Awuyewuye lórí ₦70,000 owó ìrànwọ́ tí Tinubu kéde fáwọn òṣìṣẹ́, ọ̀pọ̀ èèyàn kọminú pé ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù ọmọ Naijiria ni kò lánfààní sówó náà

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/X
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n kominu lori N70,000 owo iranwọ oṣooṣu ti ijọba Aarẹ Bola Tinubu kede fawọn oṣiṣẹ ijọba apapọ latari bi epo bẹntiroolu ṣe n gbowo lori si i.
Ọpọ eeyan lo ti sọ pe ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ọmọ Naijiria bi awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ aladaani, oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ to fi mọ awọn ti ko ri iṣẹ ṣe ni ko ni lanfaani si owo iranwọ ti ijọba apapọ kede fawọn oṣiṣẹ naa.
Ohun ti ọpọ eeyan n sọ ni pe awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ ti yoo maa jẹ anfaani owo iranwọ N70,000 loṣooṣu yii kere ninu gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria.
Laipẹ yii ni Aarẹ Tinubu buwọlu owo iranwọ naa eyi ti minisita fọrọ oṣiṣẹ kede igbesẹ ọhun.
Ijọba apapọ gbe igbesẹ yii lẹyin ti apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC leri wi pe awọn yoo gunle iyanṣẹlodi kaakiri Naijiria latari bi owo epo bẹntiroolu ṣe n lọ soke looorekoore.
NLC tun kepe ijọba Tinubu lati ṣe alekun owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ eyi ti i ṣe N70,000 bayii.
Ọjọbọ ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ karun un oṣu Kọkanla ni ijọba kede wi pe awọn oṣiṣẹ yoo bẹrẹ sii maa gba owo iranwọ naa.
Amọ, awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ nikan ni yoo lanfaani si owo iranwọ naa.
Ẹwẹ, ajọ oluṣiro National Bureau of Statistics, NBS, ti sọ pe eeyan 71,200,000 lo n ṣiṣẹ fun ara wọn ni Naijiria nigba ti eeyan 3,320,000 jẹ oṣiṣẹ ijọba.
Ajọ NBS ṣalaye pe eeyan 9,640,000 lo n ṣiṣẹ nileeṣẹ aladaani ni Naijiria.
Alaye ajọ NBS yii tumọ si pe eeyan perete ni yoo jẹ anfaani owo iranwọ N70,000 ti ijọba kede yii fawọn oṣiṣẹ.
Ṣaaju loṣu Kẹsan an to kọja ni ajọ NBS kede pe owo ounjẹ n lọ soke ni Naijiria pẹlu iwọn 19.59% nigba tawọn eeyan n ra lita epo bẹntiroolu kan ni N1,370 si N1,420.
Bẹẹ ni owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ ko ju N70,000 lọ.
Faakaja laarin aarẹ ẹgbẹ NLC ati TUC lori ọrọ N70,000 owo iranwọ ti ijọba buwọlu fawọn oṣiṣẹ
Ẹwẹ, aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, Joe Ajaero ati aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC, Festus Osifo, ti n tako ara wọn lori ẹni to laṣẹ lati dunaadura owo oṣu ati owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ pẹlu ijọba apapọ.
Awuyewuye yii jẹ jade lẹyin ti ijọba apapọ buwọlu sisan N70,000 fawọn oṣiṣẹ gẹgẹ bi owo iranwọ fun oṣu mẹfa latari bi epo bẹntiroolu ṣe gbowo lori.
Nigba to n sọrọ lori eto The Morning Brief nileeṣẹ tẹlifisan Channels TV, Ajaero ni ẹgbẹ NLC laṣẹ lati dunaadura owo oṣu ati owo ajẹmọnu fawọn oṣiṣẹ pẹlu ijọba nipa titẹle alakalẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ lagbaaye, the International Labour Organization (ILO).
Ajaero sọ pe ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC le dunaadura pẹlu NLC nigba ti NLC le ba ijọba sọrọ lorukọ awọn oṣiṣẹ.
Ninu ọrọ tiẹ, aarẹ ẹgbẹ TUC, Osifo ṣalaye lori eto The Morning Brief ti ileeṣẹ Channels TV kan naa wi pe NLC ko ba TUC sọrọ kankan lori adehun N70,000 owo iranwọ ti ijọba buwọlu fawọn oṣiṣẹ.
Osifo wa kepe Ajaero wi pe ko mu ẹri to le fidi rẹ mulẹ pe ilana ẹgbẹ oṣiṣẹ lagbaaye ILO faye gba NLC lati dunaadura lorukọ ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC.
Aarẹ ẹgbẹ TUC sọ pe ko si ibi ti ẹgbẹ oṣiṣẹ lagbaaye ILO ti sọ pe ẹgbẹ oṣiṣẹ kan le dunaadura fun ẹgbẹ oṣiṣẹ mii.
Amọ, Ajaero duro lori ẹsẹ rẹ pe NLC lo gbe igbesẹ lati ba ijọba apapọ sọrọ lori owo iranwọ N70,000 ti Tinubu buwọlu fawọn oṣiṣẹ.
''A fun ijọba ni gbedeke lati wa nnkan ṣe si ọrọ naa, bi bẹẹ kọ, a o bẹrẹ iyanṣẹlodi.
Ijọba si beere fun ọjọ mẹrin lati ba wa ṣepade pọ.
Lẹyin ti ipade naa waye ni ọrọ N70,000 owo iranwọ fawọn oṣiṣẹ jade,'' Ajaero lo sọ bẹẹ.
Aarẹ ẹgbẹ NLC fikun ọrọ rẹ pe ẹgbẹ oṣiṣẹ ko le sọ nipa alekun owo oṣu bayii tori ijọba ko tii gbe igbimọ ti yoo dunaadura pẹlu aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ dide.



























