Ìjọba àpapọ̀ fẹ́ yá $516m láti ṣe ọ̀nà láti Sokoto sí Badagry

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Bola Tinubu ti ke si ile igbimọ aṣofin Naijiria ki won buwọlu owo ti iye rẹ to $516,333,070 ti oun fẹ ya lati gbọ bukata oju ọna marosẹ Sokoto si Badagry to fẹ ṣe.

Ọrọ naa lo wa ninu lẹta kan ti Aarẹ igbimọ aṣofin naa, Godswill Akpabio ka niwaju awọn ọmọ ile.

Gẹgẹ bi lẹta naa ṣe sọ, owo ti ijọba fẹ yan ọhun ni wọn reti lati ile ifowopamọ Deutsche, eyii ti wọn yoo fi ṣe abala 1, 1A ati 1B oju ọna naa ti yoo ni ẹgbẹrun kan kilomita

Anfani ti ọna naa yoo ṣe fun ọrọ aje Naijiria

Ijọba sọ pe ọna naa ni yoo so agbegba Àríwá-Ìwọ̀-Oòrùn pọ mọ Gúúsù-Ìwọ̀ Oòrùn Naijiria.

Ijọba apapọ sọ pe ọju ọna marosẹ ọhun ni yoo jẹ ọkan lara awọn iṣẹ to ṣe gboogi lara awọn akanṣẹ ijọba Tinubu labẹ asia Renewed Hope.

Nigba to n ṣalaye bi wọn yo ṣe na owo naa, Aarẹ sọ pe ọna ọhun yoo la ipinlẹ Sokoto, Kebbi, Niger, Kwara, Oyo, Ogun, ati Eko kọja.

Ijọba ni ọna ọhun ti iwọn rẹ to "ẹgbẹrun kan kilomita yoo so ipinlẹ Sokoto, Kebbi, Niger, Kwara, Oyo, Ogun, ati Eko pọ mọ ara wọn, bẹrẹ lati Illela titi de Badagry."

Wọn ni yoo tun din iye akoko ti awọn arinrinajo n lo loju ọna ọhun ku.

Iye ọdun ti Naijiria yoo fi san owo naa

Tinubu sọ pe ọdun mẹsan an ni ijọba Naijiria yoo fi san owo naa tan, amọ ko ni san owo kankan ni ọdrun mẹta akọkọ.

Lẹyin naa lo rọ awọn aṣofin ọhun ki wọn tete buwọlu ẹbẹ oun lati ya owo naa.

Nigba ti olori awọn aṣofin naa ka lẹta Aarẹ niwaju ile, wọn sọ pataki oju ọna ti ijọba fẹ fi owo naa ṣe.

Wọn ni ọpọ anfani ni yoo ṣe faraalu ti wọn ba ti pari rẹ tan.

Awọn aṣofin naa ni ọna ọhun yoo din iye akoko ti eeyan n lo lati Sokoto si ipinlẹ Eko ku lati wakati mẹtala si wakati mẹfa pere.

Ile aṣofin ti wa fa ọrọ naa le igbimọ to n ri si ọrọ gbese labẹ ati loke okun lọwọ ki wọn si jabọ pada laarin ọsẹ kan.