Ohun tó fàá tí Ààrẹ Kenya fi sọ pé ọmọ Naijiria ò lè sọ èdè òyìnbó dáadáa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọrọ ti Aarẹ William Ruto orilẹede Kenya sọ pe awọn ọmọ Naijiria ko le sọ ede oyinbo daadaa ti fa awuyewuye lori itakun ayelujara.

Nigba to n bawọn ọmọ orilẹede Kenya to n gbe lorilẹede Italy sọrọ lọjọ Aje, Ruto sọ pe ''ti ẹ ba tẹti si ọmọ Naijiria to n sọ ede Gẹẹsi, o ṣee ṣe ki ẹ ma gbọ nnkan ti wọn n sọ.

Ẹ maa nilo ẹni to le ṣe ongbufọ lati tumọ nnkan ti ọmọ Naijiria n sọ ni ede Gẹẹsi.

Amọ, awọn ọmọ Kenya wa lara awọn ọmọ orilẹede to n sọ ede Gẹẹsi to dantọ julọ lagbaaye.''

Ṣugbọn ọrọ yii ti bẹyin yọ tori ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria atawọn ọmọ orilẹede Afirika mii ni wọn ti bu ẹnu ẹtẹ lu Ruto wi pe o n tabuku orilẹede ilẹ Afirika mii.

Akọroyin ọmọ orilẹede Zimbabwe kan, Hopewell Chin'ono, sọ pe ''ede awọn ijọba amunisin ni ede Gẹẹsi eyi ti ko tumọ si pe eeyan ni ọpọlọ pipe tabi idagbasoke.''

Ilẹ Gẹẹsi lo ko orilẹede Naijiria ati Kenya lẹru, ede Gẹẹsi si lawọn mejeeji n sọ gẹgẹ bi ede to so gbogbo eeyan awọn orilẹede naa pọ.

Amọ, iro ede Gẹẹsi Naijiria ati Kenya yatọ si ara wọn.

Iyatọ to wa laarin bi orilẹede mejeeji sẹ n sọ ede oyinbo ko ṣẹyin ipa ti ede abinibi ilẹ onikaluku ni lori ede oyinbo ti wọn n sọ eyi ti ijọba amunisin mu wa.

Ninu ọrọ rẹ, Ruto ni eto ẹkọ Kenya to dara lo mu ki ọ rọrun fawọn ọmọ orilẹede naa lati le maa sọ ede Gẹẹsi to dantọ.

''Eto ẹkọ Kenya dara gan an. Sisọ ede Gẹẹsi wa si dantọ.

A wa lara awọn orilẹede to n sọ ede Gẹẹsi to dantọ julọ lagbaaye.

Bakan naa ni a ni awọn akọṣẹmọṣẹ ti wọn gbọrẹgẹjigẹ kaakiri agbaaye,'' Ruto lo sọ bẹẹ.

Awọn ọmọ Naijiria n gbadun ju awọn eeyan Kenya, bo tilẹ jẹ pe epo bẹntiroolu ti gbowo lori - Tinubu

Sẹnẹtọ Shehu Sani ni Ruto n tabuku ede Gẹẹsi orilẹede ti Ọjọgbọn Wole Soyinka to gba ami ẹyẹ to ga julọ ninu imọ Litiresọ lagbaaye ati orilẹede ti agbaọjẹ onkọwe Chinu Achebe ati gbajuagbaja onkọwe Chimamanda Adiche ti wa.

Awọn eeyan mii lori itakun ayelujara naa sọ fun Ruto pe ko lọ wa ojutuu sawọn iṣoro to n koju awọn eeyan Kenya.

Loorekoore ni ariyanjiyan maa n waye lori ayelujara laarin awọn eeyan Kenya ati Naijiria.

Ni ọpọ igba ni nnkan to maa n fa iwọ-o-ju-mi emi-o ju-ọ maa n da lori eto ẹkọ, ounjẹ, orin ati ere idaraya.

Ṣaaju loṣu Kẹrin yii lawọn eeyan Kenya ti bu ẹnu ẹtẹ lu Aarẹ Bola Tinubu lẹyin to sọ pe awọn ọmọ Naijiria n gbadun ju awọn eeyan Kenya atawọn orilẹede Afirika mii lọ, bo tilẹ jẹ pe owo epo ti wọn sii.

Bo tilẹ jẹ wi pe Ruto ko sọ pe ọrọ ti Tinubu sọ ṣaaju loun fesi si, ọpọ lo gbagbọ pe Tinubu ni Ruto n baa wi.

Aarẹ Kenya ko tun tii sọ nnkankan le ọrọ to sọ naa, amọ, awọn ọmọ Kenya kan ti ṣatilẹyin fun aarẹ wọn pe awọn eeyan lo ṣi i gbọ tori awada lo n ṣe.

Naijiria ni awọn to n sọ ede oyinbo ti pọ julọ nilẹ Afirika.