Wo kókó ohun mọ́kànlá tí Tinubu fi ránṣẹ́ sọ́mọ Náíjíríà lórí ààbò àti ọrọ̀ ajé láti sàmì ọdún kẹta rẹ̀ nípò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Ọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Karun-un ọdun 2026 yii lo pe ọdun mẹta ti Bola Tinubu ti wa nipo aarẹ orilẹede Naijiria.
Layajọ ọdun kẹta naa, Tinubu fi atẹjade kan sita lati ọwọ olukede rẹ, Bayo Onanuga.
Ninu atẹjade naa ni Aarẹ ti ni gbogbo awọn igbesẹ bii yiyọ owo iranwọ ori epo (fuel subsidy removal), riro owo naira lagbara lọja agbaye, gbigbe ogun ti ai si aabo ati bẹẹ bẹẹ lọ toun da wọle ti so eso rere fun orilẹede yii.
Wọnyi ni awọn ẹka gbogbo ti Aarẹ Tinubu ka pe oun ti fọwọ ba layajọ ọdun kẹta rẹ nipo olori orilẹede Naijiria
- Ilọsiwaju ati idagbasoke ọrọ aje han gedegbe:
Labala ọrọ aje ati idagbasoke, Aarẹ Tinubu sọ pe o ti han kedere pe ilọsiwaju ti ba ọrọ aje Naijiria, o si ti le figa gbaga pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ ju bo ṣe wa ni 2023 toun gbajọba lọ.
Aarẹ ṣalaye pe awọn to fẹ da ileeṣẹ silẹ ni Naijiria ti n ni igbagbọ ninu rẹ ju ti tẹlẹ lọ, ọjọ ipin idokowo n ṣe daadaa, bẹẹ ni awọn ileeṣẹ ti n jere ju ti tẹlẹ lọ ni Tinubu sọ.
- Atunṣe oju ọna
Awọn ọna marosẹ to din diẹ lẹgbẹrun mẹta (2700) ni iṣakoso Tinubu ti ṣe bo ṣe sọ.
Awọn ọna bii Lagos-Calabar Coastal Highway, Sokoto-Badagry Super Highway, Abuja-Kaduna-Zaria-Kano Road ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn eyi ti din wahala ọkọ ku bo ṣe wi, o si ti jẹ ki irinajo rọrun.
- Ẹka epo rọbi ati afẹfẹ idana:
Aarẹ Tinubu sọ pe atunto to ba ẹka yii ti mu ọpọlọpọ biliọnu dọla waye fun Naijiria, pẹlu awon ileeṣẹ elepo ilẹ okeere ti wọn ti kọyin si Naijiria tẹlẹ, ṣugbọn ti wọn ti pada wa nigba ti iṣakoso oun ti gbe igbesẹ
Aarẹ sọ pe eto onibiliọnu marun-un dola ($5 billion NLNG Train) ti n pari lọ, ti yoo si jẹ ki epo rọbi pọ si I, ti Naijiria yoo ri lo, ta pupọ soke okun bo ṣe sọ.
- Ina mọnamọna-
'Gbese ni ẹka ina mọnamọna wa n jẹ tẹlẹ, wọn ko si mọ ibi ti wọn dojukọ. Lonii, a ti n tako awọn iṣoro yẹn.
"A mọ pe ko si orilẹeede to le goke agba ninu okunkun, la ṣe n kowo le ilana ọna ọba ti yoo ran awọn ileeṣẹ ati okoowo lọwọ"
Bẹẹ ni Aarẹ Tinubu wi.
- Riro awọn ọmọ Naijiria lagbara lẹka ọgbin, eto ẹkọ ati ile gbigbe
Aarẹ Tinubu sọ pe ẹgbẹlẹgbẹ awọn agbẹ ni iṣakoso oun ti ro lagbara pẹlu nnkan ọgbin, ajilẹ, ẹrọ igbalode ati bi wọn yoo ṣe ko ire oko wọn de ọja lati ta.
- Eto ẹkọ:
Ilana ẹyawo ti wọn gbe kalẹ fun awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga (Nigerian Education Loan Fund) ni Aarẹ sọ pe o ti fun akẹkọọ to le ni 1.5million ni anfaani lati le kawe nile ẹkọ giga.
O ni owo to le ni ₦282 ni ijọba oun ti lo lati ri I pe ko si akẹkọọ to ni iṣoro lati wa nile ẹkọ giga nitori ai si owo.
- Ile gbigbe:
"Eto ireti ọtun nipa ile gbigbe (Renewed Hope Housing Programme), pẹlu ti ijọba apapọ Federal Housing Authority (FHA), n pese ile to le ni ẹgbẹrun mẹwaa (10,000 housing units) kaakiri ipinlẹ mẹrinla ati ilu Abuja ni Aarẹ Tinubu wi.
Ilera:
Ẹgbẹẹgbẹrun awọn ile iwosan ijọba alabọọde kaakiri ni wọn ti ro lagbara bi Tinubu ṣe ṣalaye, bẹẹ si ni eto ilera ma-da-mi-dofo naa tun wa fawọn ọmọ Naijiria to n ṣe alaini.
- Owo ounjẹ ati owo ọkọ:
Owo ounjẹ to lọ silẹ lati 2023 si 2024 yoo maa lọ bẹẹ bi Aarẹ ṣe wi, bẹẹ lo ni iṣẹ n lọ lati din owo ọkọ ku, bi awọn ọlọkọ ṣe n yi ọkọ to n lo epo pada si ti afẹfẹ CNG.
- Eto aabo ati iṣọkan orilẹede:
O ni iyatọ ti w ani awon agbegbe ati ilu kaakiri lẹka aabo, nitori awọn ologun ati ẹṣọ alaabo yoku ti ṣe afikun agbara wọn.
"Awọn ologun wa pẹlu awọn ẹṣọ alaabo to ku ti ṣe afikun agbara wọn lati koju awọn agbesunmọmi, ajinigbe, awọn ole to n ji epo ati gbogbo itakun iwa ọdaran.
- Ọrọ awọn ọdọ ati imọ ẹrọ:
Si awọn ọdọ, Aarẹ sọ pe oun gbagbọ ninu wọn, wọn ki I ṣe iṣoro fun orilẹede yii.
O fi kun un pe ijọba oun nawo si imọ ẹrọ ti yoo tun ro wọn lagbara si i.
- Afojusun ọjọ iwaju:
Aarẹ rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati fọwọsowọpọ pẹlu iṣakoso rẹ, lati ṣẹgun awọn iṣoro to wa nilẹ.
O ni ki wọn ma ṣe jẹ ki ọrọ ẹsin ati ẹya da orilẹede yii ru, ṣugbọn ki wọn maa ranti pe orilẹede to daa ko rọrun lati gbe kalẹ, afi bi kaluku ba sowopọ gbe ẹru ilu pẹlu ijọba.

























