Ẹ gbà wá o, àwọn agbébọn ti fẹ́ pa wá tán - Àwọn ọ̀dọ́ Gúúsù Kwara figbeta

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn ọdọ apa Guusu ipinlẹ Kwara (Kwara South) ti rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ Naijiria, ti ipinlẹ ati ti ibilẹ lati jọwọ dasi ọrọ eto aabo lọdọ awọn.

Awọn ọdọ naa sọ eyi di mimọ nibi iwọde ifẹhonuhan alaafia ti wọn se ni ilu Ajase-Ipo, nijọba ibilẹ Irepodun, lanaa, ọjọ kẹrinlelogun osu Kẹrin ọdun 2026 yii.

Wọn ni awọn agbebọn ti fẹrẹ pa awọn tan, o si gba ki ijọba tete gbe igbesẹ ki ilẹ awọn ma baa di ahoro.

Nibi ti ọrọ naa ka wọn lara de, awọn ọdọ Guusu Kwara ti wọn n gbe niluu Eko, Ilorin ati awọn ilu mi-in tẹ ọkọ leti wa silẹ lati dara pọ mọ ifẹhonuhan yii.

"Yorùbá ni wá, a fẹ́ kí ìjọba lé gbogbo àwọn ẹ̀yàkẹyà kúrò lórí ilẹ̀ wa"

Nibi ifẹhonuhan naa ni wọn ti ṣalaye pe ẹya Yoruba ni gbogbo awọn, awọn si fẹ kijọba bawọn le awọn ẹya ti wọn n yọ awọn lẹnu jinna rere si awọn ilu awọn.

Awọn olufẹhonuhan naa sọ pe ojojumọ ni wọn n ji awọn gbe ti wọn si n pa awọn, eyi ni wọn ni o fi pọn dandan fun ijọba bayii lati gbe igbesẹ, ki wọn si le gbogbo awọn ajinigbe wọn yii kuro lori ilẹ awọn.

Ọkan lara awọn olufẹhonuhan naa, Afeez Alẹsinlọyẹ, sọ pe iṣẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan ni Guusu Kwara ti kuro ni ohun ti eeyan le fi ọwọ kekere mu.

Alesinloye sọ pe: "Awọn ọba wa n sun, wọn n hanrun, ṣugbọn awọn ọmọ ilu o le sun ile mọ.

"Gbogbo awọn akọni ti a gbojule ni ilu kọọkan ni wọn n pa lọkọọkan ti a ko si ri nnkankan ṣe si i.

"Igba ti wọn n pa awọn akọni ti ilu gboju le, ki waa ni ireti awọn araalu.?

"A fẹ ki aarẹ Tinubu dide si ọrọ wa tori Yoruba lawọn naa, ko si yẹ ki ọmọ Yoruba maa jiya loju wọn.

"Ni ijẹta ni wọn tun ya wọ ilu mẹta, Alabe, Babanla ati Kajola, eeyan mọkanla ni wọn ji gbe lọ ti agbara wa o si dawọn duro.

"Wọn n gbe ọba, wọn n gbe ijoye, wọn gbe araalu, a fẹ ki ìjọba Kwara ati ijọba apaapọ wa gba wa o."

Ìlú tí àwọn agbébọn ti ṣọṣẹ́ lé ní ogún

Ẹlomiran to tun kin ọrọ yii lẹyin ni Ọgbẹni Muritala Ishola, ẹni to ṣalaye pe ijọba ibilẹ meje lo wa ni Guusu Kwara, awọn ilu ti awọn onisẹ ibi yii ti fọwọ ba nibẹ le ni ogun.

"Awọn inaa bo ṣe ka wọn ni :

Oreke, Babanla, Oke-Ode, Bayagan Ora, Adanla, Memudu, Shagbe, Omugo Alosoro, Alawon, Iganmu, Al-heri, Budesu Busewa, Ologomo, Agbeku, Agunjin, Abayan Idofin Odo Ase, Owa Onire, ati Aadin Ileire.

Àwọn ìlú tí wọ́n ti dahoro

Bakan naa lo darukọ awọn ilu kan pe wọn ti di ahoro bayii. Awọn ilu naa bi Ishola ṣe pe wọn ni:

Omugo, Ajegunlẹ, Ahun, Oyatedo, Oke-Oyan.

O ni wọn ti di ahoro bayii latari ijinigbe to ti di lemọlemọ nibẹ.

"Wọn n gbe wa láya, gbe wa lọkọ, wọn si n gbe wa lọmọ lọ. A rọ ijọba ki wọn ma ṣe wo wa niran.

"Ni bii ọjọ meji sẹyin, wọn ya wọ ilu Olayinka, wọn si gbe Ọba ilu naa ati awọn mi-in lọ.

"O se pataki fun ijọba ki wọn tete gbe igbesẹ lori ọrọ yii, o to gẹẹ."