Àwọn afurasí tó lé ní 400 yóò fojú balé ẹjọ́ lónìí lórí ìgbéṣùmọ̀mí

Oríṣun àwòrán, Others
Ko din ni awọn afurasi agbeṣumọmi irinwo ti wọn yoo farahan nile ẹjọ lọjọ Aje ni Naijiria ni ile ẹjọ giga ilu Abuja, olu ilu Naijiria.
O jẹ ọkan gboogi lara igbẹjọ ti yoo waye lori ipenija aabo to n ba orilẹ ede yii, ti wọn si n ri gẹgẹ bi ọna ti ijọba n gba lati koju laasigbo to n waye leralera lasiko yii.
Igbẹjọ yii lo n waye lẹyin ọsẹ diẹ ti irufẹ igbẹjọ bẹẹ waye ninu oṣu Kẹrin ọdun yii nibi ti ijọba ti wọ awọn afurasi to le ni ẹẹdẹgbẹta lọ sile ẹjọ lori igbeṣumọmi ti ile ẹjọ si dajọ fun awọn to le ni 386 ninu wọn.
Igbẹjọ ti yoo waye lonii ni ọpọ eeyan n ri gẹgẹ bi itẹsiwaju ijọba lati gbe igbesẹ to tọ lati kasẹ igbẹjọ naa nilẹ ati lati ṣedajọ ododo fawọn afurasi agbeṣumọmi naa.
Oniruuru ẹsun ni awọn afurasi agbeṣumọmi naa n koju to fi mọ ṣiṣe ikọlu sawọn araalu, ipese ounjẹ, ibugbe, ohun irinna fawọn Boko Haram ati ikọ agbeṣumọmi mii.
Igbagbọ wa pe ile ẹjọ yoo mu igbẹjọ naa y ani kiakia pẹlu agbekalẹ awọn akanṣe ile ẹjọ to maa mu igbejọ ya.
Orilẹ ede Naijiria n koju igbeṣumọmi latọwọ oriṣiriṣi awọn ikọ agbeṣumọmi bii Boko Haram, Iswap ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọpọ eeyan lo ti padanu ẹmi wọn sọwọ awọn agbeṣumọmi yii nipasẹ oniruuru ikọlu awọn oniṣẹ laabi yii ni ọdun yii nikan.
Lati bii ọdun mẹrindinlogun sẹyin ni awọn agbeṣumọmi ti n ṣọṣẹ ni Naijiria, gbẹmi ọpọ eeyan, tawọn eeyan to le ni miliọnu meji si ti di ailanilelori mọ.
Amọ diẹ lawọn to maa n koju igbẹjọ lori igbeṣumọmi, ti ọpọ awọn agbeṣumọmi si maa n lo ọpọ ọdun ni ahamọ lai koju igbejọ kankan.
Yatọ si igbeṣumọmi, oniruuru ikọlu lo tun n waye laaarin awọn agbẹ atawọn darandaran ti igbagbọ wa pe wọn jẹ iran Fulani.
Ikọlu yii saba maa n yọri si ipaniyan paapaa ni ẹkun aarin gbungbun ati iwọ oorun ariwa Naijiria.
Ipenija aabo mii to tun n waye ni Naijiria ni awọn agbebọn ti wọn maa n gbe eeyan lati gba owo. Awọn wọnyii lo saba n ṣekọlu si ile ẹkọ lati ji awọn akẹkọọ gbe lati fi gba owo lawọn ilu to wa ni ẹsẹ kuku.

























