Aṣọ oníbúrẹ́dì 500 tí mo wọ lọ síbi àmì ẹ̀yẹ AMVCA dá egbò sí mi lẹ́yìn, mú ẹ̀yìn ro mi, ó jẹ́ kí n fara ṣèṣe - Queen Mercy

Oríṣun àwòrán, Queen Mercy Atang/Instagram
Gbajumọ Queen Mercy Atang to kopa ninu eto Big Brother Naija ti sọ pe aṣọ ti wọn fi ẹẹdẹgbẹta burẹdi dara si lara, toun wọ lọ sibi ayẹyẹ ifunilamiẹyẹ ti AMVCA ṣagbatẹru rẹ niluu Eko, ti jẹ koun fara ṣeṣe.
Mercy sọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Pidgin.
Ọpọ eeyan bẹrẹ sii sọ nipa kaba ti wọn ni o fi ẹẹdẹgbẹta burẹdi sara rẹ, lẹyin ti o wọ lọ si ibi ayẹyẹ AMVCA naa.
Nigba to n sọrọ, Mercy ni oun kọ loun ran aṣọ naa, bi ko ṣe gbajumọ aranṣọ Toyin Lawani to jẹ ọga ileeṣẹ Tianah Empire.
''Lakọkọọ, emi kọ ni mo ran aṣọ naa, Tianah Empire, lo ran aṣọ ọhun.
Temi ni pe ki n kan gbe aṣọ naa, ki n dẹ wọ ọ,'' Mercy lo sọ bẹẹ.
Mercy fikun ọrọ rẹ pe aṣọ naa wuwo lara oun debi wi pe, o fẹẹ le kan igbaaroko oun.
O ni aṣọ naa jẹ ki oun ṣeṣe debi wi pe egbo wa lẹyin oun.
Mercy ni o pẹ ki Tianah to pari aṣọ naa.
''Aṣọ naa wuwo lara mi gan an, ti ẹ ba wo ẹyin mi, ẹ maa ri egbo nibẹ''
''Tianah kọkọ sọ fun mi pe ki n wa wọ aṣọ naa wo lati mọ ibi to ku si.
Amọ, aṣọ naa wuwo lara mi gan an, ti ẹ ba wo ẹyin mi, ẹ maa ri egbo nibẹ.
Burẹdi to wa lara aṣọ ọhun wuwo pupọ, ṣe lo dabi ki n maa sunkun nigba ti mo n wọ aṣọ naa.
Mo ni lati sọ fun wọn pe mo fẹ mi kanlẹ na nigba ti mo n wọ aṣọ naa,'' Mercy lo sọ bẹẹ.
O ni gbara toun kọkọ wọ aṣọ ọhun loun sare bọ ọ pada ti oun si bu sẹkun, ki o to tun wọ ọ pada.
Mercy to kopa ninu eto Big Brother Naija tẹlẹ ri ṣalaye pe oun pinnu lati ran aṣọ oniberẹdi ọhun lati le polowo okowo oun.
O ni oun ko pinnu tẹlẹ lati kopa ninu ayẹyẹ AMVCA tọdun yii tori bi oun ṣe kọju mọ iṣẹ okowo oun.
Mercy ni ẹni to ba oun ran aṣọ naa lo pada gba oun ni imọran lati lọ fun eto naa.
Atang sọ pe oun gan an ko mọ pe aṣọ naa le di nnkan tawọn eeyan yoo maa sọ nipa rẹ kaakiri lori itakun ayelujara.
O ni iyalẹnu lo jẹ foun wi pe oniruuru ileeṣẹ iroyin lo gbe iroyin jade lori aṣọ naa.


























