"Ẹ jọ̀ọ́ ẹ má jẹ́ kí wọ́n fi ẹ̀mí wa ṣòfò," àwọn olùkọ́ tí agbésùnmọ̀mí jígbé l'Ogbomoso rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba

Ibẹrubojo to gbalẹ nipinlẹ Oyo ko tii dopin bayii lẹyin ijinigbe awọn olukọ ati akẹkọọ to waye ni ijọba ibilẹ Oriire laarin oṣu yii.
Awọn agbesunmọmi to ṣiṣẹ naa tun ti gbe fidio mii jade, nibi ti ọkan lara awọn olukọ ọhun ti n rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Oyo pe ki wọn fun awọn ajinigbe naa ni nnkan ti wọn n bere fun ki awọn le gba itusilẹ.
Ile ẹkọ Community High School, ni ijọba ibilẹ Oriire ni wọn ti ji awọn eeyan ọhun gbe lọjọ karundinlogun, oṣu Karun un, ọdun 2026 ti a wa yii.
Fidio ọhun ti wọn ka silẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun un yii, to jẹ ayajọ ọjọ awọn ọmọde lagbaye tun ti n fa ori ayelujara ya bayii ni Naijiria.
Ninu fidio ọhun ni adari awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa, Arabinrin Alamu ti bẹbẹ lorukọ awọn eeyan naa ti wọn wa ni igbekun.
O ni "Ẹ jọwọ, a n bẹbẹ. Oni lo pe ọjọ kẹtala ti wọn ti ko wa, a ṣi wa ninu igbo titi di akoko yii.
"A n bẹ yin, Aarẹ Tinubu, gomina Seyi atawọn ọmọ Naijiria mii ki wọn dide fun iranlọwọ wa.
"Mo ke pe ajọ NUT, ANCOPSS, ki wọn ran wa lọwọ lati ba wọn sọrọ.
"A ko fẹ ki wọn fi agidi ṣe e, ohun ti a bere ni pe ki wọn ba wọn dunadura ki wọn le fi wa silẹ.
"A wa ninu otutu, a wa ninu ojo ati ninu oorun, awa atawọn ọmọ kekere ni a wa nibi. Ẹ jọwọ, a n bẹ yin, ẹ ma jẹ ki wọn fi aye wa ṣofo."
Ti ẹ ko ba gbagbe, awọn agbesunmọmi naa ti ṣekupa ọkan lara awọn eeyan naa ti wọn ji gbe lẹyin ti wọn ti kọkọ pa olukọ kan sile ẹkọ ọhun lasiko ikọli naa.
Fidio ọgbẹni Oyedokun ti wọn pa si akata awọn ajinigbe naa mu ọpọ ọmọ Naijiria da si ọrọ ọhun ti ọpọlọpọ ninu wọn si n bu ẹnu atẹ lu ijọba Bola Tinubu pe o ti kuna lori eto aabo.
Lọjọ Ẹti, ẹgbẹ awọn olukọ ṣe ifẹhonuhan niluu Ibadan lori iṣẹlẹ ọhun.



























