You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Agbébon ṣíná ìbọn bolẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́ tó ń gbá bọ́ọ̀lù lóríi pápá, 29 kú, ọ̀pọ̀ farapa
Awọn agbebọn to n pa ọpọ eeyan lẹkun pẹlu ikọlu tun ti ṣọṣẹ niluu meji nipinlẹ Adamawa, awọn ọdọ to n gba bọọlu lorii papa ni wọn da ibọn bo lọtẹ yii, eeyan mọkandinlọgbọn (29) ni wọn pa ninu wọn lọjọ Aiku.
Yato sawọn ti wọn yinbọn pa, ọpọ awọn ọdọ naa lo tun farapa.
Awọn ilu ti wọn dojukọ lọtẹ yii ni Guyaku ati Telabala, nijọba ibilẹ Gombi.
Ikọlu tuntun yii lo n waye lẹyin ọsẹ kan ti iru rẹ waye ni Mayo Ladde, nijọba ibilẹ Hong, Adamawa kan naa, nibi ti wọn ti sọ ina si awọn ile ijọsin kan.
Bawo ni ikọlu tuntun yii ṣe waye?
Gẹgẹ bi awọn to ṣoju wọn ṣe ṣalaye, lasiko ti ere bọọlu kan n lọ lọwọ, ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii ni awon agbebọn naa de.
Papa iṣere ile ẹkọ alakọọbẹrẹ kan ni awọn to n gba bọọlu ti n gba a ki wọn too maa gbọ iro ibọn lakọlakọ.
Eyi lo mu awon eeyan maa sa kiri lati da aabo bo ẹmi wọn lọwọ iku gbigbona.
Ṣugbọn bi wọn ṣe sa to, oku sun lọ jara.
Olugbe Guyaku kan ṣalaye pe lojiji ni awọn agbebọn naa de.
Wọn kọkọ pa eeyan meji ti wọn jokoo ninu ahere wọn, wọn si tun dana sun ahere naa.
O ni oun ko le sọ pato iye eeyan to ba ikọlu naa lọ.
Gomina Umaru Fintiri ṣabẹwo sibudo ikọlu, fidi ẹ mulẹ pe eeyan 29 lo ku
Lati ba awọn ti iṣẹlẹ aburu yii kan kẹdun, gomina ipinlẹ Adamawa; Umaru Fintiri, ṣabẹwo si ibudo ikọlu naa.
Bakan naa ni gomina sọ pe abẹwo oun tun wa fun lati mọ bi nnkan ṣe n lọ si bayii.
Gomina Fintiri ṣapejuwe iṣẹlẹ naa bi eyi to ba ni lọkan jẹ, to n waye laipẹ ti ikọlu kan ṣẹlẹ.
Fintiri sọ pe awon ọdaran Boko Haram lo n ṣekọlu yii.
O wa fi awon olugbe agbegbe naa lọkan balẹ, o ni iṣẹ n lọ pẹrẹwu lati so okun aabo le, oun yoo si ri I pe aabo wa fun wọn.
Gomina yii fidi ẹ mulẹ, pe eeyan to to 29 lo ku ninu ikọlu yii, o ni ohun to buru jai ni.
IS kede pe awọn lawọn wa nidii ikọlu to pa eeyan 29
Bi idaamu ti ikọlu yii da silẹ ṣe n lọ lọwọ, ti ọpọ eeyan si n ke irora, ẹgbẹ IS ti sọ pe awọn lawọn wa nidii ikọlu naa.
Islamic State group (IS) to kede eyi ko sọ idi ti wọn fi gbe igbesẹ aburu naa.
Ọpọ idile lo ti fi ile wọn silẹ lasiko yii ni Guyaku, latari aibalẹ ọkan.
Agbegbe yii paala pẹlu orilẹede Cameroon, o si ti koju ikọlu lọwọ awọn agbesunmọmi abẹle ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ IS.
Nibẹrẹ oṣu yii, eeyan to to irinwo (400) ni wọn dajọ fun pe wọn ni ajọṣe pẹlu ikọ Boko Haram, ati igun keji rẹ ti I ṣe Islamic State West Africa Province (ISWAP).
Fídíò tó ṣàfihàn ibùba ajínigbé ní ìpínlẹ̀ Ogun - Ohun tí a mọ̀ rèé
Fidio kan ti jade sori ayelujara, to n ṣafihan ibi kan ti wọn pe ni ibuba ajinigbe nipinlẹ Ogun.
Ninu fidio ọhun ni ọkunrin kan ti ni awon eeyan nilo lati ṣọra nipinlẹ Ogun, o ni nitori ipinlẹ Ogun ni ibuba awon ajinigbe ti fidio naa ṣafihan wa.
Ẹni to n sọrọ ninu fidio ọhun kọkọ n sọ ede Igbo, nigba to si ya lo yi i si ede Gẹẹsi.
Fidio naa tun ṣafihan apa kan inu igbo naa, nibi ti ẹnikan to wọṣo bii ti ologun to si gbe ibọn dani ti n gbiyanju lati yinbọn soke.
Apa kan fidio naa tun ṣafihan awon kan ti wọn ni ajinigbe lo gbe won pamọ sinu igbo ọhun.
Eredi fidio naa bi won ṣe ṣalaye ninu rẹ, ni pe ki awon araalu ṣọra pupọ, nitori awon ajinigbe yii ni ibuba kaakiri awon igbo ipinlẹ Naijiria.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọrọ lori fidio naa
Lọjọ Aiku, ọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹrin 2026, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi atẹjade kan sita lati ṣalaye lori fidio naa.
DSP Oluseyi Babaseyi, Alukoro ọlọpaa Ogun to fi atẹjade naa sita lorukọ Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, Bode Ojajuni, ṣalaye pe:
"Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun n fi asiko yii sọ fun yin pe ko sohun to jọ ohun to n ṣẹlẹ ninu fidio to gba ori ayelujara kan .
"Fidio naa jẹ irọ, aṣinilọna, bẹẹ ni ko wa lati ipinlẹ Ogun tabi apa ibi kankan ni Naijiria."
Atẹjade ọlọpaa naa sọ pe iwadii fi han pe orilẹede Kenya ni won ti ya fidio naa, lasiko ti won n mu awon kan to n ji ẹran agbo gbe.
Wọn fi kun un pe ikọ kan, General Service Unit (GSU) lo ya fidio naa pẹlu ẹrọ drone wọn.
Alukoro ọlọpaa sọ pe iwadii tun fi han, pe ọdun 2022 ni fidio naa kọkọ jade sori ayelujara.
O ni latigba naa ni won si ti n gbe e jade nigba to ba wu won pẹlu irọ, lati ko awon eeyan ilu laya soke nipa ipo aabo nipinlẹ Ogun.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Bode Ojajuni, naa koro oju si ohun to wa ninu fidio naa, o si rọ awọn eeyan lapapọ lati ma ṣe gba a gbọ rara.
Ojajuni fi da awon eeyan ipinlẹ Ogun loju, pe ileeṣẹ ọlọpaa Ogun ko sinmi nipa ki alaafia ati aabo wa fun ẹmi ati dukia awon olugbe ibẹ.
Kọmandi ọlọpaa Ogun wa rọ awọn eeyan pata lati ma ṣe pin fidio naa kiri lori ayelujara mọ, tabi eyikeyi iru rẹ ti wọn ko le fidi rẹ mulẹ, ki won ma baa lọwọ si dida omi alaafia ilu ru.
Bi wọn ba ri ohun ifura to le koba aabo, ileeṣẹ ọlọpaa Ogun rọ wọn lati tete fi to agbofinro leti.
Amọ pinpin ohun ti ko ṣẹlẹ kiri tabi gbigbe iroyin atako kiri ni ko si aaye fun bi wọn ṣe sọ.