Ìfẹ̀hónúhàn bẹ́ sílẹ̀ ní France lẹ́yìn tí PSG gba ife ẹ̀yẹ Champions League, èèyàn 219 farapa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Apapọ eeyan 219 lo ti farapa bayii lẹyin ifẹhonuhna to bẹ silẹ ni France lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Paris Saint-Germain (PSG) gba ife ẹyẹ Champions League ti Arsenal si lulẹ lalẹ ana.
A gbọ pe eeyan mẹjọ lo wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun gẹgẹ bii ọrọ minisita fun ọrọ abẹle, Laurent Nuñez.
Ẹgbẹgbẹrun ọlọpaa lo jade lati lọ pana rogbodiyan naa, eyii to di irinkerindo oju popo lọwọ.
Marunlelaadọta lo farapa ninu awọn ọlọpaa ọhun.
Nuñez sọ pe eeyan 780 lawọn ti fi ṣikun ọlọpaa mu bayii lori rogbodiyan naa ti 450 eeyan si ti wa ninu atimọle.
Awọn alaṣẹ sọ pe wọn ri oku eeyan kan loju ọna ring road niluu Paris, eyii ti awọn oluwọde gbiyanju lati di lorumọju.
Ṣaaju ni ẹgbẹrun mẹfa eeyan ti kọkọ korajọ lati ṣe iwọde ajọyọ fun PSG ni gbagede ti Eiffel Tower wa.
Minisita fun ọrọ abẹle naa sọ pe awọn agbofinro ko ni faye idarudapọ kankan nilẹ naa.
O ni "A jẹ orilẹede to n faye gba ki gbogbo nnkan maa lọ letoleto, ofin wa faye gba ki awọn eeyan korajọ amọ a ko ni faye gba aṣeju."
Irufẹ iṣẹlẹ yii kan naa waye lọdun to kọja nigba ti rogbodiyan bẹ silẹ lasiko ti PSG n ṣajọyọ ife ẹyẹ ti wọn gba.
Lọdun yii, lẹyin ti PSG jawe olubori lẹyin pẹnariti pẹlu Arsenal ni ọgọrọ eeyan yabo gbagede Champs-Élysées.



























