You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àlàyé rèé lórí ìdí tí ìjọba ṣe yọ ẹ̀sùn fifi owó ṣèrànwọ́ fún ìgbẹ́sùnmọ̀mí kúrò nínú ẹjọ́ ti Malami ń jẹ́
Bi a ba ni eegun baba ẹni yoo jo, bi ko ba si wa jo mọ, ẹnikan ko le muni si i.
Eyi lo n waye bayii bi ijọba orilẹede Naijiria ṣe yọ ẹsun fifi owo ran igbesunmọmi lọwọ kuro lara ẹjọ ti wọn fi kan Abubakar Malami, Minisita eto idajọ nigba kan.
Tẹ o ba gbagbe, Malami ati ọmọ rẹ; Abdul Aziz ni wọn jọ n jẹjọ to ni i ṣe pẹlu nini nnkan ija ogun lọwọ lọna aitọ, ati ti pe wọn n ran awọn agbesunmọmi lọwọ.
Ki lo de ti wọn yọ ẹsun yii kuro fun Malami atọmọ rẹ?
L'Ọjọru ana ti i ṣe ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹrin, ọdun 2026 ni agbefọba Akinlolu Kehinde, fi to ile ẹjọ giga ilu Abuja leti, pe ijọba Naijiria ti yọ ẹsun fifi owo ran igbesunmọmi lọwọ kuro fawọn olujẹjọ mejeeji.
Alaye ti Akinlolu ṣe ni pe ijọba ti ṣatunṣe si awọn ẹjọ ti Malami n jẹ, fun idi eyi, awọn yọ ẹsun atijọ naa kuro.
O fi kun un pe ijọba ti sẹ atunto awọn ẹsun tuntun fun awọn olujẹjọ naa ti wọn yoo jẹjọ rẹ.
Ni bayii, ẹsun pe wọn ba nnkan ija ogun lakata wọn ni wọn yoo jẹ.
Agbejọro fun Malami, Shaibu Aruwa, naa fidi ẹ mulẹ fun kootu.
O ni oun ti ri ẹ̀dà iwe ipẹjọ tuntun naa, oun si fara mọ ọn.
Ki ni wọn ni wọn ba nilee Malami nigba naa?
Ibọn kan ati ọta ibọn mẹrindinlogun ti wọn ko ti i yin, ti wọn ni wọn ba nilee Abubakar Malami ni Birnin Kebbi, pẹlu ọta ibọn mẹtadinlọgbọn mi-in lo fa a ti wọn fi fẹsun nini nnkan ija ogun lọna aitọ kan wọn lakọọkọ.
Ijọba sọ pe imurasilẹ lati ran igbesunmọmi lọwọ ni.
Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun aṣilo agbara kan Abubakar Malami, pe o kọ lati fẹsun kan awon to n kowo silẹ fun iranlọwọ awon agbesunmọmi, nigba to wa nipo Minisita eto idajọ lorilẹede yii.
Ijọba fẹsun kan an pe bi iwe igbẹjọ awon eeyan naa ṣe de ọfiisi Malami to nigba to wa nipo agbara, ko fi ofin gbe awon to yẹ ko fi gbe lori igbesunmọmi.
Eyi ni wọn ka si pe wọn n ran awon agbesunmọmi lọwọ, to si tako abala, 26 (2) ofin igbesunmọmi ti wọn gbe kalẹ ni 2022.
Ṣaa, Adajọ Joyce Abdulmalik fi aaye silẹ fun wọn lati maa lo anfaani beeli 500m ẹnikọọkan wọn lọ.
Pẹlu iwe irinna wọn ti ile ẹjọ ti gba silẹ.
O sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un ọdun 2026.
Malami, iyawo atọmọ rẹ ṣi n jẹjọ pẹlu EFCC
Tẹ o ba gbagbe, awọn ẹsun ajẹbanu, kiko dukia olowo nla jọ lọna eru lasiko to n ṣe olootu idajọ atawọn ẹsun mi-in ṣi wa ti Malami, ọmọ ati iyawo rẹ n jẹ.
Ajọ EFCC to n ri si ṣiṣe owo ilu mọkumọku lo pe wọn lẹjọ naa.
Ile ẹjọ giga ilu Abuja ni wọn ti n gbọ ẹjọ yii naa, Adajọ Emeka Nwite lo si n dari igbẹjọ ọhun.
Malami ati idile rẹ sọ pe awọn ko jẹbi awọn ẹsun wọnyi, ile ẹjọ si fun wọn ni beeli pẹlu ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira (500 million naira).
Pẹlu oniduuro meji ti wọn ni dukia ni Asokoro tabi agbegbe Maitama, l'Abuja.