Wo àwọn adarí ẹgbẹ́ NURTW tí wọ́n ti gbẹ̀mí wọn nílùú Eko

Oríṣun àwòrán, The Punch
Ẹnu lọlọ yii lawọn agbebọn ṣekupa akọwe ẹgbẹ awọn awakọ, NURTW, nipinlẹ Eko, Toba Ajiboye, ti inagijẹ rẹ n jẹ Toba Ijaya.
Ajiboye ku lẹyin ti awọn kan ṣadede ṣina ibọn fun ọkọ rẹ loju ọna Ikorodu, lẹyin ti wọn gbe dele iwosan lo fi aye silẹ latari ọta to fi fara gba.
Wayi o, kii ṣe Toba Ijaya ni akọkọ adari ẹgbẹ NURTW ti wọn yoo ṣekupa nipinlẹ Eko.
Iwọnyii ni akosilẹ awọn ọmọ ẹgbẹ ati adari ẹgbẹ NURTW ti awọn kọlọrọsi ẹda ti gbẹmi wọn ni Eko fun idi kan tabi omiran.
Alhaji Saula Saka (2008)
Ọjọ kẹfa, oṣu Kinni, ọdun 2008 ni wọn ṣekupa Alhaji Saka Saula ( tabi Saula Saka) nile rẹ to wa lagbegbe Iyana Ipaja.
Awọn ẹgbẹ ajafẹtọọmọniyan sọ pe ọpọ igba ni wọn yinbọn fun ọkunrin ọhun lasiko ikọlu naa.
Ajọ Observatory for the Protection of Human Rights Defenders ke si ijọba ki wọn gbe iwadii dide lori iṣẹlẹ naa lọdun naa lọhun.
Azeez Otun (Ashake) (2014)
Lẹyin iwọde ẹgbẹ oṣelu PDP kan to waye ni gbagede Tafawa Balewa Square, to wa ni Lagos Island ni wọn yinbọn pa Ashake logunjọ oṣu Kẹsan an, ọdun 2014.
Eeyan mẹta mii lo tun ku ninu ikọlu ọjọ naa.
Ọlọpaa mu afurasi meje lori iṣẹlẹ naa amọ ile ẹjọ tu wọn silẹ lori pe ko si ẹri to dantọ lati ṣedajọ wọn.
Olayemi Eniola (Esi Oluwo) (2015)
Olayemi Eniola, ti ọpọ mọ si Esi Oluwo tabi Baba Esi ku lẹyin ija to waye ni Osohodi lọdun 2015.
A gbọ pe ọrọ oṣelu lo ṣokunfa ikọlu to mu ẹmi rẹ lọ.
Kunle Mamowora (Mammok) (2015)
Oloogbe naa to jẹ oludaabobo alaga ẹgbẹ ọhun, Musiliu Akinsanya (MC Oluomo), ni wọn pa siwaju ile mọlẹbi rẹ ni Oshodi.
Nigba ti yoo di ọdun 2019 ni ile ẹjọ fi afurasi meji, Ayuba Balogun ati Evans Adamson pamọ si ọgba ẹwọn lori ikọlu naa.
Nnkan bii aago meje abọ alẹ ninu oṣu Kẹsan an, ọdun 2015 ni wọn gbẹmi ọkunrin ọhun.
Iroyin ni Mafoluku ni ọkunrin naa ti lọ gẹ irun ki wọn to kọlu u.
Rasaq Bello (Hamburger) (2017)
Asiko eto idibo ijọba ibilẹ kan to waye ni Oshodi ni wọn ti yinbọn pa Hamburger.
A gbọ pe awọn ẹgbẹ alatako meji ni wọn n ja lasiko eto idibo naa ki ọta ibọn to ba a.
Ganiyu Ayinla (Pinero) (2018)
Inu oṣu Kinni, ọdun 2018 ni wọn yinbọn pa Pinero.
Ọlọpaa mu afurasi mẹrin lori ikọlu naa lori ẹsun pe eto idibo ẹgbẹ ọhun to n bọ lọna ni wọn ṣe gbẹmi rẹ.
Ismaila Azeez Ibrahim (Legacy) (2019)
Ibi ipolongo ibo oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ni wọn ti pa Legacy lọdun 2019.
Niṣe ni wọn gun ọkunrin naa pa lọdun naa lọhun.
Samuel Kayode (Ekpo Kinkin) (2021)
Oloogbe naa ni igabkeji alaga NURTW ni Agboju ṣaaju iku rẹ.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, asiko to n gbiyanju lati daabo awọn oloṣelu meji kan lasiko ipolongo ibo ni ibọn ba a.
Ọlọpaa bẹrẹ iwadii amọ a ko mọ ayọrisi iwadii ọhun.
Sulaimon Lawal Onaolapo (Arikuyeri) (2022)
A gbọ pe ija lori ẹni ti yoo ṣakoso ibudokọ ni wọn tori rẹ pa Arikuyeri ni Mile 12.
Oloogbe naa lo n ṣakoso ibudokọ Mile 12 ṣaaju iku aitọjọ rẹ.
Toba Ajiboye (Toba Ijaya) (2026)
Inu ọdun 2026 yii ni wọn pa Ajiboye.
Iroyin ni asiko ti oloogbe naa n bọ lati ile ọrẹ korikosun rẹ kan ni adugbọ Fadeyi ni ikọlurẹ waye.
A gbọ pe awọn agbebọn naa kọlu Ajiboye loju ọna marosẹ Ikorodu nibi ti wọn ti ṣina ibọn fun ọkọ rẹ ti ọta ibọn si wa lara ọkọ ọhun.
Awọn fidio ati aworan to n milẹ titi lori ayelujara ṣafihan ọkọ naa pẹlu oniruru ọta ibọn lara n ati iwaju gilaasi rẹ.
A kọkọ gbọ pe Ijaya atawọn mii ti wọn wa ninu ọkọ naa moribọ ninu ikọlu ọhun amọ o fara gbọta ibọn.
Lẹyin naa ni a gbọ pe akọwe NURTW naa pada dagbere faye latari ọta ibọn to far agba.



























