ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti wọn si ni o pọn dandan ki ayipada ba eyi ti orilẹ ede Naijiria yoo ba tẹsiwaju.