You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gbọin-gbọin ni a wà lẹ́yìn Makinde bí òkè, àhesọ ọ̀rọ̀ lásán n'ìròyìn tó ní a fẹ́ yọ ọ́ nípò – Ilé Aṣòfin Oyo
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti sọ pe gbọin-gbọin lawọn wa lẹyin Gomina Seyi Makinde ipinlẹ naa.
Adari ile, Họnọrebu Adebo Ogundoyin, lo fọrọ yii lede loju opo X rẹ.
Abenugan ile sọrọ yii lẹyin iroyin kan to ti tan kalẹ ṣaaju wi pe ile fẹ yọ Makinde nipo.
Amọ, Ogundoyin ti sọ pe gbogbo ile lo ni igboya ati igbẹkẹle ninu gomina ipinlẹ Oyo lati maa ba iṣẹ rẹ lọ.
Eyi lo mu ki gbogbo ọmọ ile dibo wi pe awọn wa lẹyin Makinde pẹlu eto iṣejọba rẹ.
Adari ẹgbẹ oṣelu to pọju nile, Họnọrebu Sanjo Adedoyin, to n ṣoju ẹkun Guusu Ogbomoso lo dabaa wi pe ki ile dibo lati kede atilẹyin wọn fun Makinde.
Họnọrebu Adedoyin naa sọ pe iroyin tawọn eeyan kan n gbe kiri pe ile fẹ yọ gomina ipinlẹ Oyo ipo ko lẹsẹ nlẹ rara.
O ni irọ ni iroyin naa, ati wi pe iroyin ọhun ni ọwọ oṣelu ninu.
Adedoyin ni gbogbo ọmọ ile aṣofin ipinlẹ Oyo lo wa ni iṣọkan ti wọn si n ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi ofin ṣe la a kalẹ.
O ni ko si igba kankan ti ile jiroro lori a ti yọ Gomina Makinde nipo.
Họnorebu Adedoyin ni ọta ipinlẹ Oyo lawọn eeyan to n gbe iroyin kiri pe ile fẹ yọ Makinde nipo.
O wa dupẹ lọwọ awọn akẹgbẹ rẹ lori ''bi wọn o ṣe gba ki ero ibi awọn eeyan kan ti wọn fẹ ba iṣẹ ribi ribi ti ijọba Makinde n ṣe jẹ wa si imuṣẹ.''
''Ko si iyapa ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo, a n ṣisẹ wa bi iṣẹ lati ri pe awọn araalu jẹ anfaani ijọba awarawa.
Ahẹsọ ọrọ lasan an lawọn eeyan kan n gbe kiri, a ko si fẹ ki ẹnikẹni tẹti si wọn.''
''Alabaṣiṣẹpọ lawa aṣofin jẹ pẹlu gomina, a o si jọ pari ijọba yii ni''
Igbakeji adari ile, Họnọrebu Mohammed Fadeyi, to kin aba naa lẹyin sọ pe iṣọkan ni ile aṣofin Oyo wa.
Gbogbo ile tun gboṣuba kare fun adari ile fun bi o ti n dari ile naa lọna to n mu ilọsiwaju ba ipinlẹ Oyo.
Wọn ni ile ti ṣe oniruuru aṣeyọri labẹ aṣẹ Họnọrebu Ogundoyin to jẹ abẹnugan ile.
Gbogbo ọmọ ile aṣofin wa kede atilẹyin wọn fun Gomina Makinde ati adari ile Ogundoyin.
Nigba to n sọrọ, adari ile ni ''mo fẹ fi da gbogbo eeyan loju pe iṣọkan wa laarin gbogbo ọmo ile aṣofin ipinlẹ Oyo.
Eyi si yatọ si ahesọ ọrọ tawọn eeyan kan n gbe kiri wi pe iyapa wa laarin awọn aṣofin.
Nnkan ti mo fẹ kawọn oloṣelu mọ ni pe ko si nnkan ti wọn le ṣe si awọn aṣoju tawọn araalu ba ti yan.
A ti sọ asọyepọ gẹgẹ bi ile, a si ni igboya ninu iṣejọba Gomina Makinde.
Alabaṣiṣẹpọ lawa aṣofin jẹ pẹlu gomina, a o si jọ pari ijọba yii ni.''
Lẹyin tawọn aṣofin sọrọ naa tan ni wọn sun ijokoo ile si ọjọ kejila oṣu Karun un ọdun yii.