Wo ibi ti ǹkan dé dúró nínú ìbò awọn ọmọ Amẹrika tí yóò sọ bí ìgbẹ̀yìn ìjọba Trump yóò ṣe rí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ọmọ ilẹ Amẹrika ti bẹrẹ eto idibo to maa n waye laarin saa ijọba, eyii ti wọn n pe ni 'midterm elections'.
Ninu eto idibo yii lawọn araalu yoo ti dibo yan awọn eeyan sipo aṣojuṣofin ati ipo awọn aṣofin.
Esi eto idibo naa lo ṣeeṣe ko sọ ibi ti awọn ọmọ ilẹ naa yoo dojukọ ninu eto idibo Aarẹ ọdun 2028.
Ipinlẹ marun un ọtọtọ ni yoo dibo lori ẹto awọn ọkunrin ti wọn fi iṣẹ abẹ parada si obinrin atawọn obinrin ti wọn pa ara wọn da si ọkunrin.
Lawọn ipinle mii, ọrọ ẹtọ lori oyun ṣiṣẹ lo kan awọn, nigba ti ọrọ owo ori fun awọn olowo gọbọi kan awọn eeyan California.
Fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democrat, eyii yoo jẹ igba akọkọ ti wọn yoo maa dibo lẹyin ti wọn lulẹ ninu eto idibo gbogbogbo to waye lọdun 2024.
Fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican ẹwẹ, afojusun wọn ni lati jẹ ki awọn ti yoo wọ ile igbimọ aṣofin jẹ awọn ti yoo ṣe ti Aarẹ Trump.
Bo tilẹ jẹ pe awọn iroyin kan n fi han pe o ṣeeṣe ki ẹgbẹ oṣelu Democrat ṣaṣeyọri ninu eto idibo naa, o digba ti wọn ba ka esi ibo naa tan ki a to le fidi awọn to jawe olubori mulẹ.
Lara awọn agbegbe ti eto idibo naa ti kọkọ bẹrẹ ni Vermont, lẹyin naa lo bẹrẹ lawọn agbegbe mii bii New York, New Jersey, Virginia ati Maine.
Ṣaaju eto idibo naa ni Aarẹ Trump ti kọkọ juwe awọn oludije ninu ẹgbẹ oṣelu Democrat gẹgẹ bii awọn ti ipo ijọba ko tọ si.
O tun sọ pe asiko yii ni awọn araalu n pa owo to pọ julọ wọle ninu itan, lẹyin naa lo mẹnuba ọrọ irinajo awọn ọmọ ilẹ mii si Amẹrika ati ogun Iran.
Wayi o, awọn iwadii kan fidi rẹ mulẹ pe pupọ awọn ọmọ Amẹrika ni inu wọn ko dun si Trump, paapaa lori ọwọngogo to gbode ati ogun ti ilẹ naa ati Israel n gbe ti Iran.


























