Ibà ọ̀rẹ̀rẹ̀ (Lassa Fever) wọ ìpínlẹ̀ Oyo, wo ọ̀nà márùn-ún láti dènà rẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba ipinlẹ Oyo ti kede pe eeyan kan ti ku nitori arun iba Ọrẹrẹ ti a tun mọ si Lassa Fever.

Obinrin naa,ẹni ọdun mẹrinlelogoji, ni wọn lo jade laye nile iwosan UCH tori arun iba ọrẹrẹ naa.

Atẹjade kan ti Kọmisana feto ilera nipinlẹ Oyo, Dokita Jesuserimi Ajetunmobi fisita lo kede bẹẹ.

Ajetunmobi ni ijọba ipinlẹ Oyo se agbende ikọ eleto ilera kan, Incident Management System (IMS) ti yoo maa sa ipa lati dena itankalẹ Iba ọrẹrẹ naa.

Bakan naa lo ni ikọ eleto ilera ọhun tun ti n sapa lati sawari awọn eeyan to ni ibasepọ pẹlu obinrin alarun Iba Ọrẹrẹ to ku naa, ki wọn le sayẹwo fun wọn boya wọn ti ni arun naa.

BBC News Yoruba wa se akojọpọ iroyin nipa arun iba ọrẹrẹ eyi to nii se pẹlu awọn apẹrẹ ti arun naa le mu wa, itọju rẹ ati ipa rẹ lori ilera ẹda.

Ki lo n fa arun Iba Ọ̀rẹ̀rẹ̀?

Iba Lassa jẹ arun kan to maa n waye lati ara kokoro aifojuri ti a mọ si Virus.

Kokoro yii maa n de ara eeyan lati ara ounjẹ tabi nnkan eelo ti ekute to ni kokoro lara naa ba tọ si, tabi to ṣe igbọnsẹ si .

Ajọ eleto ilera agbaye, World Health Organisation (WHO), sọ ọ di mimọ pe iba Lassa pọ ni apa Iwọ Oorun Africa, paapaa ni Naijiria, Liberia, Mali, Togo, Guinea, Ghana, Sierra Leone ati Benin.

Bakan naa, iba Lassa yii tun maa n tàn lati ara ẹnikan si ikeji, nibi ti ko ba ti si idaboobo ati itọju to peye.

Gẹgẹ bi NCDC ṣe wi, arun Lassa n lagbara si i , pẹlu bo ṣe jẹ pe onka awọn to n kọlu n pọ si i.

Nipa iru awọn eeyan ti iba yii saaba maa n kọlu, ajọ naa sọ pe awọn eeyan ti ọjọ ori wọn wa laaarin ọdun mọkanlelọgbọn (31) si ogoji ọdun (40), takọ-tabo ni wọn ni o si le mu.

Bawo ni o se le mọ pe o ni arun iba ọrẹrẹ?

  • Ko maa rẹ eeyan latinu wa
  • Ki ọna ọfun maa dun eeyan
  • Ki eeyan maa ya igbẹ leralera
  • Ki ẹjẹ maa da lati imu, erigi
  • Ki ẹjẹ maa wa ninu itọ eeyan tabi loju abẹrẹ
  • Ki igba aya maa ro eeyan
  • Ki eeyan ni irora lati mi

Ọna marun un lati dèna Lassa Fever

Aisan iba ọrẹrẹ jẹ aisan ti ko ni ẹrọ, amọ ti o ni itọju ti ẹni to ba ni aisan naa ba tete lọ si ile iwosan lati fi ara rẹ han.

Ọna ti a le gba dina aisan ti o wa lati ara ẹran igbẹ papa eku inu ile:

  • Ẹ sọra fun jijẹ eku tabi ẹran igbẹ.
  • Ẹ ma se sa garri sita gbangba.
  • Ẹ pa awọn eku to ba wa ni inu ile ati agbegbe yin.
  • Ẹ pa oko tabi koriko ti o ba wa ni agbeegbe, ki ayika naa le wa ni mimo ni gbogbo igba.
  • Awọn ohun elo ounjẹ gbọdọ wa ni inu ike ti ẹkutele ko lee de bẹ.
  • Ẹ sọra lati farakan ẹni ti o ma ni aisan iba ti kosi tete lọ.
  • Awon dokita tabi osisẹ ile iwosan gbọdọ sọra gidigidi, ki wọn si lo ibọwo tabi iboju ti wọn ba n toju ẹni to n se aisan.