Àgbà òṣèré tíátà, Feso Oyewole jáde láyé

Oríṣun àwòrán, mr latin
Agba oṣere tiata Yoruba, Baniyamin Fesogboye Oyewole, ti ọpọ mọ si Feso Oyewole, ti jade laye.
Awọn mọlẹbi oloogbe naa lo kede iroyin iku rẹ ninu atẹjade kan lọjọ Abamẹta.
Aarẹ ẹgbẹ oṣere tiata ni Naijiria, TAMPAN, Bolaji 'Mr Latin' Amusan naa tun fidi iroyin iku oloogbe ọhun mulẹ loju opo Facebook rẹ.
Ṣaaju ni iroyin iku oloogbe naa ti kọkọ n lọ lori ayelujara ki awọn mọlẹbi rẹ to fidi iroyin naa mulẹ ninu ikede ti wọn ṣe.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ ni pato ohun to ṣokunfa iku naa ati bo ṣe dagbarere faye, wọn ni ana ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2026 lo papoda.
Mọlẹbi rẹ sọ ninu atẹjade wọn pe "Ni itẹriba fun ifẹ Allah (SWT), a kede ipapoda baba, baba-baba, ọkọ ẹgbọn ati ibatan wa, Baniyamin Fesogboye Oyewole to pada si ọdọ ẹlẹda rẹ lọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2026.
"A dupẹ lọwọ Allah fun igbeaye to fun, asi gbadura ko dari ẹsẹ rẹ jin in...."
Gẹgẹ bii awọn mọlẹbi naa ṣe sọ, oni ọjọ Abamẹta ni eto isinku rẹ waye nile rẹ to wa ni Oke Orogbo, lagbegbe Lalupon, niluu Ibadan.
Ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo ti bẹrẹ si n ṣedaro rẹ bayii lori ayelujara.
Oloogbe naa kopa ninu ọpọlọpọ ere agbelewo ti wọn ṣe ni ede Yoruba nigba aye rẹ.

























