You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́wàá táwọn èèyàn ti ń kojú ebi jùlọ ní àgbáyé, tó fi mọ́ Nàíjíríà
Ajọ Global Network Against Food Crises (GNAFC), ajọ to n gbogunti aisi ounjẹ kaakiri gbogbo agbaye ti kọminu lori bi awọn eeyan ti ko ri ounjẹ jẹ ṣe n pọ si kaakiri agbaye.
Abọ iwadii ti ajọ naa gbe jade fun ọdun 2026 sọ pe eeyan to le ni ọgọta le ni igba miliọnu ni orilẹ ede mẹtadinlaadọta kaakiri agbaye ni wọn n koju ebi ọjaja fọwọ mẹkẹ.
Ajọ naa ka orilẹ ede mẹwaa eyi ti Naijiria wa lara wọn gẹgẹ bi awọn orilẹ ede tawọn eeyan ibẹ ti n koju airi ounjẹ jẹ julọ lọdun 2026.
Wọn ṣekilọ pe o ṣeeṣe kawọn eeyan naa tun lekun ti ko ba si igbiyanju lati fopin si awọn ohun to n ṣokunfa ebi ni awọn orile ede naa.
Gẹgẹ bi abajade iwadii ajọ naa ati ẹka ajọ iṣọkan agbaye to n ri si ounjẹ, iyẹn World Food Programme, WFP, a ṣe akojọ awọn orilẹ ede mẹwaa ti awọn eeyan ti ebi n pa pọ si julọ.
Naijiria – eeyan miliọnu marundinlogoji
Orilẹ ede Naijiria lo wa loke tente ninu awọn orilẹ ede ti ajọ GNAFC ni o ni awọn eeyan ti ebi n pa julọ ninu awọn orilẹ ede ti wọn ṣe iwadii rẹ.
Ẹka ajọ iṣọkan agbaye to n ri si ounjẹ, iyẹn World Food Programme, WFP ninu abọ iwadii rẹ tọdun 2026 sọ pe eeyan miliọnu marundinlogoji ni ebi n ba finra ni Naijiria.
Abọ iwadii WFP naa sọ pe ẹkun ila oorun ariwa Naijiria ni awọn ti ko ri ounjẹ jẹ pọ si julọ ati pe awọn ọmọde ati obinrin ni ọrọ naa kan julọ, ti wọn si wa ninu ewu.
Wọn ka ipinlẹ Borno, Yobe ati Adamawa bii awọn ipinlẹ ti nnkan ti buru julọ ti apapọ awọn eeyan to n koju ebi ni ipinlẹ mẹtẹẹta nikan to miliọnu mẹfa din diẹ.
DR Congo – eeyan miliọnu mẹrindinlọgbọn
Gẹgẹ bi ẹka ajọ iṣọkan agbaye to n ri si ounjẹ, World Food Programme ati International Food Security Programme, IPC ṣe sọ, eeyan miliọnu mẹrindinlọgbọn o le lo n koju ebi ọjaja fọwọ mẹkẹ ni Democratic Republic of Congo.
IPC sọ awọn eeyan to din diẹ ni miliọnu mẹrin lo n koju iyan to lagbara ninu awọn eeyan naa.
Ajọ to n ri si ounjẹ ati ohun ọgbin, Food and Agriculture Organization, FAO ati WFP ti wa ṣekilọ pe laasigbo to n tẹsiwaju ni DR Congo yoo tun mu alekun ba iyan to n ba awọn eeyan ibẹ finra.
Sudan – eeyan miliọnu mọkandinlogun
Atẹjade kan ti WFP fi lede ninu oṣu Kẹrin ọdun 2026 ṣafihan rẹ pe eeyan to le ni miliọnu mọkandinlogun lo n koju ebi ni orile ede Sudan.
Atẹjade naa sọ pe oogun to n lọ lọwọ ni orilẹ ede ọhun ati aifi aaye gba awọn ajọ to n boju aanu woni lati ri bi wọ ibẹ wa lara ohun to mu ki awọn eeyan to n koju airi ounjẹ jẹ ni orilẹ ede naa pọ to bẹẹ.
WFP sọ pe bii ilaji awọn eeyan to w ani Sudan ni wọn n koju ebi paapaa ni awọn agbegbe ti ohun ti n waye bii El-Fasher, nibi ti awọn eeyan to to miliọnu mẹfa ti n koju ebi gidi.
Lati ọdun 2023 ni Sudan ti n koju ogun abẹle eyi to ti mu ki ọpọ eeyan fi ile wọn silẹ.
Afghanistan – eeyan miliọnu metadinlogun
Atẹjade kan ti ajọ iṣọkan agbaye ati ajọ iṣọkan Yuroopu fi sita lọdun 2025 sọ pe ipo Karun-un ni Afghanistan wa ninu awọn orilẹ ede tawọn eeyan rẹ n koju ebi julọ.
Atẹjade ti ajọ Global Food Security and Climate Change, GRFC gbe jade sọ pe eeyan to le ni miliọnu mẹtadinlogun lo n koju ebi ni Afghanistan.
Gẹgẹ bi ijabọ naa ṣe sọ, ida mẹrindinlogoji eeyan to wa ni orilẹ ede naa ni ebi n pa.
Yemen - eeyan miliọnu metadinlogun
Ogun abẹle to ti n waye ni Yemen lati bii ọdun mẹwaa sẹyin ti mu ki iyan ati ebi maa ba awọn eeyan orilẹ ede naa finra gẹgẹ bi ajọ iṣọkan agbaye ṣe sọ.
WFP sọ pe eeyan miliọnu metadinlogun ni o n koju ebi ni orilẹ ede naa.
Iwadii ni eeyan miliọnu marun-un o din diẹ ni ko nile lori mọ nitori laasigbo to n ba orilẹ ede naa finra.
Bangladesh - eeyan miliọnu mẹẹdogun
Bangladesh, to wa ni guusu awọn orilẹ ni ẹkun Asia, wa lara awọn orilẹ ede tawọn eeyan rẹ n koju ebi julọ ni agbaye.
Gẹgẹ bi iwadii GNAFC tọdun 2026, eeyan miliọnu mẹẹdogun ni ebi n da laamu ni orilẹ ede naa lọdun yii.
Awọn aṣatipo Rohinyga to le ni miliọnu kan, ti wọn wa lati Myanmar ni ajọ WFP n ṣe atilẹyin fun ni orilẹ ede naa.
Ijabọ naa ni ida mẹtalelọgbọn awọn eeyan Bangladesh lo n koju idunkoko ebi ni Bangladesh.
Myanmar - eeyan miliọnu mejila
Myanmar, to jẹ orilẹ ede to mule ti Bangladesh wa lara awọn orilẹ ede to n koju iyan ni agbaye.
Eeyan to le ni miliọnu mejila lo n koju ebi nibẹ gẹgẹ WFP ṣe sọ.
Ni Myanmar, orilẹ ede to ti n koju laasigbo lati ọdun pipẹ, awọn iya ko ri ounjẹ fun awọn ọmọ wọn lati le w ani ilera pipe, eyi to n mu ki ọpọ ọmọde wa ninu ewu airi ounjẹ jẹ.
Syria - eeyan miliọnu mẹsan-an
O ti n to ọdun mẹtala lọ ti ogun abẹle ti n waye ni Syria eyi to ti sọ ọpọ eeyan sinu ebi.
Atejade ajọ WFP fi han pe eeyan to le ni miliọnu mẹṣan-an lo n koju ebi to lagbara ni Syria.
Ijabọ naa ni iṣoro nla ni awọn eeyan Syria n koju ki wọn to le ri ounjẹ fun awọn ebi wọn.
Gẹgẹ bi iwadii ṣe fi han Syria lo w ani ipo keji awọn orilẹ ede tawọn eeyan rẹ maa n rinrin ajo si orilẹ ede mii julọ.
Pakistan - eeyan miliọnu meje abọ
Ninu atejade kan ti ajọ WFP fi lede loṣu Keji ọdun yii, wọn ni eeyan miliọnu meje abọ lo n koju ebi ni Pakistan.
Ẹkun omi to ṣọṣẹ ni orilẹ ede naa ni ọdun to kọja lo ṣokunfa bi orilẹ ede naa ṣe ba ara rẹ ninu ewu yii bi ọpọ ohun ọgbin ṣe ba ẹkun omi naa lọ.
Yatọ si eyi, Pakistan tun ti koju ọgbẹlẹ eyi to ti doju ẹka eto ọgbin orilẹ ede naa delẹ.
South Sudan – eeyan miliọnu meje abọ
Bii ilaji apapọ awọn eeyan to wa ni South Sudan ni ebi n pa.
Abọ iwadii naa ṣafihan pe awọn ọmọde to le ni miliọnu meji lo ṣeeṣe ki wọn koju airi ounjẹ lọdun to n bọ.
Gẹgẹ bi IPC ṣe jabọ, awọn eeyan 28,000 lo ṣeeṣe ki wọn koju ebi to lagbara lawọn agbegbe ti laasigbo ti n waye.
Awọn nnkan to n dakun airi ounjẹ jẹ kaakiri agbaye
Lara awọn nnkan tawọn ajọ naa ka pe o ṣokunfa tie bi fi pọ ni awọn orilẹ ede yii ni:
- Laasigbo ati ogun
- Ipenija aabo
- Ọwọngogo
- Ayipada oju ọjọ
- Ẹkun omi ati ọgbẹlẹ
- Ọwọngogo awọn ohun ọgbin
Awọn ọna lati tan awọn iṣoro yii
Abọ iwadii naa sọ pe lati koju iṣoro ebi ọjaja fọwọ mẹkẹ yii, awọn orilẹ ede ti iṣoro yii n ba finra nilo lati fọwọsowọpọ lati wa ojutuu si iṣoro naa.
Wọn ni igbesẹ to gbopọn gbọdọ wa lati wa bi ounjẹ ṣe maa pọ si ni ilu lojuna ati mu adinku bae bi ati iyan.
Bakan naa ni wọn ni awọn ijọba ni gbogbo ipele gbọdọ gbe igbesẹ lati mu alekun ba ohun ọgbin ni gbogbo ọna.
Wọn fi kun pe ayipada oju ọjọ gbọdọ jẹ ohun ti wọn maa mojuto, ki ipese iṣẹ si wa fun awọn to n gbe ni ẹsẹ kuku.
Wọn ni aabo tun gbọdọ wa fawọn ajọ to maa n pese ohun iranwọ fawọn orilẹ ede to n koju iṣoro ounjẹ, ti ijọba si gbọdọ ni ifarajin si mimojuto awọn ohun to n fa ebi.