Wo ìlú tí o ti nílò láti fi BVN, NIN àti ìwé ọjọ́ ìbí rẹ̀ sílẹ̀ láti yá 'power bank' nítorí àìsí iná fún ọdún 18
Awọn olugbe ilu Ogbokoda, nipinlẹ Ondo ti ke gbajare si ijọba ipinlẹ naa, paapaa gomina Lucky Aiyedatiwa fun iranlọwọ, lori ina ọba ti ko si niluu naa fun ọpọ ọdun.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, fun nnkan bii ọdun mejidinlogun ni ilu ọhun, to jẹ olu ilu ijọba ibilẹ Ilaje, ko fi ni ina ọba.
Lẹyin nnkan bii ọdun mejidinlogun naa, wọn fun ni ina, amọ ina ọhun tun ti lọ lati nnkan bii oṣu mẹfa bayiii.
Awọn eeyan ilu naa lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba lasiko ti awọn akọroyin wa ṣabẹwo sibẹ.
"Lati 2005 ni a ko ti ni ina, ₦120,000 ni mo n na lori ẹrọ amunawa mi loṣu"
Ọdọbinrin kan to jẹ oniṣowo niluu Igbokoda, Akingboye Temiwunmi, sọ fun BBC pe lati ọdun 2005 loun ti bẹrẹ si n ṣakiyesi pe ko si ina niluu naa mọ.
O ni nigba to di 2024, wọn ni ina fun nnkan bii ọdun kan ti ina naa tun pada da gbere fun wọn.
Ọdọbinrin ọhun sọ pe "Ina ti ko si yii o ti ṣakoba fun emi ti mo jẹ oniṣowo.
"Ti mo ba fẹ fi epo sinu ẹrọ amunawa mi, maa lo epo lita marundinlogun, oun lo jẹ ki n lọ sọ ẹrọ amunawa naa di eyii to n gaasi.
"Gaasi bii ₦4,200 ni mo n ra loojọ, eyii ti apapọ rẹ n to ₦120,000 loṣu kan."
Temiwunmi sọ pe oun ko ri ere mọ lori owo ti oun n ṣe, o si jẹ ohun ibanujẹ pe ọmọ agbagbe Igbokoda naa ni gomina to wa lori oye amọ o kuna lati wa ojutu si iṣoro ina ọhun.
O pari ọrọ rẹ pe ọpọ araalu naa lo ti gba ilu mii lọ latari ina ti ko si.
Ọdun mejidinlogun ni a ko fi ni ina, ọmọ wa dẹ ni gomina - Ọba Odidiomo
Ọba ilu Igbokoda, Afolabi Oladimeji Odidiomo sọ fun wa pe iya ina n jẹ awọn gidi, koda, o ni epo bẹntiro bii ẹgbẹrun mẹẹdogun loun n ra lojojumọ lati ni ina mọju ni aafin oun.
O ni "A n bẹ ijọba, ki awa na tilẹ le gbe igbeaye to jọju to pọn eeyan le.
"Nigba wo ni a fẹ kuro ninu iṣẹ ati oṣi yii!"
"Ara nnkan ti awa naa ṣe gbadura niyẹn pe ki ọmọ wa di gomina... mo gbagbọ pe o ṣi maa ṣe.
"Nitori ti ko ba ṣe e itiju nla lo maa jẹ fun wa."






