Kí ló ṣẹlẹ̀ tí ọ̀gá ọlọ́pàá 167 fi ń sọ tẹnu wọn níwájú ìgbìmọ̀ tó ń ṣèbáwí ọlọ́pàá? Àlàyé rèé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Igbimọ FDC to n ṣẹbawi fawọn ọlọpaa to ba tasẹ agẹrẹ lẹnu iṣẹ ti bẹrẹ ifọrọwanilẹnuwo fun ọga ọlọpaa mẹtadinlaadọsan (167) ni olu ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria to wa niluu Abuja.

Awọn ọga ọlọpaa naa ni a gbọ pe wọn ti fi oniruuru ẹsun kan wọn.

Lara ẹsun ti wọn fi kan wọn ni aṣilo ipo ati ṣiṣe ohun ti ko tọ lẹnu iṣẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Anthony Placid, lo fọrọ yii lede loju opo ayelujara rẹ.

Ọgbẹni Placid ṣalaye ninu atẹjade to fi sita loju opo ileeṣẹ ọlọpaa to wa lori X pe ''ifọrọwanilẹnuwo naa ti bẹrẹ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa l'Abuja.

Iwadii yii wa lara afojusun ileeṣẹ ọlọpaa lati fọ ileeṣẹ naa mọ fun anfaani gbogbo ọmọ Naijiria

Igbimọ FDC lo maa n ri si ibawi awọn ọlọpaa ti ipo wọn ba ti de ASP lọ soke to ba huwa kan tabi omiran to lodi sofin lẹnu iṣẹ.

Igbimọ yii maa n wo oniruuru ẹsun ti wọn ba fi kan awọn ọga ọlọpaa yii fini fini ni ibamu pẹlu ofin.

Lẹyin naa ni wọn yoo gba ajọ PSC to n ṣakoso ileeṣẹ ọlọpaa ni imọran lori iru ijiya ti wọn le fun wọn.''

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ọga agba ọlọpaa Naijiria, IGP Olatunji Disu, ti sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni beṣu bẹgba lati ri pe awọn ọlọpaa ṣiṣẹ wọn lai fi ọwọ pa ida ofin loju.

Ọgbẹni Placid fikun ọrọ rẹ pe ko si ọlọpaa to ba jẹbi ẹsun ti wọn kan an ti ko ni foju wina ofin.

''Ọga ọlọpaa ti sọ pe ifọrọiwanilẹnuwo awọn ọga ọlọpaa to n lọ lọwọ jẹ ọna kan lati jẹ ki araalu ni igboya si i ninu awọn ọlọpaa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣetan lati ri pe awọn ọlọpaa ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ lai tasẹ agẹrẹ si ofin,'' Placid lo sọ bẹẹ.