Ilé ìgbìmọ̀ àṣofin Ghana buwọ́lu òfin tó kéde ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta fún ìbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ile igbimọ aṣofin orilẹeede Ghana ti buwọlu ofin to sọ ọ di eewọ ki eeyan maa ni ibalopọ akọsakọ tabi ibalopọ akọsakọ, LGBTQ+, ti ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o ṣe bẹẹ yoo si fi ẹwọn bii ọdun mẹta jura.
Ofin tuntun ọhun tun ke pe araalu lati fi to ijọba leti ti wọn ba kofiri ẹnikẹni to ba n ṣe nnkan naa ti wọn ti fofin de.
Labẹ ofin LGBTQ+ yii, obinrin ko gbọdọ ba obinrin bii tirẹ lopọ, ọkurin ko gbọdọ ba ọkunrin bii tirẹ lopọ, obinrin ko gbọdọ maa ba ọkunrin lopọ ko tun maa ba obinrin lopọ, bẹẹ ni ọkunrin to n ba obinrin lopọ ko gbọdọ tun maa ba ọkunrin lopọ, ọkunrin ko gbọdọ para rẹ da si obinrin bẹẹ ni obinrin ko gbọgọ pa ara rẹ da si ọkunrin.
Ṣaaju ni awọn olori ẹlẹsin ti kọkọ gbogun ti Aarẹ John Dramani Mahama lori ọrọ naa bo tilẹ jẹ pe o gbọdọ buwọlu ofin ọhun ko to pada si ofin ti wọn yoo maa lo.
Wayi o, ẹgbẹ awọn ajafẹtọọmọniyan kaakiri agbaye bii Human Rights Watch ni wọn ti koro oju si ofin naa.
Wọn ni ofin ọhun yoo fi ẹmi awọn to n ni ibalopọ abosabo ati akọsakọ sinu ewu.
Nigba to n ba awọn aṣofin ẹgbẹ rẹ sọrọ, ẹni to ṣagbatẹru ofin ọhun, John Ntim Fordjour sọ pe ofin naa yoo daabo bo idile ati aṣa ilẹ Ghana.
O ni ofin tuntun naa ran awọn ofin to ti wa nilẹ tẹlẹ lọwọ, yoo tun ran ijọba lọwọ lati gbogun ti awọn to n ni ibalopọ akọsakọ ati abosabo.
Aṣofin naa ni ẹnikẹni to ba n ṣatilẹyin fun awọn to n ṣe ibalopọ akọsakọ ati ibalopọ abosabo naa tun le ri ẹwọn he.
Wọn ni eyii yọ awọn agbẹjọro, akọroyin, atawọn oṣiṣẹ eto ilera ti wọn kọ iroyin nipa iwa naa tabi ti wọn n pese itọju fun awọn to n ṣe bẹẹ.
Ajọ Human Rights Watch ti kọwe si ijọba Ghana pe ko gbe ofin naa ti sẹgbẹ kan fun anfani ati ẹtọ araalu.


























