Akẹ́kọ̀ọ́ ní òun gba máàkì 394 nínú 400 ní ìdánwò UTME, ṣe tòótọ́ọ́ ni àbí òfegè? Ohun tí a mọ̀ réè

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Idanwo UTME ti waye o si ti pari, amọ ọkan lara awọn esi idanwo naa lati ipinlẹ Cross River ti di ariwo lori ayelujara.

Akẹkọọ kan, Okon Winnifred Sampson, ni wọn lo gba 394 ninu irinwo (400) maaki, ninu idanwo Unified Tertiary Matriculation Examination ti ọdun 2026 yii.

Ori ẹka ayelujara X ni ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ @Onsogbu, gbe esi naa si pẹlu akọle to kọ si i pe:

"Okon Winnifred Sampson, ọdọmọbinrin kan lati ipinlẹ Cross River, ṣiṣẹ takuntakun ninu idanwo UTME, o gba ami 394 to tayọ ninu 400.

"Awọn esi idanwo rẹ ree: 96 ninu ede Gẹẹsi, 99; ninu Biology; 98 ninu Chemistry ati 99 ninu Physics… aṣeyọri to tayọ leyi loootọ. Mo nifẹẹ eyi."

Bẹẹ ni Onsogbu kọ sọju opo X nipa akẹkọọ naa ati esi to ni o gba ninu UTME 2026.

Ọrọ di ariyanjiyan lori ayelujara

Latigba ti esi idanwo ti iru rẹ fẹrẹ ma waye ri yii ti jade sori ayelujara ni awọn eeyan ti n gba ọrọ naa mọra wọn lọwọ.

Ọpọ eeyan lo n sọ pe ọmọ wo ni ori rẹ pe to bẹẹ to ṣe bẹbẹ bi eyi.

Wọn ni yoo wu awon lati ri i pe ootọ ni Winnifred gba gbogbo maaki JAMB tan bi eyi, to jẹ mẹfa pere lo ṣẹku ti yoo fi gba gbogbo irinwo maaki idanwo naa.

Bẹẹ naa si ni awọn kan n sọ pe awọn ko fi gbogbo ara gba esi naa gbọ.

Wọn ni o ṣee ṣe ko ni kọnu-n-kọhọ ninu bo ṣe ṣẹlẹ nigba kan ti akẹkọọbinrin kan, Mmesoma Ejikeme, ni 2023, ṣe ayederu esi idanwo UTME yii kan naa.

Mmesoma lati ipinlẹ Anambra sọ nigba naa pe oun gba 362, dipo 249 to gba gan-an.

Ajọ JAMB pada fi ododo to wa ninu esi idanwo naa han, Mmesoma si jade tọrọ aforiji lọwọ gbogbo eeyan to ti kọkọ purọ esi idanwo rẹ fun.

Eyi lo mu awọn mi-in ma gba esi tuntun to tun gbode yii gbọ.

JAMB ṣalaye ọrọ

Lati tan imọlẹ si ọrọ yii, Agbẹnusọ JAMB, Ọmọwe Fabian Benjamin, fi atẹjade kan sita lanaa ọjọ Aiku.

Ninu atẹjade naa ni JAMB ti ṣalaye pe ofege, irọ gbuu ni esi idanwo Okon Winifred to jade yii:

" Kinni kan ti wọn pe ni esi idanwo ni wọn n pin kiri lori ayelujara bayii, to n kede pe akẹkọọ kan gba 394 ninu idanwo UTME 2026, irọ gbuu ni.

"O ya ni lẹnu pe awọn eeyan to nimọ ni Naijriia n pin iru rẹ kiri."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa wi.

"Esi UTME ṣee wo lasan ni, a ko ṣe e fun pinpin kiri bayii"

Agbẹnusọ JAMB tẹsiwaju pe ọna ti awon gbe esi idanwo UTME gba ni pe ki awọn akẹkọọ wo o lasan, ki I ṣe pe ki wọn maa pin in kiri lori ayelujara.

O ni iwe ti won n pin kiri yii ki i ṣe otitọ rara, agbelẹrọ ni.

"Lakọkọ, ajọ yii ti sọ pe wiwo lasan ni esi idanwo wa fun.

"Ori ayederu ilana ni iwe ti won n pin kiri yii wa, eyi to to lati fi han pe ki I ṣe gidi.

"Ikeji ni pe bayii kọ ni JAMB ṣe n gbe nọmba iforukọsilẹ jade, ko si tẹle ilana '20269' to han lori rẹ yii, ofege ni."

Atẹjade naa tẹsiwaju pe awọn nnkan mi-in tun wa nibẹ ti ko jọra wọn, ti eeyan yoo ti mọ to ba wo o lẹẹkan pere pe ayederu ni.

Ajọ JAMB wa rọ araalu lati maa tẹle awon ohun to ba ti oju opo rẹ nikan wa, yala esi idanso tabi ikede.

Wọn ni ohun ti JAMB ba gbe jade ni ki wọn gbagbọ, ki I ṣe agbelẹrọ ori ayelujara.

Ni bayii, esi idanwo JAMB ko ṣee pin kiri bi won ṣe wi, wiwo lasan ni won le wo o loju opo to wa.