Èèyàn mẹ́rin míràn ni ajínigbé tún pa ní Mowe, kì í ṣe ṣọ́jà nìkan - Iléeṣẹ́ ológun

Awon sọja lagbegbe kan tawọn eeyan wa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Yatọ si ṣọja kan ti iroyin sọ pe awọn ajinigbe to ṣoro ni Mowe, ipinlẹ Ogun, pa lọjọ Aje, ileeṣẹ ologun ẹka tipinlẹ Ogun ti fidi ẹ mulẹ pe, wọn tun pa eeyan mẹrin mi-in.

Ninu atẹjade ti Ọgagun Idereghi Samuel Akari, Igbakeji ọga to n ri si ikede nileeṣẹ ologun 35 Artillery Brigade, Alamala niluu Abeokuta, fi sita lo ti ṣalaye pe:

"Ikọ ologun 35 Artillery Brigade, pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ọlọpaa, jọ sowopọ koju ijinigbe kan, nibi ti wọn ti fẹ ji awọn oṣiṣẹ ọmọ ilẹ China kan gbe labule Magbon, Mowe, nijọba ibilẹ Obafemi-Owode, ipinlẹ Ogun

"Iṣẹlẹ naa waye lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa ọdun 2026, nigba ti awọn afurasi ajinigbe dena de awọn agbofinro, lasiko tawọn agbofinro naa n gbiyanju lati da aabo bo awọn oṣiṣẹ to n wa yẹpẹ.

"Ija nla bẹ silẹ, ibọn bẹrẹ si i ro lakọlakọ, nigba naa ni awọn agbofinro pa ọkan lara awọn alatako naa."

O tẹsiwaju pe awọn yoku ku sa lọ nipa gbigba oju igbo lọ soju ọna Odo Ogun.

"Bi wọn ṣe n sa lọ ni wọn ko eeyan marun-un ti wọn ti mu tẹlẹ lọ, wọn si pada pa mẹrin ninu wọn"

Gẹgẹ bi Ọgagun Idereghi ṣe wi, awọn ajinigbe yoku sa lọ loju ija naa, ṣugbọn wọn ko eeyan marun-un lọ lati fi da aabo bo ara wọn.

O ni wọn ṣe eyi ki awọn ṣọja ma baa le yinbọn mọ wọn mọ, wọn fi awọn eeyan naa ṣe od iyi ara wọn ka nitori ibọn ologun.

"Wọn pada pa mẹrin ninu awọn eeyan ti wọn gbe lọ naa ki wọn too lo ọkọ oju omi sa lọ.

"Ọkan lara awon ti won mu naa to raye sa mọ wọn lọwọ, ṣalaye pe awọn ajinigbe gbe oku eyi to ku lara wọn lọ.

Ninu ikọlu naa ni ṣọja kan ti padanu ẹmi rẹ bi Idereghi ṣe wi, nigba ti sọja keji farapa.

"Ṣọja kan ku, ikeji farapa, awọn ọlọpaa meji naa si farapa pẹlu ọta ibọn to ba wọn."

O fi kun un pe awọn ti gbe oku ṣọja to doloogbe naa lọ si ile igbokuusi ijọba to wa ni Sagamu, pẹlu oku awon eeyan ti awọn ajinigbe naa pa.

Awọn to si farapa n gba itọju lọwọ bo ṣe sọ.

Ọga ologun naa tẹsiwaju pe ohun gbogbo ti pada sipo, ki araalu fi ọkan balẹ.

Afurasí ajínigbé pa ṣọ́jà ní Mowe, ìkejì farapa

Nnkan ko fararọ fawọn ologun meji kan lọjọ Aje, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii, nigba ti awọn kan ti wọn fura si pe ajinigbe ni wọn, kọlu agbegbe Magbon -Etido, Mowe nipinlẹ Ogun, ti wọn pa sọja kan, ṣe ikeji leṣe.

Bo tilẹ jẹ pe awọn agbebọn ni awọn ara agbegbe naa tilẹ kọkọ ro pe wọn ya de, ileeṣẹ ọlọpaa Ogun fidi ẹ mulẹ pe iṣẹlẹ naa ki i ṣe ti bandiiti rara.

Magbon-Etido, ni Mowe, wa nijọba ibilẹ Obafemi Owode, ipinlẹ Ogun.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọwọ aarọ ọjọ Aje naa ni iṣẹlẹ yii waye gẹgẹ bi awọn o ṣoju mi koro ṣe sọ.

Olugbe agbegbe naa kan ti ko darukọ ara rẹ nitori aabo, ṣalaye pe toguntogun ni awọn ajinigbe naa de.

O ni bi wọn ṣe de ni wọn dojukọ ibi ti wọn fẹẹ kọlu.

Bakan naa ni fọnran ohun kan to jade lori ayelujara, ti ẹnikan to pe ara rẹ ni Jimoh Owolabi to ni oun ni Alaga agbegbe Onidagbasoke Ajumoni ṣe, ṣalaye pe ọkunrin kan to n wa kusa yẹpẹ, ti awọn mọ si Kapo, ni awọn ajinigbe naa fẹ ji gbe lọ.

Lati dena ijinigbe naa ni awọn ṣọja meji to n ṣọ Kapo fi koju awọn ajinigbe ọhun bo ṣe wi, nigba naa si ni wọn yinbọn fun wọn.

Jimoh tẹsiwaju pe ibọn naa lo pa ṣọja kan, ti ikeji si faragbọta ṣugbọn ti ko ku ni tiẹ.

"Ko si bandiiti ni Magbon, awọn ajinigbe lo wa koju awakusa yẹpẹ kan ta a mọ si Kapo.

"Lasiko ikọlu naa ni ẹṣọ to n ṣọ ọ pade iku, ti ikeji rẹ si farapa."

Bẹẹ ni fọnran ohun to jade lori ayelujara naa ṣalaye, pẹlu afikun pe iroyin eke ni pe bandiiti ti wọ Magbon Etido, ni Mowe, ipinlẹ Ogun.

O fi kun un pe awọn ọlọpaa, ologun atawọn ẹṣọ alaabo mi-in ti wa ni lagbegbe naa tẹlẹ ti wọn n ṣọ ibẹ, kawọn eeyan yee gbe ohun ti ko ṣẹlẹ kiri.

Alaye ileeṣẹ ọlọpaa Ogun

Lalẹ ọjọ Aje naa ni Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Oluseyi Babaseyi, fi atẹjade kan sita lori iṣẹlẹ yii.

Ninu atẹjade naa lo ti fidi iku ṣọja kan mulẹ, ati pe ikeji n gba itọju nileewosan.

DSP Babaseyi sọ pe ko sohun to jọ bandiiti tabi agbebọn ninu iṣẹlẹ ọhun, bi ko ṣe pe iṣẹlẹ iwa ọdaran lasan ni.

"Lẹyin iṣẹlẹ naa, ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ajọṣepọ awọn ologun, tete ko awọn ẹṣọ alaabo lọ si agbegbe naa, wọn si bẹrẹ iṣẹ lati mu awọn to lọwọ si i.

"Iwadii wa ko fi han pe iṣẹlẹ naa ni ohunkohun lati ṣe pẹlu bandiiti, bẹẹ ni iwadii ati iṣẹ ọpọlọ n lọ lọwọ."

O fi kun alaye naa pe ki araalu fi ọkan balẹ, ohun gbogbo wa labẹ akoso pẹlu bawọn ṣe ti ṣafikun agbofinro sagbegbe naa.