Èèyàn bíi 400 rí ẹ̀wọ̀n he lórí ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú agbésùnmọ̀mí ní Naijiria

Ikọlu agbesunmọmi ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, Anadolu via Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Nnkan bii irinwo eeyan lo ti gba oniruru idajọ ni Naijria bayii lori ibaṣepọ wọn pẹlu awọn ẹgbẹ agbseunmọmi.

Lara awọn idajọ ti awọn afurasi naa gba ni idajọ ẹwọn ọdun marun un si ẹwọn gbere fun ibaṣepọ wọn pẹlu ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram ati ẹgbẹ Islamic State West Africa Province (Iswap) to yapa kuro ni Boko Haram.

Idajọ yii lo n waye lasiko ti gbogbo oju wa lara ijọba apapọ Naijiria lati gbogun ti awọn agbesunmọmi ko si tan iṣoro eto abo to mẹhẹ.

Oniruru ẹgbẹ agbesunmọni ni awọn ọmọ ogun Naijiria n koju lọwọ yii, bi awọn kan ṣe n ja ija ẹsin lawọn mii n fi ijinigbe ṣiṣẹ ṣe.

Ọdun 2009 ni ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Boko Haram bẹrẹ ikọlu ni Ariwa ti wọn si gbẹmi ẹgbẹrun eeyan nigba ti wọn sọ eeyan bii miliọnu meji di alainilelori, gẹgẹ bii awọn ajafẹtọọmọniyan ṣe sọ.

Lọjọru to kọja ni ijọba ilẹ Amẹrika kilọ fun awọn ọmọ ilẹ rẹ to fẹ lọ si Naijiria ki wọn tun ero wọn pa latari eto abo to mẹhẹ nibẹ.

O le ni afurasi 500 to jẹjọ nile ẹjọ giga to wa niluu Abuja lori ẹsun ti ijọba fi kan wọn.

Lara ẹsun ti wọn fi kan wọn ni kikopa ninu oniruru ikọlu tabi ṣiṣe atilẹyin fun awọn agbesunmọmi nipa fifun wọn lowo, ohun ija oloro tabi nipa awọn atilẹyin mii.

Lọjọ Ẹti ni adajọ ṣe idajọ eeyan 386 lara awọn 500 naa.

O da awọn meji silẹ pe wọn ko lọwọ ninu rẹ, ile ẹjọ ni ki eeyan mẹjọ maa lọ ile wọn layọ ati alaafia nigba to sun igbẹjọ eeyan 112 siwaju.

Ẹwẹ, lọpọ igba lawọn araalu ti maa n fẹsun kan ijọba Naijiria pe pupọ ninu awọn to n fi ṣikun ofin gbe lo n tu silẹ lai ṣe idajọ wọn.

Nigba mii ẹwe, araalu ti fẹsun kan ijọba pe awọn kii gbọ nnkankan mọ lẹyin to ba kede pe oun mu agbesunmọmi lati mọ ibi ti ọrọ wọn ja si.

Igbesunmọmi jẹ ọkan gboogi lara iṣoro to n koju ijọba Naijiria fun ọpọ ọdun, o si da bii pe bi ijọba mii ṣe n gori oye ni eto abo n buru siwaju si.